France dá orí Ọba ilẹ̀ Afirika kan tí wọ́n bẹ́ lásìkò ìjọba amúnisìn padà lẹ́yìn ọdún 128

Oṣiṣẹ ijọba Madagascar kan gbe apoti ti wọn fi aṣọ pupa we nibi eto ti ileeṣẹ ijọba France to n ri si ọrọ aṣa ti da agbari Ọba Toera pada.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ọdun mejidinlaadoje, akitiyan awọn ẹbi Ọba Toera ati ti ijọba Madagascar ti jẹ ki France da ori ọba ti wọn ti fi pamọ naa pada bayii.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede France ti da agbari Ọba Malagasy lorilẹede Madagascar, eyi ti awọn ọmọ ogun France ṣeku pa lasiko ijọba amunisin, pada.

Ijọba France da agbari Ọba Toera ati tawọn meji mii to jẹ ijoye rẹ pada pẹlu ayẹyẹ to waye nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ aṣa niluu Paris ti i ṣe olu ilu orilẹede naa.

O ti le ni ọgọrun un ọdun ti ijọba France ti ko awọn agbari naa lọ si ilu Paris, ti wọn si ko wọn pamọ sinu ile iko nnkan iṣẹmbaye si.

Didapada awọn agbari yii jẹ imuṣẹ ofin tuntun ti France ṣẹṣẹ ṣe lati da gbogbo ẹya ara awọn eeyan ti wọn ko pamọ pada.

''Ọna to tabuku eniyan ni awọn agbari oloogbe yii gba de ipamọ wa, o si tun sọ nipa iwa ipa aye ijọba akonilẹru,'' Minisita to n ri si ọrọ aṣa ni France, Rachida Dati ni ileeṣẹ iroyin AP lo sọ bẹẹ.

Loṣu Kẹjọ ọdun 1897 ni ijọba France ran awọn ọmọ ogun lọ lati lọ gba ijọba Menabé nibi tawọn ẹya Sakalava n gbe lẹkun guusu orilẹede Madagascar.

Nibẹ lawọn ọmọ ogun ọhun ti pa ọpọlọpọ ọmọ ogun abẹle to wa ni Menabé.

Wọn ṣeku pa Ọba Toera naa, wọn si tun bẹ ori rẹ. Ori yii ni wọn fi ranṣẹ si ilu Paris ti wọn si fi pamọ sile iko nnkan iṣẹmbaye si.

Ayẹwo awọn oniṣẹṣe fidi rẹ mulẹ pe ori Ọba Toera ni France da pada loootọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin ọdun mejidinlaadoje, akitiyan awọn ẹbi Ọba Toera ati ti ijọba Madagascar ti jẹ ki France da ori ọba ti wọn ti fi pamọ naa pada bayii.

Ko si akọsilẹ ayẹwo DNA fun agbari Ọba Toera yii, awọn ayẹwo ti wọn ṣe lori rẹ ni bii ọdun meloo kan ko kẹsẹ jari.

Amọ, ayẹwo tawọn oniṣẹṣe laarin awọn eeyan Sakalava ṣe fidi rẹ mulẹ pe ori Ọba Toera ni France da pada loootọ.

Ẹwẹ, Minisita aṣa lorilẹede Madagascar, Volamiranty Donna Mara, ti oun naa sọrọ nibi ayẹyẹ ti wọn ti da agbari Ọba Toera pada sọ pe nnkan to ṣe pataki ni ijọba France ṣe.

O ni ọgbẹ ọkan ni bi agbari Ọba Toera ati tawọn ijoye rẹ meji ti wọn da pada jẹ fun awọn ẹbi wọn ni Madagascar lasiko ti wọn fi wa nilẹ okeere.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba France yoo da ẹya ara awọn eeyan to ti wa ni ipamọ wọn fun ọjọ pipẹ pada.

Lọdun 2002 ni wọn da oku obinrin kan ọmọ orilẹede South Africa ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Hottentot Venus'' pada si South Africa lẹyin ti wọn ti kọkọ ṣafihan rẹ kaakiri ilẹ Yuroopu.

Amọ, igba akọkọ ree ti France yoo da ẹya ara eeyan pada labẹ ofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe.

Akọsilẹ fihan pe, o le ni ẹgbẹrun lọna ogun ẹya ara eeyan ti France ko pamọ eyi ti wọn ko wa lati awọn orilẹede agbaye.