Niger: Wọ́n dáná sun obìnrin tí wọ́n ló sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀sìn Islam

Aworan yii ṣafihan awọn ọlọpaa ọkunrin meji, wọn gbe ibọn dani, dira ogun daadaa. Ọkan nini wọn bo imu rẹ pẹlu irinṣẹ kan, o si fi igo dudu si oju. Ọlọpaa kan naa tun n han fẹẹrẹfẹ lapa ẹyin, oun wọsọ alawọ aro, nigba ti awọn meji yoku wọ aṣọ dudu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ọlọpaa meji to gbe ibọn dani, dira ogun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Obinrin onile ounjẹ kan ti pade iku ojiji nipinlẹ Niger, wọn dana sun un nitori wọn lo sọrọ to lodi si ẹsin Islam ati Anọbi Muhammad.

Satide, ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni iṣẹlẹ naa waye niluu Kasuwan-Garba, ijọba ibilẹ Mariga, nipinlẹ Niger.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, onibara ọkunrin kan lo n ba iya olounjẹ naa ṣe ẹfẹ, to ni oun yoo fẹ ẹ, to si fi ọrọ Anọbi gbe fifẹ naa lẹsẹ.

Eyi ni iroyin sọ pe iya olounjẹ naa fesi si, ti awọn to wa nibẹ si sọ pe ọrọ rẹ tabuku ẹsin Islam.

Kí ni wọ́n ṣe fún un kí wọ́n tóó dáná sun ún?

Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe wi, awọn ti ọrọ obinrin naa bi ninu kọkọ mu un lọ sile Olori agbegbe Kasuwan-Garba, ẹni to fa a le awọn agbofinro lọwọ fun iwadii.

Ṣugbọn awọn ẹlẹhonu naa pọ ju, wọn gba iya olounjẹ lọwọ awọn agbofinro, wọn si sọ ina si i lara.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger fi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ọlọpaa Niger, Wasiu Abiodun, sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lorii rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Satide ni iṣẹlẹ yii waye.

Alukoro ṣalaye pe obinrin naa torukọ rẹ n jẹ Amaye, ni wọn fi to awọn leti pe o sọ awọn ọrọ kan to lodi si ẹsin Islam.

Ọrọ naa lo ni o bi awọn eeyan kan lagbegbe Kasuwan-Garba ninu.

"O ṣe ni laanu pe o di ija igboro, wọn si dana sun obinrin naa ki awọn agbofinro too de." Abiodun lo ṣalaye bẹẹ.

O ni bo tilẹ jẹ pe alaafia ti jọba lagbegbe naa, ileeṣẹ ọlọpaa koro oju si iṣẹlẹ yii, ati bi awọn kan ṣe fi ofin sọwọ ara wọn.

Alukoro ọlọpaa Niger sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to lọwọ si ipaniyan yii, awon yoo mu wọn, wọn yoo si foju wina ofin.

Ẹ o ranti pe eyi kọ ni igba akọkọ ti wọn yoo pa eeyan lori ọrọ odi ti wọn ba ni wọn sọ si ẹsin Islam lapa Oke Oya.

Loṣu Kẹfa ọdun 2023 ni wọn juko pa ọkunrin alapata kan, Usman Buda, nipinlẹ Sokoto, wọn ni o sọrọ odi si Anọbi Muhammad.

Ṣaaju ni wọn si ti fi iru iku kan naa pa Deborah Samuel, akẹkọọ-binrin nileewe ẹkọṣẹ awọn tiṣa ti i ṣe Sheu Shagari College of Education,ipinlẹ Sokoto.