Ìbò ìjọba ìbílẹ̀: APC borí 20 nínú 23 ní Rivers

Ko din ni ijọba ibilẹ ogun (20) ti ẹgbẹ oṣelu APC ti bori bayii ninu idibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Rivers ni Satide, ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii.
Ẹgbẹ oṣelu alatako ti i ṣe PDP ko ri mu ju ijọba ibilẹ mẹta pere lọ.
Awọn ijọba ibilẹ ti PDP ri mu naa ni Port Harcourt, Obio Akpor ati Ogba/Egbema/Ndoni.
Eyi ni igba akọkọ ninu itan ipinlẹ Rivers, ti APC yoo gba gbogbo agbegbe mọ wọn lọwọ bi eyi.
Bakan naa ni APC tun palẹmọ ibo sipo kansilọ nijọba ibilẹ ogun, wọn fi mẹta pere silẹ fun PDP.
Nigba to n kede esi idibo naa, alabojuto ajọ INEC ni Rivers (RSIEC), Ọmọwe Michael Odey, sọ pe awọn yoo fun awọn to yege ni iwe ẹri lọjọ Aje.
Ọpọ araalu ni ko jade dibo ọhun, ṣugbọn ibo naa fi wọn lọkan balẹ pe ijọba pajawiri to n lọ ni Rivers ko ni i pẹẹ dopin, lẹyin ti Aarẹ Tinubu kede rẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2025.
Àtúpalẹ̀ àwọn tó jáwé olúborí
Abua/Odual LGA - APC
Àlaga: Ofori Owolabi
Ibo: 28755
Igbakeji Alaga: Abunu Victoria
Ahoada East - APC
Alaga: Solomon Achoma
Ibo: 54,509
Igbakeji Alaga: Florence Ndukwu
Ahoada West - APC
Alaga: Eugene Ebele Cheta
Ibo: 84125
Igbakeji Alaga: Josephine Uba
Akuku Toru: APC
Alaga: Bob Fubarab A.
Ibo: 63593
Igbakeji Alaga: Wariagbani George
Andoni- APC
Alaga : Otuo Loveday Promise
Ibo: 126,181
Igbakeji Alaga: Ezekiel Raphael Abigbani
Asari Toru LGA- APC
Alaga: George Onengiyeofori
Ibo: 56383
Igbakeji Alaga: Deborah Amos Bobmanuel
Bonny LGA - APC
Alaga: Pepple Abinye Blessing
Ibo: 30543
Igbakeji Alaga: Ibimieye Alagbari
Degema LGA - APC
Alaga: Michael George Williams
Ibo: 61536
Igbakeji Alaga: Harry Maureen
Eleme LGA - APC
Alaga: Obarilomate Ollor
Ibo: 77452
Igbakeji Alaga: Beauty Eke
Emohua LGA - APC
Alaga: Lloyd Chidi Julius
Ibo: 114308
Igbakeji Alaga: Amadi Lilian Obiageri
Etche LGA - APC
Alaga: Njoku Boniface Chima
Ibo: 100649
Igbakeji Alaga: Obele Faith
Gokana LGA - APC
Alaga: Deborah Confidence
Ibo: 96478
Igbakeji Alaga: Kpobari Epsibari
Ikwerre LGA - APC
Alaga: Wobodo Charles
Ibo: 62746
Igbakeji Alaga: Kinika Ethel Chidi
Khana LGA - APC
Alaga: Thomas Bariere
Ibo: 156027
Igbakeji Alaga: Ngbere Mpigi
Obio/Akpor LGA - PDP
Alaga: Dr. Gift Onyinye Wodo
Ibo: 328823
Igbakeji Alaga: Dr. Mrs. Gloria Joyce Nyeche
Ogba/Egbema/Ndoni - PDP
Alaga: Chukwu Shedrach Ogbodo
Ibo: 51051
Igbakeji Alaga: Dr. Happiness Nwokocha
Ogu/Bolo LGA- APC
Alaga: Vincent Nimieboka
Ibo: 36374
Igbakeji Alaga: Alabo Eunice
Okrika LGA - APC
Alaga: Akuro Alfred Tobin
Ibo: 32285
Igbakeji Alaga: Obulubo Charity
Omuma LGA - APC
Alaga: Obasi Uchechukwu
Ibo: 38530
Igbakeji Alaga: Achiri Faustina Joy
Opobo/Nkoro LGA - APC
Alaga: James A. James
Ibo: 34822
Igbakeji Alaga: Jacks Gladys
Oyigbo LGA - APC
Alaga: Okechukwu Akarao Nwogu
Ibo: 101495
Igbakeji Alaga: Okorie Ngozi Juliana
Port Harcourt - PDP
Alaga: Sir Allwell Ihunda
Ibo: 235054
Igbakeji Alaga: Tom Quinn Mina Mildred
Tai LGA - APC
Alaga: Okwe Mbakpone
Ibo: 70080
Igbakeji Alaga: Caroline Amawa
' Ìbò náà lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀'

Oríṣun àwòrán, RSGH Media
Ninu ọrọ rẹ nipa idibo naa, Apaṣẹ ipinlẹ Rivers, Ajagunfẹyinti Ibok-Ete Ekwe Ibas, sọ pe idibo ọjọ Satide naa lọ ni irọwọrọsẹ.
Ọgagun Ibas to mojuto idibo naa, ṣabẹwo si awọn ibudo idibo bii ileeṣẹ ijọba Emohua Council Secretariat, agbegbe Okporowo/Ogbakiri, Abule Igbu Ogbo ati ilu Ogbunuabali ni Port Harcourt.
O ni:
"Inu mi dun pẹlu ohun ti mo ri lonii, idibo naa lọ ni alaafia. Awọn oludibo ati awọn oṣiṣẹ eleto idibo ṣe bo ṣe yẹ."
BBC News Yoruba yoo maa mu abajade iroyin ibo naa bo ba ṣe n lọ.














