Ta ni Sanku Comedy, gbajúmọ̀ aláwàdà orí ayélujára, tí ikú rẹ̀ ń milẹ̀ tìtì?

Oríṣun àwòrán, Mr Sanku Comedy/Facebook
O ti le ni ọjọ kan bayii ti iroyin kan to jade ti sọ pe gbajumọ adẹrininpoṣonu, Sanku Olaniyi, ti ọpọ mọ si Sanku Comedy ṣagbako ijamba ọkọ.
Iroyin ijamba ọkọ ọhun ti a gbọ pe o ṣẹlẹ niluu Odo-Oba lopopona Oyo si Ogbomoso lo ti mi ori ayelaujara titi lati ana ọjọ Aje titi ti oni.
BBC Yoruba gbiyanju lati ba ẹbi Sanku sọrọ ki a le mọ okodoro ohun to ṣẹlẹ gan an, amọ, pabo ni gbogbo igbiyanju wa jasi.
Amọ, awọn akẹgbẹ Sanku ti fi idi rẹ mulẹ pe ọdọmọde adẹrininpoṣonu naa ti jẹ Ọlọrun ni pe.
@kinat2404 to jẹ ọkan lara awọn akẹgbẹ Sanku kọ ọrọ soju opo TikTok rẹ wi pe '' Adetola mi Abdulsamad, o o sọ fun mi pe wa a tete lọ ni kiakia bayii.
Jọwọ dide nlẹ tori a si ni oriṣiiriṣii nnkan lati jọ ṣe papọ, Sanku mi.''
@kinat2404 fi oniruuru fọto Sanku soju opo TikTok rẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Funmi Awelewa naa sọrọ lori iku Sanku loju opo Instagram rẹ pe ibanujẹ nla ni ikú ọdọmọde aderininpoṣonu náà jẹ.
O ni awọn gbàdúrà nigba toun gbọ pe wọn ti gbe Sanku lọ si ile iwosan Bowen Hospital niluu Ogbomoso.
Funmi Awelewa ni "ki lo wa de bayii Oloun."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Aderininpoṣonu mii, Ozain, naa sọ loju opo Facebook rẹ pe Eledua ko Sanku lọwọ ikú ojiji lọsẹ meji sẹyìn.
O ni iyalẹnu lo wa jẹ wí pe asiko yii ni Sanku pada ku
Ta a ni Sanku ọdọmọde adẹrininpoṣonu to dolooge?
Gẹgẹ bi iroyin kan ṣe fidi rẹ mulẹ, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ni Sanku i ṣe ki o to ku ninu ijamba ọkọ lopopona Oyo si Ogbomoso.
Lọdun 2021 ni a gbọ pe Sanku bẹrẹ iṣẹ adẹrininpoiṣonu ti awọn eeyan si bẹrẹ si ni mọ ọ diẹ diẹ lori itakun ayelujara.
Amọ, lọdun 2024 ni okiki rẹ kan gẹgẹ bii adẹrininpoṣonu lẹyin to kopa ninu sikiiti kan to pa ọpọ eeyan lẹrin in.
Ẹbun ipanilẹrinin ti Eledua fi jinki rẹ ati oniruuru sikiiti ara ọtọ to maa n ṣe wa lara awọn nnkan ti ọpọ eeyan fi fẹran rẹ.
Lati igba ti iroyin iku rẹ ti jade ni ọpọ eeyan papaa julọ awọn akegbẹ rẹ ti n ṣedaro rẹ lori itakun ayelujara.
Ṣé lóòtọ́ ni gbajúmọ̀ adẹ́rìnínpòṣónú, Sanku Comedy jáde láyé lẹ́yìn tó kàgbákò ìjàmbá ọkọ̀ lọ́jọ́ Ajé?

Oríṣun àwòrán, Sanku/TikTok
Gbajúmọ̀ adẹ́rìnínpòṣónú, Sanku Olaniyi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sanku Comedy ti forí sọ̀tà ìjàmbá ọkọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, lásìkò tí Sanku ń ṣe ìrìnàjò láti ìlú Ilorin ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹsàn-án ni ọkọ̀ tó wọ̀ ní ìjàmbá ní òpópónà Ogbomoso sí Oyo.
Gẹ́gẹ́ bí fídíò tó gba orí ayélujára ṣe ṣàfihàn rẹ̀, ìjàmbá ọkọ̀ náà pọ̀ tí àwọn èèyàn méjì, èyí tí Sanku náà wà lára wọn wà nílẹ̀, tí wọn kò le dìde.
Ìròyìn ní nígbà tí wọ́n gbé Sanku dé ilé ìwòsàn Bowen University Teaching Hospital tó wà ní ìlú Ogbomoso, àwọn dókítà ní òkú rẹ̀ ní wọ́n gbé wá àmọ́ BBC News Yorùbá kò le fi ìdí èyí múlẹ̀ lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Ẹnìkan tí òun náà máa ṣe ètò lórí ayélujára, Jidex Klothing nínú fídíò kan tó fi sórí ìkànnì Instagram rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé ṣàfihàn ọkọ̀ tí Sanku wọ̀ bó ṣe bàjẹ́ tó.
Bákan náà ló ṣàfihàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà nínú ọkọ̀ tú Sanku wọ náà, tó sì jẹ́ pé àwọn kan farapa lásán ni nígbà tí àwọn kan wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run tó fi mọ́ Sanku.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti kéde ikú Sanku Comedy lórí ayélujára, tí wọ́n sì ń ṣe ìdárò rẹ̀ lórí ìkànnì X àti Instagram, kò ì tíì sí àtẹ̀jáde kankan látọwọ́ ẹbí tàbí àwọn alákòóso rẹ̀ láti fìdí ikú rẹ̀ múlẹ̀.














