Kí ni òfin Islam sọ nípa ìpànìyàn nítorí sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí Anabi?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Amaye ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Niger nígbà tí àwọn kan dáná sun ún, fún ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ànábì Muhammad.
Gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Niger ṣe sọ, Amaye tó ń ta oúnjẹ ni àwọn èèyàn kan ṣe ìkọlù sí, tí wọ́n sì dáná sun-ún ní agbègbè Kasuwan-Garba ní ìpínlẹ̀ náà ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni Niger, Wasiu Abiodun fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 2025 sọ pé àwọn èèyàn náà ti dáná sun obìnrin náà tán kó tó di pé àwọn ọlọ́pàá ríbi débẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn ṣe ṣàlàyé, wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí èèyàn kan tó jẹ́ oníbàárà tó ra oúnjẹ lọ́wọ́ Amaye sọ fún un pé òun fẹ́ fi ṣe aya láti fi mú Sunnah Anabi wá sí ìmúṣẹ.
Wọ́n ní èsì tí Amaye, tí òun náà jẹ́ Mùsùlúmí, fún ọkùnrin náà jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì sí Anobi Muhammad.
Èyí ni wọ́n ni ó bí àwọn ọkùnrin tó wà níbẹ̀ nínú, tí wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ọ̀dọ́ olórí agbègbè náà níbi tí Amaye tún ti tún ọ̀rọ̀ náà sọ, tó sì bí àwọn ọkùnrin tó wà níbẹ̀ nínú pẹ̀lú.
Èyí ló ṣokùnfà bí áwọn èèyàn náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ òkò lu Amaye, tí wọ́n sì tún dáná sun ún títí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fa awuyewuye lórí ayélujára, tí àwọn èèyàn sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ àwọn èèyàn náà.
MURIC bu ẹnu àtẹ́ lu pípa obìnrin náà ní Niger
Àjọ tó ń rí sí ẹ̀tọ́ àwọn Mùsùlùmí ní Nàìjíríà, MURIC ti bu ẹnu àtẹ́ lu pípa Amaye, tí wọ́n sì ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò bá ẹ̀sìn Islam mu.
Adarí àjọ MURIC, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq Akintola nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni ẹ̀sùn sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí Anabi Muhammad tàbí Allah ní ìjìyà lábẹ́ òfin Islam àmọ́ ó ní ìlànà tí ìjìyà bẹ́ẹ̀ le gbà wáyé.
Ó ní kìí ṣe pé àwọn èèyàn kàn máa kó ara wọn jọ tí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn bíkòṣe pé ó di tí ilé ẹjọ́ ní ìlànà Sharia tàbí ti ìjọba bá dájọ́ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.
"Òfin tí Islam ṣe ni pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gba ẹ̀mí èèyàn àyàfi láti ọwọ́ ilé ẹjọ́ tí ìjọba gbé sílẹ̀. Ẹni tí ilé ẹjọ́ bá dájọ́ ikú fún nìkan ni Islam fi ààyè sílẹ̀ fún pé kí wọ́n gba ẹ̀mí ẹ̀ yálà ilé ẹjọ́ olóyìnbó tàbí ti Sharia."
Ó ní sísun èèyàn nínà tàbí ṣíṣá èèyàn ládàá jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin Islam.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq ní ó pọn dandan fún ìjọba láti ṣe àwárí àwọn tó hùwà láabi náà, kí wọ́n sì fi wọ́n jófin láti dènà irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, onímọ̀ nípa ẹ̀sìn Islam ní ìlú Ilorin, Muritadha Yahaya sọ fún BBC News Yorùbá pé lóòótọ́ ni Hadith kan wà tó fẹ́sẹ̀ múlẹ̀ pé ikú ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tó bá bú Anabi.
Ó ní nínú ìlànà Sharia, adájọ́ nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí àti àwọn ẹlẹ́rìí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹni náà ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún.
Alfa Muritadha fi kun pé irúfẹ́ ìjìyà bẹ́ẹ̀ kò tún gbọdọ̀ wáyé ní ìlànà dídáná sun èèyàn nítorí Ọlọ́run nìkan ló ní ẹ̀tọ́ láti fi iná jẹ èèyàn níyà.
Ìlànà wo ni wọ́n máa ń gbà láti kọnu ìfẹ́ sí èèyàn nínú Islam?
Onímọ̀ Islam, Muritadha Yahaya ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí òfin Islam ṣe là á kalẹ̀, ọ̀nà méjì ni ọkùnrin lè gbà láti fi dẹnu ìfẹ́ kọ obìnrin.
Ó ní ọ̀nà àkọ́kọ́ ni nípasẹ̀ lílọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí ọmọbìnrin bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn tó bá kù fun ní òbí tó sì jẹ́ pé àwọn ni wọ́n máa jíṣẹ̀ náà fún obìnrin.
Ìkejì ní lílọ ba ẹni náà fúnra rẹ̀ tí wọ́n sì jọ máa sọ̀rọ̀ láti jọ sọ̀rọ̀ lórí tí wọ́n bá wu ara wọn.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí irú èsì tí èèyàn le bá lẹ́nu ẹni tí èèyàn bá kọ ẹnu ìfẹ́ sí, Alfa Muritadha ní kò sí ohun tó burú nínú kí obìnrin kọ̀ láti fẹ́ èèyàn ṣùgbọ́n tó gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìlànà tó bá Islam mu.
Ó fi kun pé ó jẹ́ ohun tó burú fún mùsùlùmí láti máa bú ẹlẹ́sìn míì tó sì jẹ́ ohun tó le dá wàhálà sílẹ̀.
Iye ìgbà tí pípa èèyàn nítorí sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí Anabi
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí pípa èèyàn fẹ́sùn pé wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Anabi Muhammad ń wáyé pàápàá ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.
Ní ọdún 2022, akẹ́kọ̀ọ́ kan, Deborah Samuel pàdánù ẹ̀mí sí ìkọlù bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n dáná sun ún láàyè ní ìpínlẹ̀ Sokoto fẹ́sùn ó sọ̀rọ̀ òdì sí Anabi.
Bákan náà ni wọ́n sọ òkò pa ọkùnrin kan, Usman Buda ní ìpínlẹ̀ Sokoto kan náà fún ẹ̀sùn kan náà.















