Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Amẹ́ríkà ní owó orí ọjà tí Trump gbé kalẹ̀ fáwọn orílẹ̀ èdè kò bófin mu

Trump nínú ọ́fíìsì rẹ̀ ní While House. Ó wọ aṣọ olómi aro pẹ̀lú táì àwọ̀ èsúrú.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Max Matza & Anthony Zurcher
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn kan ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn owó orí ọjà tí ààrẹ orílẹ̀ èdè náà Donald Trump ń gbé kalẹ̀ ló jẹ́ títàpá sí òfin, èyí tó le ṣe àkóbá fún ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ òkèèrè.

Ìdájọ́ náà kan àwọn owó orí ọjà tí Trump ṣe tako àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé láti fi gbẹ̀san tó fi mọ́ China, Mexico àti Canada.

Nínú ìdájọ́ táwọn adájọ́ méje nínú àwọn mọ́kànlá panupọ̀ lé lórí ní ẹ̀rí tí Trump mú wá pé ààyè wà fún irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ṣíṣe ètò pàjáwìrì fún ọrọ̀ ajé lòdì sí òfin.

Ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹwàá ni àmúṣẹ ìdájọ́ náà tó gbérasọ láti fún ìjọba ní àǹfààní láti pinnu bóyá wọ́n máa lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ láti bèèrè fún àyípadà ìdájọ́ náà.

Ààrẹ Trump tib u ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ náà tó sì ní ó máa ṣe àkóbá fún orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

"Lónìí, ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó ń fi òṣèlú ṣe sọ pé kí a yọ àwọn owó orí ọjà tí a ṣe, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ló máa borí níkẹyìn.

"Tí a bá yọ àwọn owó orí ọjà náà kúrò, ohun tí kò da rárá fún w ani. Ó máa ṣe ìkúrẹtẹ̀ fún owó Amẹ́ríkà, ọ sì yẹ kí a máa lágbára si ni," Trump kọ.

Ṣáájú ni Trump ti ní àwọn owó orí ọjà tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin International Emergency Economic Powers Act (IEEPA), èyí tó fún ààrẹ lágbára láti gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn tó bá le dúnkokò mọ́ orílẹ̀ èdè rẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nínú ìdájọ́ náà, tó jẹ́ abala ìwé 127, ilé ẹjọ́ náà ní IEEPA kò ní kí ààrẹ gbé àlékún owó orí ọjà kalẹ̀ àti pé ilé aṣòfin ló ní agbára láti ṣe àgbékalẹ̀ owó orí àti owó orí ọjà, tí IEEPA kò sì lè yí èyí padà.

ilé ẹjọ́ náà ní kò dájú pé nígbà tí àwọn ilé aṣòfin gbé òfin náà kalẹ̀ lọ́dún 1977, wọn kò gbèrò láti ṣe àyípadà òfin tó ti wà nílẹ̀ àti láti fún ààrẹ ní agbára láti ṣe àgbékalẹ̀ owó orí ọjà.

Ìdájọ́ náà ló ń wáyé látàrí ẹjọ́ tí àwọn iléeṣẹ́ kérejé méjì kan àti àgbáríjọ àwọn ìpínlẹ̀ ní US pè tako Donald Trump lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.

Lẹ́yìn tí Trump gbé àwọn òfin rẹ̀ kalẹ̀ ní oṣù Kẹrin níbi tó ti gbé owó orí ọjà tó tọ ìdá mẹ́wàá kalẹ̀ fáwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé. Trump kéde ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí Amẹ́ríkà gba òmìnira lórí àwọn ètò okoòwò ṣíṣe tí kò tọ́.

Ní oṣù Karùn-ún ni ilé ẹjọ́ kan ní New York sọ pé àwọn owó orí ọjà tí Trump gbé kalẹ̀ náà kò bá òfin mu. Nítorí ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ni àmúṣẹ ìdájọ́ náà kò ì tíì fi wáyé.

Ní àfikún sí àwọn owó orí ọjà náà, ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà tún wọ́gilé owó orí ọjà tako Canada, Mexico àti China èyí tí Trump ní ó pọn dandan láti mú àdínkù bá bí wọ́n ṣe ń gbé egbògi olóró wó Amẹ́ríkà.

Ẹ̀wẹ̀, ìdájọ́ náà kò kan àwọn ọjà bíi irin àti alumíníọ̀mù èyí Trump gbé kalẹ̀ lábẹ́ àṣẹ ààrẹ míì.

Ṣáájú àgbékalẹ̀ idájọ́ náà ni àwọn agbẹjọ́rò ilẹ̀ ìjọba Amẹ́ríkà sọ pé tí ilé ẹjọ́ bá yí àwọn ìpinnu Trump padà, ó ṣeéṣe kó sọ orílẹ̀ èdè náà sínú irúfẹ́ ìṣòro ètò ọrọ̀ ajé tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní lọ́dún 1929.

"Ṣíṣe àyípadà àwọn àṣẹ ààrẹ lórí owó orí ọjà yóò ní ipa tó lágbára lórí ètò ààbò, ìbáṣepọ̀ ilẹ̀ òkèèrè àti ètò ọrọ̀ ajé," àwọn agbẹjọ́rò náà kọ nínú lẹ́tà kan.

"Ààrẹ gbàgbọ́ pé orílẹ̀ èdè wa kò ní lè san ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tírílíọ̀nù dọ́là táwọn orílẹ̀ èdè kan ti san padà èyí tó máa kó Amẹ́ríkà sí oko gbèsè."

Ìdájọ́ náà tún tan ná wádìí àwọn àdéhùn kan tí Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀ èdè kan tọwọ́bọ̀ láti mú àdínkù bá owó orí ọjà wọn.

Ìdájọ́ tuntun le mu kí ó ṣeéṣe kí ààrẹ Trump gba ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lọ.

Àwọn adájọ́ mẹ́sàn-án ilé ẹjọ́ náà, tí wọ́n bá fẹnukò, yóò pinnu bóyá ìgbésẹ̀ Trump wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà kò lọ bí ààrẹ ṣe fẹ́, ó ṣeéṣe kí ìjọba wò ó pé adájọ́ mẹ́ta péré nínú àwọn adájọ́ náà ló jẹ́ èyí tí ẹgbẹ́ ]oṣèlú Republican yàn.

Nínú àwọn adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, mẹ́fà ló jẹ́ yíyàn láti ọwọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican tó sì jẹ́ pé Trump ló yan mẹ́ta nínú wọn.