Kí ni 'Maulud Nabiy' àti ìdí tí èrò àwọn Mùsùlùmí fi yàtọ̀ lóríi rẹ̀?

Awọn ọkunrin Musulumi pupọ lo wa ninu aworan yii, wọn jokoo ninu mọṣalaṣi nla kan. Awọn kan de fila, awọn kan ko de, oniruuru aṣọ ni wọn wọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ọkunrin Musulumi pupọ ninu mọṣalaṣi kan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ayajọ ọjọ ibi Anabi Muhammad (Ki ikẹ ati ọla maa ba a) ti i ṣe ojiṣe Ọlọun Allah ni awọn Musulumi n pe ni Maulud Nabiy.

Ayajọ ọjọọbi Anabi Muhammad naa lo ko lonii yii, ọjọ karun-un oṣu Kẹsan-an ọdun 2025, ti wọn si n ṣajọyọ rẹ kaakiri.

Ṣugbọn ki i ṣe gbogbo Musulumi aye lo n sami ayẹyẹ ọjọọbi naa, bi awọn kan ṣe sọ ọ di ko ṣee ma ṣe, ti wọn yoo gun ẹṣin yipo ilu tilu-tifọn, bẹẹ ni awọn Musulumi kan sọ pe ẹṣẹ nla ni ki eeyan ṣe Mọludi ninu Islam.

Anabi ti wọn n sami ọjọọbi rẹ lonii yii ni baba rẹ n jẹ Abdullah ọmọ Abdul Mutalib, iya rẹ si ni Amina ọmọ Wahab.

Ọmọ ọdun mẹfa ni Muhammad wa ti iya rẹ fi ku, ko si tilẹ ba baba rẹ, baba ti ku ki iya rẹ too bi i.

Eyi lo fi jẹ baba to bi baba rẹ, Abdul Mutalib lo tọ ọ de aaye kan ki baba naa too dagbere faye, ti ẹgbọn baba rẹ, Abu Talib, si tun tẹwọ gba a .

Nigba ti Anabi Muhammad n dagba bii ọdọkunrin, o bẹrẹ si i ba obinrin olowo kan, Khadija, ta ọja.

Opó ni Khadija, oun lo si nawọ ifẹ si Anabi nigba to ri i pe o ṣe olootọ ni gbogbo ọna. Khadija naa si ni iyawo akọkọ ti Anabi fẹ, bo tilẹ jẹ pe iya naa ju u lọ fun ọdun mẹẹẹdogun.

Ni ọdun 610, nigba ti Muhammad wa ni ẹni ogoji ọdun, Malaika Jubril bẹ ẹ wo ninu iho ti a mọ si Hira, nibi to ti gba aṣẹ imọ lati ka Kurani, to si gba aaya akọkọ ninu iwe mimọ naa.

Bẹẹ lo si ṣe bẹrẹ iṣẹ ojiṣẹ fun Ọlọun ọba Allah. O si jiṣẹ naa fun ọdun mẹtalelogun gbako ki ọlọjọ too de.

Lẹyin iku rẹ ni 632, awọn kan bẹrẹ si i ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, paapaa julọ laaarin sẹnturi kẹsan-an si ikẹwaa.

Orilẹede Egypt ni wọn ti kọkọ bẹrẹ ayẹyẹ ọjọọbi naa ti wọn n pe ni Maulud Nabiy, bẹẹ lo si ṣe to kari awọn Musulumi aye gbogbo.

Kí ni Maulud gan-an?

Aworan Omowe Moctar Diallo, lati General Lansana Conté University, ni Conakry, Guinea. Eeyan pupa ni ọkunrin naa, o de fila pupa, o fi ẹrọ ti eeyan fi n gbọ ohun lori foonu si oke apa ọtun rẹ. O n rẹrin-in musẹ bo ṣe n wo oju kamẹra.

Oríṣun àwòrán, @ Dr. Moctar Diallo

Àkọlé àwòrán, Ọmọwe Moctar Diallo

Apetan Maulud ninu ede Larubawa ni "Al-mawlid al-nabawi" Ìbí Anabi.

