Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu ń dẹ́yẹsí àwọn ẹkùn kan ní Nàìjíríà? Iléeṣẹ́ Ààrẹ ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu
Bi Ogun ẹni ba dani loju, a maa fi n gbari ni.
Eyi ni ohun ti ijọba apapọ, labẹ idari Aarẹ Bola Tinubu, tori rẹ ṣalaye fun awọn to n gbe e kiri pe ijọba yii n ro ile apa kan, dapa kan si, ati pe apa Ariwa Naijiria ko ri nnkan pọnla labẹ iṣakoso yii.
Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹjọ ni atẹjade kan ti ileeṣẹ Aarẹ Naijiria wa, Minisita eto iroyin ati itaniji, Mohammed Idris lo si fi lede.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti ṣalaye pe akoyawọ ati ṣiṣe deede ni Tinubu n lo lati ṣe ohun amayedẹrun si ẹkun mẹfa ti Naijiria pin si.
Wọn fi kun un pe ootọ inu ati bi eeyan ba ṣe kunju oṣuwọn to lo si n lo lati yan awọn eeyan sipo ijọba.
"Ko si ẹya tabi ẹkùn to n ṣe ẹrú ẹgbẹ rẹ lorilẹede yii, gbogbo ẹkun mẹfẹẹfa lo ni ẹka idagbasoke.
"Bi iṣẹ oju ọna ṣe n lọ ni Guusu, bẹẹ naa ni marosẹ Badagry–Sokoto n lọ lọwọ, to gba apa Ariwa julọ.
"Ilana pinpin ire yii naa ni ijọba si n lo kaakiri fun awọn iṣẹ amayedẹrun to n waye ni awọn ẹkun Naijiria.
"150bn fun ọkọ oju irin Kano, 100bn fun ti Kaduna''
Minisita eto iroyin naa tẹsiwaju ninu alaye rẹ, pe owo to to aadọjọ biliọnu naira (150b) ni ijọba Tinubu ti ya sọtọ lati ṣe oju ọna irin reluwee ipinlẹ Kano.
O ni ọgọrun-un kan biliọnu (100bn) ni wọn si fẹẹ fi ṣe iru rẹ ni Kaduna.
Iru rẹ ti wọn n ṣe nipinlẹ Eko ati Ogun naa wa lara iṣẹ ijọba Tinubu bo ṣe wi, eyi ti yoo gbe Naijiria goke agba, ti iṣẹ to le ni ẹgbẹrun lọna igba ati aadọta (250,000) yoo si wa fun awọn eeyan lati ṣe kaakiri Naijiria.
" A tun n gbero lati gbe ọna ọkọ oju irin apa Ila Oorun Naijiria lati Port Harcourt si Maiduguri dide.
"Lafikun, o le ni ẹgbẹrun kan ileewosan alabọọde ti iṣakoso Aarẹ Tinubu ti gbe dide kaakiri Naijiria, to n fi han pe a ko ko iyan ilera awọn araalu kere."
Ileeṣẹ Aarẹ Tinubu sọ pe ko ruju rara, nitori akọsilẹ fi han pe apa Ariwa-Iwọ-Oorun (North-West) n ri nnkan gba julọ.
Bí wọ́n ṣe pín owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀
• North West (Ariwa-Iwọ-Oorun) : ₦5.97 trillion (o le ni ida ogoji iṣẹ to n lọ nibẹ ti ijọba ti buwọ lu (over 40% of approvals)
• South South (Guusu-Guusu): ₦2.41 trillion.
• North Central(Aarin Gbungbun Ariwa): ₦1.13 trillion
• South East (Guusu Ila-Oorun): ₦407 billion
• North East (Ariwa Ila-Oorun): ₦400 billion
• South West (Guusu Iwọ-Oorun). ( Wọn yọ ilu Eko kuro nibẹ): ₦604 billion
Àwọn akanṣe iṣẹ ọna ti Tinubu n ṣe:
1. Lagos–Calabar Coastal Highway (750 km): 175 km to n lọ lọwọ l'Ekoo, Cross River ati ipinlẹ Akwa Ibom.
2. Sokoto–Badagry Superhighway (1,068 km): 378 km to n lọ lọwọ ni Kebbi ati Sokoto
3. Trans-Sahara Highway (465 km): 118 km to n lọ lọwọ nipinlẹ Ebonyi.
4. Akwanga–Jos–Bauchi–Gombe Road (439 km): Wọn n tun un ṣe si I ko le baa pẹ.
Ida mejilelaadọta (52%) ni Ariwa fi gun, nigba ti Guusu ko ju mejidinlaaadọta (48%) lọ.
Awọn ojulowo iṣẹ miran ati iye ti wọn yoo fi ṣe wọn lapa Ariwa:
• Sokoto–Gusau–Funtua–Zaria Road (275 km,olopo meji: ₦824bn).
• Abuja–Kaduna–Kano Road (350 km olopo meji: ₦764bn).
• BUA Tax Credit Road, ni Jigawa, Katsina, Kano (256 km olopo meji.
• Zaria–Hunkuyi Road (156 km).
• Kano Northern Bypass (49 km).
• Kano–Maiduguri Road (100.9 km)
Bama ati Dikwa Road ni Borno (100 km).
• Damaturu–Maiduguri Road (110 km).
• Malando Road ni Kebbi (76 km).
• Benue–9th Mile Road (250 km olopo meji, $958m).
• Lokoja–Okene olopo meji (86 km).
• Kaduna–Katsina Roads (Sections 1 and 2, ₦150bn).
Ojúlówó iṣẹ́ ní Guusu ati owo rẹ̀:
• Lagos–Ibadan (8.5 km, ₦33bn).
• Lagos–Sagamu (12 km olopo meji).
• Oyo–Ogbomoso–Ilorin (₦146bn).
• Atunṣe afara Carter, Third Mainland ati Eko Bridge (₦120bn).
Ojúlówó iṣẹ́ ní Guusu Ila-Oorun ati owo rẹ̀:
• Enugu–Onitsha Road (107 km, ₦202bn via MTN Tax Credit).
• Enugu–Onitsha Road (72 km, ₦150bn via CBC).
• Enugu–Abakaliki Road (36 km).
• 2nd Niger Bridge Access Road (17.5 km dualised, ₦175bn).
• Lokpanta–Enugu Road (61 km dualised, ₦100bn).
Guusu Guusu:
• Eleme–Onne Road (30 km, ₦156bn).
• Eket Bypass (9.7 km dualised, ₦76bn).
• East–West Road Section 2 (₦186bn).
• Nembe–Brass Road (₦150bn).
• Lokoja–Benin Dualisation (₦167bn).
• 2nd Niger Bridge Access Road nn Delta (17 km olopo meji, ₦146bn).
• Bodo–Bonny Road nipinlẹ Rivers (35 km pẹlu afara mejila, ₦200bn).
Yatọ si ọna ọkọ ilẹ ati ti oju irin, atẹjade yii sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ lori igbedide ẹka agbara 255MW to wa ni Kaduna, ibudo afẹfẹ idana AKK, wọn si tun n gbe kanga mẹta to jẹ ti epo rọbi ni Kolmani, ipinlẹ Bauchi ati Gombe.
Ilana pin in ire ko dọgba bii ti Ọlọfa mọjọ ni wọn ni Tinubu n lo, ati pe ki awọn ọmọ Naijiria fọkan balẹ.
Ileeṣẹ Aarẹ ni ko sẹni ti ko ni I tọwo ninu ọbẹ idagbasoke ti Tinubu n se fun Naijria lọwọ, wọn ni suuru to lọjọ ni.














