Ìyá ọlọ́kadà t'ọ́kọ̀ ọlọ́pàá tẹ̀ pa níbi ìwọ́dé tako owó gọbọi táwọn aṣòfin ń gba, bèèrè fún 'ìdájọ́ òdodo'

Àkọlé fídíò, Ìyá ọlọ́kadà t'ọ́kọ̀ ọlọ́pàá tẹ̀ pa níbi ìwọ́dé tako owó gọbọi táwọn aṣòfin ń gba, bèèrè fún 'ìdájọ́ òdodo'
Ìyá ọlọ́kadà t'ọ́kọ̀ ọlọ́pàá tẹ̀ pa níbi ìwọ́dé tako owó gọbọi táwọn aṣòfin ń gba, bèèrè fún 'ìdájọ́ òdodo'

Ọlọkada ni Affan Kurniawan. Iṣẹ aje rẹ lo si ba lọ ni Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọn oṣu kẹjọ amọ ko pada dele mọ laaye.

Affan Kurniawan jade laye kẹyin ti ọkọ ọlọpaa gba a lasiko iwọde kan lọjọbọ.

Iku arakunrin naa ti fa ọpọlọpọ iwọde fun atunto ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Indonesia bayii.

Opopona kan nibi ti awọn ọlpaa atawọn oluwọde ti n koju ara wọn afẹfẹ tajutaju ku gbogbo igboro.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iya Affan Kurniawan ṣalaye fun BBC News Indonesia pe idajọ ododo lọkan oun n poungbẹ fun bayii lori iku ọmọ oun.

Omilẹngbẹ ero lo peju si ibi eto isinku, pupọ wọn lo si n lọọgun pe asiko ti fun awọn alaṣẹ nibẹ lati rii daju pe iwadii to daju waye lori iku rẹ, ki wọn ma si ṣe fi ololo fọhun ninu iwadii naa.

Ààrẹ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹbí ọlọ́kadà náà

Ààrẹ Prabowo Subianto tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹbí Kurniawan fún ọṣẹ́ táwọn

ọlọ́pàá náà ṣe, tó sì rọ àwọn èèyàn orílẹ̀èdè Indonesia láti túbọ̀ ní ìgbàgbọ̀ nínú ìjọba.