Ǹjẹ́ ewu ń bẹ fún àlááfìà rẹ bí o bá ń fi oúnjẹ àárọ̀ sílẹ̀ láì jẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ironu ohun ti a fẹẹ jẹ ba ti kuro ninu ìṣẹ́, ìṣẹ́ ọ̀hun kù fẹẹrẹfẹ, awọn miran a si ni ìṣẹ́ buṣe, nitori pe dandan ni ka jẹun, ko si si oogun ebi kan ju ounjẹ lọ.
Ounjẹ ẹẹmẹta lojumọ ni ọpọ eeyan gba pe o yẹ ki eeyan maa jẹ, iyẹn naa si ni ounjẹ aarọ, ọsan ati ti alẹ.
Lasiko yii ti imọ ijinlẹ ti goke agba pupọ, ọlọkan-o-jọkan ọrọ lo ti tan kalẹ nipa bo ṣe yẹ ki eeyan maa jẹun, paapaa ounjẹ aarọ.
Ọpọ imọran lati gbọ nipa pe ounjẹ aarọ ṣe pataki pupọ ninu ounjẹ oojọ, nitori o le so ara ro fun igba pipẹ ninu ọjọ.
Ohun ti ọpọ eeyan lode oni si gbonjuba ni pe o lewu pupọ bi eeyan ko ba ki n jẹ ounjẹ aarọ, bo tilẹ jẹ pe awọn oniwadii kan tun ti n tako ki eeyan ji laaarọ ko si jẹun.
Awọn gba pe bi eeyan ko ba ki n jẹun aarọ, to si jẹ ẹni to sanra, o le ran an lọwọ lati din ara sisan naa ku.
Ẹwẹ, nigba mi-in, ki i ṣe pe eeyan o fẹẹ jẹun aarọ, ṣugbọn iṣẹ le diju, ti aaye ko ni si lati jẹun, awọn nnkan mi-in ti eeyan ko ni ikapa lori rẹ si le ṣẹlẹ ti eeyan ko fi ni le jẹun aarọ.
Ṣugbọn to ba jẹ bi awọn oloyinbo ṣe tu ounjẹ aarọ ti wọn n pe ni 'Breakfast' ni a fẹẹ tẹle, iyẹn jijẹun lati ja aawẹ ti a ti n gba latigba ti a ti sun lalẹ wọ owurọ, yoo ye wa yeke pe ounjẹ aarọ ṣe pataki gan-an.
Ǹjẹ́ àìjẹun àárọ̀ lè dín ara àsanjù kù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ iṣẹ iwadii ti awọn onimọ ti ṣe nipa ounjẹ aarọ ati pe boya aijẹ rẹ maa n sabaa ni ajọṣepọ pẹlu ara asanju (obesitiy).
Iwadii kan ti wọn ṣe lorilẹede America, eyi ti wọn fi wo ilera eeyan ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) laaarin ọdun meje, fi han pe awọn ti wọn n jẹ ounjẹ aarọ gaaki lojumọ, kere ni ìwọ̀n (BMI), ju awọn ti wọn n jẹ ounjẹ ọsan ati alẹ ni odiwọn nla lọ.
Awọn oniṣẹ iwadii naa sọ pe ounjẹ aarọ maa n jẹ ki inu kun, yoo si ṣe iranwọ fun bi eeyan yoo ṣe tun le jẹun miran.
Ṣugbọn abọ iwadii kan ti wọn ṣe fun awọn obinrin mejilelaadọta ti wọn sanra asanju, fi han pe ki i ṣe awọn kan ninu wọn bi awọn kan ninu wọn ṣe n padanu ounjẹ aarọ lo ba wọn di ara sisan naa ku.
Iwadii naa fidi ẹ mulẹ pe ayipada to ba ohun ti wọn n ṣe lojumọ lo ba mu adinku ba bi wọn ṣe n sanra sii.
Awọn obinrin to ni awọn maa n jẹ ounjẹ aarọ ṣaaju ki iwadii naa too waye, padanu ọra to din diẹ ni iwọn kilogiramu mẹsan an (8.9kg) ni agọ ara wọn lẹyin ti wọn ko jẹ ounjẹ aarọ mọ, lodi si iwọn kilogiramu mẹfa o le diẹ (6.2kg) fun awọn ti wọn n jẹ ounjẹ aarọ.
Awọn to ti lii jẹ ounjẹ aarọ latilẹ padanu ọra inu ara to din diẹ ni iwọn kilogiramu mẹjọ (7.7) nigba ti wọn bẹrẹ si i jẹ ounjẹ aarọ, ati iwọn kilogiramu mẹfa (6kg) nigba ti wọn kọ ounjẹ aarọ silẹ lai jẹ.
To ba waa jẹ pe ki i ṣe aijẹun aarọ ni eeyan fi le din ara sisan ku, ki lo de ti wọn n sọ pe kawọn to ba sanra asanju yee jẹun aarọ mọ?
Alexandra Johnstone, Ọjọgbọn onimọ nipa ounjẹ ni fasiti ilu Aberdeen, sọ pe boya awọn ti ki I jẹun aarọ ko mọ anfaani ati oore to n bẹ ninu ounjẹ aṣaraloore lọwọ aarọ ni.