"Bi a ba n sọrọ nipa Maulud ninu ẹsin Islam, a n sọ nipa ayẹyẹ ọjọọbi Anabi Muhammad (ki ikẹ ati ọla maa ba a).

"Ọjọ kejila, oṣu kẹta ni wọn bi Anabi, eyi to tumọ si ọjọ kejila, oṣu Rabi-al-Awal ninu ẹsin Islam"

Bẹẹ ni Ọmọwe Moctar Diallo, Ọjọgbọn lati General Lansana Conté University, ni Conakry, Guinea, ṣalaye.

Bakan naa, Youssou Mounkaila, Akọwe apapọ fun ẹgbẹ Islamic Association, lorilẹede Niger, kin ọrọ yii lẹyin.

O ni:

" Iranti lo jẹ fun wa, pe Anabi ti ikẹ ati ọla n bẹ fun, waye loru Rabi-al-Awal. Itumọ rẹ ni pe o yẹ ka ṣeranti rẹ, nnkan ayọ lo jẹ fun awa Musulumi lati ri ipadabọ Anabi lẹẹkan si i. "

Àwọn wo ló n ṣayẹyẹ Maulud àti ìdí ti wọ́n fi ń ṣe é?

Aworan yii ṣafihan awọn ọkunrin to gbe ilu kọ ọrun ti wọn si n lu u, pẹlu awọn to n fun fere. Oju popo ni wọn wa, ero pọ lẹyin wọn, aṣọ funfun ati ṣokoto dudu ni awọn onilu ati onifere naa wọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn onilu ati awọn to n fọn fere pẹlu ero lẹyin wọn.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi alaye, gbogbo Musulumi kọ lo n dana ayẹyẹ ọjọọbo Anabi, eyi si ti fa iyapa lawọn ibi kan lori ayajọ oni.

Gẹgẹ bi Ọmọwe Moctar Diallo ṣe ṣalaye, o ni awọn ẹka ẹsin Islam ti a mọ si Sufi maa n reti ayajọ Maulud Nabiy gidi ni.

"Awọn orilẹede ẹlẹsin Islam ti pupọ wọn jẹ Sufi maa n foju sọna fun ayajọ ọjọọbi Anabi kaakiri agbaye. Awọn wọnyi la mọ si Maghreb ati Iwọ-Oorun Africa, ati awọn orilẹede bii Sudan, awọn kan naa si wa lati Ila-Oorun bii India ati Indonesia."

"Ayẹyẹ nla gbaa ni ọdun yii jẹ fun wa, awọn ijọ Sufi ati Shiites ka ọjọ yii si ọjọ pataki ati ọjọ isinmi fawọn Musulumi."

Tẹ o ba gbagbe, awọn ijọ Sufi yii ni ọpọ mọ fun awọn ohun to yatọ ninu ẹsin Islam, bẹẹ si ni awọn Shittes naa.

Idi ni pe awọn igbagbọ kan wa ti wọn di mu, ti awon ẹlesin Islam mi-in si lodi si pe ko tọna.

Ṣugbọn lati fidi ẹ mulẹ pe ṣiṣẹ ọjọọbi Anabi tọna ninu ẹsin Islam, Youssou Mounkaila ṣalaye pe gbogbo Musulumi to ba gba Anabi gbọ lo yẹ ko ṣe ọjọọbi Anabi.

O ni eeyan ko le jẹ Musulumi bi ko ba nifẹẹ Anabi Muhammad ti ọla rẹ ga.

"Latigba aye iran Fatimid Empire, ni Egypt lo ti bẹrẹ, a n sọrọ nipa sẹnturi kẹwaa. Iyen ni pe sẹnturi mẹrin leyin iku Anabi lati ri ibẹrẹ ayẹyẹ yii" Ọmọwe Diallo lo ṣafikun ọrọ Mounkaila bẹẹ.

Mounkaila ni ajọyọ yii ko yẹ ko yọ Musulumi kankan silẹ, niwọn igba ti wọn ba ti gba Anabi Muhammad ni ojiṣẹ Ọlọun.

O ni ayọ nla lo yẹ ko jẹ fun gbogbo eeyan pata lati ṣe ọjọọbi Anabi, nitori Olugbala araye ni.

