Àsìkò tí ọmọ mi fẹ́ẹ́ ṣí ilé ìtajà ìgbàlódé fún mi ló jáde láyé- Ìya Sanku

Fọto yii ṣafihan iya to bi Oloogbe Abdulsamad Adetola Raji (Sanku Comedy),lapa osi. Ibanujẹ han loju iya naa, o lo ibori alawọ aro ati aṣọ kaba alawọ aro, iya naa jokoo lori aga, awọn abanikẹdun si wa lẹyin rẹ. Lapa ọtun ni aworan Oloogbe Sanku, irun ori rẹ pọ, o lẹ nnkan mọ imu rẹ, o si wọ aṣọ dudu.

Oríṣun àwòrán, BBC/ Mr Sanku Comedy

Àkọlé àwòrán, Aworan Iya Sanku ati Oloogbe funra rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Inu ẹkun, ọfọ ati ibanujẹ nla ni awọn eeyan ọdọmọkunrin alawada to di oloogbe laipẹ yii, Abdulsamad Adetola Raji, ti awọn eeyan mọ si Mr. Sanku Comedy ṣi wa lẹyin iku rẹ to waye nibẹrẹ ọsẹ yii.

Nisẹ ni ẹsẹ ko gba ero nile iya Oloogbe Sanku, ẹni to jade laye lẹyin ti ọkọ ayọkele rẹ sagbako ijamba lopopona Oyo si Ogbomoso.

Iya to bi Sanku, ẹni ti ọfọ naa kan ju, fi omije ṣalaye ọrọ fun BBC News Yoruba nigba ti a ṣabẹwo sile rẹ niluu Osogbo lọjọ keji iṣẹlẹ naa.

Ninu alaye rẹ, Iya Sanku ṣalaye pe ata ni oun ta, ọpọ ọdun si ni Oloogbe Samad fi ba ohun ta tomato ati awọn eroja ọbe, ko too lu aluyo ninu iṣẹ aderin-in-poṣonu to yan laayo.

O tesiwaju pe ilu Abuja ni oun ti ko wa siluu Osogbo, toun si n ta ata nitori airiṣe.

Iya Sanku sọ pe:

" Ọmọ mẹfa ni mo bi, Sanku lo wa nipo karun-un ninu wọn.

" Ọjọ to jade laye yii gan-an ni ọjọ ikomojade egbon rẹ obinrin, o si ti pe mi lorii foonu pe ki n gba awin gbogbo ohun ti a ba nilo fun eto isomoloruko naa.

"O ni toun ba pari ise oun titi alẹ, oun a ba mi fi owo naa ranṣẹ lati san gbese gbogbo ohun ti mo ba gba lawin.

" A ti dana tan, a ti ṣe gbogbo nnkan tan ni wọn pe mi pe ọmọ mi ti ṣagbako ijamba ọkọ, ọkọ ayọkẹlẹ ni wọn pe e fun mi.

" Sanku ko fẹ ki n ta ata mọ, o maa n sọ fun mi pe ata ti mo n ta yii n ti oun loju.

"O loun maa ṣi ṣọọbu igbalode fun mi ti maa maa ta ọja nibẹ. Maami ẹ fọkan balẹ lọmọ mi maa n sọ fun mi, mi o mọ pe ibi to maa ja si ree . Asiko to fẹẹ ṣi ṣọọbu fun mi lo pari si o.''

Bẹẹ ni iya Oloogbe Abdulsamad tawọn eeyan mọ si Sanku fi omije ṣalaye.

'Ìpènijà ojù tí Sanku ní ló sọ ọ́ di adẹrin-in poṣonu, iṣé kọ̀mpútà ló fẹ́ẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀'

Aworan bi Iya Sanku ṣe n sunkun ati bi awọn abanikẹdun ṣe yi i ka. Awọn kan jokoo silẹẹ, awọn kan si duro mọ irin ninu ile.
Àkọlé àwòrán, Iya Sanku n sunkun, awọn abanikẹdun yi i ka
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ẹgbọn Sanku ti orukọ tiẹ n jẹ Moshood, naa ba BBC News Yoruba sọrọ lori iku aburo rẹ.

Moshood ṣalaye pe Sanku ni ipenija oju, o ni iṣẹ awọn to n fi ẹrọ kọmputa ya aworan (Computer Graphics) lo fẹẹ ṣe tẹlẹ.

Ẹgbọn Oloogbe Sanku sọ pe ai riran daadaa rẹ lo jẹ ko kuku mu ìṣẹ aderin-in poṣonu laayo.

O ni lọjọ ti Sanku ku, oun ti kọkọ pe e fun iranlọwọ kan, o si ṣẹleri lati ran oun lọwọ lẹyin to ba ti da iya awọn lokowo tan.

Moshood ni ṣugbọn kokoro ko jẹ kawon gbadun obi to gbo, iku ko jẹ ki Sanku ṣe gbogbo ohun to fẹẹ ṣe.

Bakan naa ni ọre timọtimọ Sanku ti orukọ rẹ n jẹ Salam (King of prank ni ọpọ eeyan mọ ọn si) sọ pe orisiiṣii awuyewuye lo n lọ lori awọn ikanni ayelujara, ti awọn kan n sọ pe boya Sanku ṣe ogun owo ni.

Salam sọ pe Sanku jẹ oniwa pẹlẹ, nnkan ẹlomiran ko wu u ri, o si jẹ iyalenu fun oun nigba tawọn eeyan kan ni o tẹ àṣeyọrí rẹ nidii ni.

Ọjọ kin-ni-ni oṣu Kẹsan ọdun yii ni Sanku comedy padanu ẹmi rẹ ninu ijamba oko ayọkele, lopopona Ogbomosho si Oyo.

Ninu awọn marun-un to wa ninu oko naa, oun nikan lo padanu ẹmi rẹ, ti awọn mẹrin yooku si n gba itọju nile iwosan nipinlẹ Osun lasiko ti a pari iroyin yii.

Irọlẹ mọ alẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹrin oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 yii ni eto alẹ abẹlẹ (candle night) ti wọn fẹẹ ṣe fun Oloogbe Sanku yoo waye niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara.