Ọkọ̀ tó ń kó àwọn tó ń sá àsálà fáwọn agbébọn ní Zamfara yí dà ságbami, èèyàn 16 kú

Ọkọ oju omi kan wa lagbami. Ko si eeyan kankan ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igbesẹ ṣi n waye lati ri oku awọn olugbe ileto Dan- Maga ni ipinlẹ Zamfara lẹyin ti ọkọ oju omi to n gbe wọn ri sinu agbami, lasiko ti wọn n gbero ati sa asala fun ẹmi wọn lọwọ ikọlu awọn agbebọn ni ijọba ibilẹ Gummi.

Ni asiko ti iroyin yii fi jade, oku eeyan mẹrindinlogun ni wọn ti ri ko jade ninu agbami naa, wọn si ti ṣeto isinku wọn.

Awọn ti ori ko yọ ninu ijamba ọkọ oju omi naa wa ni ilu Nasarawar-Kifi.

Lori odo to wa laarin Dan-Maga ati Nasarawar-Kifi ni ijamba naa ti waye, gẹgẹ bi Bashiru Goga to jẹ ọkan lara awọn olugbe Nasarawar-Kifi ṣe sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News.

"Ọfọ nla la n ṣe lọwọ bayii, koda iporuru ọkan gba a ni ajalu yii mu ba wa. Ni alẹ ọjọ Ẹti, a ri eeyan mẹrinla, a si tun ri eeyan meji mii lọjọ Satide." O ni iye awọn ti wọn ti ri oku wọn yọ ninu omi bayii ti di mẹrindilogun.

Awọn ọkọ oju omi mẹta wa lẹgbẹ ara wọn loju omi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amosa, o ni awọn to ye iṣẹlẹ ijamba naa ṣi n sa asala fun ẹmi wọn nitori pe ibẹrubojo ati pada si agbegbe naa, pẹlu bi o ṣe jẹ oe awọn agbebọn ṣi wa kaakiri awọn igbọ to yi wọn ka.

Ninu ọrọ tirẹ, Mustapha Ahmad Gumi sọ pe, "bi awọn agbebọn naa ṣe n le araalu nibẹ kiri lo mu wọn sa asala pe ki awọn gba ori omi sa fun ẹmi awọn". O tun ṣalaye sii pe, " bi ero ṣe wa pọ babi ninu ọkọ oju omi naa lo faa ti o fi dojude".

Mustapha Ahmad Gumi fi kun ọrọ rẹ pe awọn obinrin at'awọn ọmọde lo pọ julọ ninu ọkọ oju omi naa.

Awọn miran ti iṣẹlẹ naa tun s'oju wọn sọ pe awọn ileto bii Danmaga, Tungar Maigunya, ati Nasarawar Kifi l'awọn eeyan naa ti wa.

Won ni eeyan mẹrindinlogun ni agbara ọkọ oju omi naa ka, irin igba jẹta ti yoo si ri lati wa ko awọn eeyan to n sa asala fun ẹmi wọn naa niyi ki o to dojude, lẹyin ti wọn ni awọn obinrin meji kan fi agidi wọ ọ pẹlupẹlu bi o ti ṣe jẹ pe ọkọ ọhun ti ko ero akoju tẹlẹ.