" Ko yẹ ko yọ ẹnikẹni silẹ, koda ninu irun kiki, ẹ o ri I pe awọn kan wa ti wọn ki I lọ si mọṣalaaṣi kirun, awọn kan ko tiẹ bọwọ fun irun kiki rara. Aṣiṣe ni gbogbo nnkan wọnyi."

Youssou Mounkaila lo wi bẹẹ.

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ Islamic Association of Niger naa sọ pe o da oun loju, pe bi Ọloun ba paṣẹ pe ki Musulumi maa ṣadua fun Anabi, yoo maa fun awọn to ba n ṣajọyọ ọjọọbi rẹ naa ni laada ni.

Àwọn wo ni kì í ṣe ọjọ́ọ̀bí Anabi àti ìdí tí wọn fi kọ̀yìn sí i?

Mọṣalaṣi kan to wu oju lati ri lo wa ninu aworan yii, gbogbo rẹ n tanna yinrin-yinrin pẹlu ọṣọ olowo iyebiye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan mọṣalaṣi nla to wọju pẹlu ọṣọ olowo iyebiye

Ko si iyapa ẹnu lori ọjọ ti wọn bi Anabi Muhammad, gbogbo Musulumi lo gba pe ọjọ kejila oṣu Rabi-al-Awal, ni.

Ṣugbọn ibi ti ẹnu ko ti ko ni pe ko yẹ ki Musulumi ṣayẹyẹ ọjọọbi Anabi.

Awọn wọnyi sọ pe Anabi funra rẹ ko ṣe ayẹyẹ ọjọọbi rẹ ri nigba to wa laye. Wọn ni aawẹ lo maa n fi ayajọ ọjọ ibi rẹ gba, ati ayajọ gbogbo ọjọ Mọnde ti wọn bi i.

Wọn ni awọn ti wọn n ṣe ọjọọbi Ojiṣẹ nla naa da a silẹ lọwọ ara wọn ni, ẹṣẹ si ni ki eeyan da ohun ti ko si ninu Kurani silẹ lọwọ ara rẹ .

Nigba to n ṣalaye nipa awọn wọnyi, Ọmọwe Diallo sọ pe:

"Igbagbọ awọn ti ki i ṣe ayajọ yii ni pe Anabi ko ṣayẹyẹ ọjọọbi rẹ, bẹẹ si ni awọn to ba a lo igba nigba naa ko ṣe e.

"Koda, iran marun-un léyin iku rẹ ko ṣe e pẹlu, iyẹn ni awọn naa ṣe ka a si ohun ti awọn kan wulẹ jokoo sibi kan ti wọn da a silẹ lati maa ṣe"

O ni iyẹn ko sọ pe ki eeyan ma ṣe ọjọọbi Anabi, niwọn igba ti ki I ṣe ijọsin, to jẹ ifẹ Ojiṣẹ nla nikan ni.

Ṣugbọn Aṣoju World Assembly of Muslim Youth, (WAMI), ẹka ti Guinea, ṣalaye tirẹ pe:

"Niwọn igba ti Anabi (Ki ikẹ ati ọla maa ba a) ko ṣe ọjọọbi re funra rẹ, ti ko si pa wa laṣẹ lati ṣe e titi de ori irandiran, ko si idi kanka fun wa lati maa ṣajọyọ ọjọọbi Anabi."

O ni awọn Musulumi ti a mọ si Salafi ati awọn mi-in ti ki i ṣe Sufi abi Shiite, ko ni i ba wọn ṣe ọjọọbi Anabi laye.

Lákòótán

O pẹ ti iyapa ẹnu nipa ayẹyẹ Maulud Nabiy yii ti n waye, ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Bakan naa ni awijare awọn to n ṣe e ati tawọn to lodi si I ko yipada.

Ko daju pe iyapa naa yoo kuro, nitori kaluku lo ni awijare rẹ to ka si tootọ ati ilana to tọ labẹ ofin ṣiṣẹ ọjọọbi Anabi Muhammad (Ki ikẹ ati ọla maa ba a).