Àǹfààní tó wà nínú jíjẹ oúnjẹ àárọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ti fi han, pe aijẹun aarọ kọ ni yoo ni ki eeyan sanra asanju. Jijẹun aarọ ko si ni ki eeyan maa sanra asanju pẹlu.
Koda, aijẹun aarọ gan-an ni awọn onimọ ṣalaye pe o n fa ida mẹtadinlọgbọn (27%) ewu aisan ọkan lagbaye.
O le mu ki aisan ọkan tun lagbara si i ni ida mọkanlelogun (21%).
O le mu ewu itọ ṣuga wa fun ọkunrin ni ida ogun (20%), o si le ṣe afikun ewu oriṣi itọ ṣuga ti a mọ si type 2 lara awọn obinrin to ba n fi ounjẹ aarọ silẹ lai jẹ.
Eyi ṣee ṣe ko ri bẹẹ nitori kikọ ounjẹ aarọ silẹ le ṣakoba fun iye eroja glucose ati insulin ninu ara, gẹgẹ bi awọn oluwadii to ṣiṣẹ lorii aawẹ gbigba ati itọ ṣuga ni 2023 ṣe ṣalaye iyẹn, 'Fasting and Diabetes Study''.
Niṣe ni wọn wadii ilana ijẹun eeyan to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan (100,000) laaarin ọdun meje.
Wọn si ri i pe ewu n bẹ fun awọn ti wọn jẹ ounẹ aarọ tiwọn lẹyin aago mẹsan-an, ju awọn to jẹ ki aago mẹjọ aarọ too lu ni wọn ti jẹun lọ.
Bakan naa ni iwadii kan ti wọn ṣe nipa awọn to n jẹun aarọ, fi han pe awọn eroja aṣaraloore wọn po ju ti awọn ti ki i jẹun aarọ lọ.
Australia, Brazil, Canada, Indonesia ati America ni wọn ti ṣe iwadii naa.
Ki ori pe perepere, ki ara ṣe deede, ki eeyan si le sọrọ lai kọsẹ lete, tun jẹ anfaani miran ti iwadii fi han pe ounjẹ aarọ ni, bi eeyan ba n jẹ e lasiko.
Atupalẹ iwadii mẹrinlelaadọta lo fidi ẹ mulẹ, pe jijẹ ounjẹ aarọ le ṣe iranwọ fun ọpọlọ eeyan, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i fidi awọn ipa mi-in to tun le ni lori ọpọlọ mulẹ.
Mary Beth Spitznagel, ọkan ninu awọn oluwadii naa to jẹ onimọ nipa ọpọlọ ni Kent State University, Ohio, ṣalaye pe awọn apẹẹrẹ kan foju han, pe jijẹ ounjẹ aarọ daa fun ki ọpọlọ ati ara jafafa, o ni ṣugbọn o ṣi nilo ki iwadii miran tun waye si i.
Lákòótán
Bo tilẹ jẹ pe ko si aridaju iru ounjẹ to yẹ ka jẹ ati asiko to yẹ ka jẹ ẹ, afẹnuko awọn onimọ ni pe ki kalulu fiye si ohun ti ara rẹ ba n ba a sọ.
Ka jẹun nigba ti ebi ba n pa wa.
"Ounjẹ aarọ ṣe pataki pupọ fun awọn eeyan ti ebi ba n pa nigba ti wọn ba ji."
Johnstone lo ṣalaye bẹẹ.
Fun apẹẹrẹ, iwadii fi han pe awọn to ṣee ṣe ki wọn ni itọ ṣuga ati awọn to ti ni i, maa n jafafa si i gan-an lẹyin ti wọn ba jẹ ounjẹ aarọ tan, to si jẹ pe ounjẹ ti ko gbe ṣuga ara wọn soke ni wọn jẹ.
Kalulu lo ni ọna to n gba bẹrẹ ọjọ rẹ, o si yẹ ki kaluku mọ odiwọn ṣuga ati glucose to wa ninu ẹjẹ rẹ.
Bẹẹ ni Spitznagel, wi.
Paripari ẹ ni pe yoo daa ka maa paarọ ounjẹ ti a n jẹ, ka ma maa jẹ oriṣi ounjẹ kan ṣaa.
O si tun ṣe pataki lati bojuto bi a ṣe n jẹun yipo ọjọ.
"Ounjẹ aṣaraloore to pe perepere daa laaarọ, ṣugbọn ki eeyan ṣe bẹẹ jẹ ẹ yipo ọjọ tun ṣe pataku julọ lati ṣamojuto itọ ṣuga, eyi to le sọ ìwọ̀n ti eeyan yoo wọ̀n, ati bi ebi yoo ṣe maa pa ni. "
"Lakootan, ounjẹ aarọ nikan kọ lo gba abojuto, bo tilẹ jẹ pe o ṣe pataki pupọ lati sọ ipo ti ara yoo wa, ṣugbọn bẹẹ naa ni eeyan gbọdọ kiyesi awọn ounjẹ yooku to n jẹ yipo ọjọ pẹlu. "
Bi awọn akọṣẹmọṣẹ naa ṣe sọ.














