'Àìsàn ibà lásán ló ṣe Shina, ọmọ Peju Ogunmola kó tó ò kú'

Oríṣun àwòrán, Peju Ogunmola/Instagram
Ọpọ eeyan lo ti n ba agba oṣerebirin, Peju Ogunmola, ti ọmọ rẹ di oloogbe, kẹdun.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji oṣu Kẹsan an, ni Shina, to jẹ ọmọ kan ṣoṣo oṣerebinrin naa, jade laye.
Botilẹ jẹ pe pupọ eeyan ni ko mọ koko ohun to fa iku ojiji fun ọdọmọkunrin ọhun lasiko ti iroyin iku rẹ jade, eyi to mu ki kaluku ma a sọ nnkan to wu u.
Amọ, alaye ti ọkan lara ẹbi naa (ti ko fẹ ki a da orukọ oun) ṣe fun akọroyin BBC ni pe, pupọ awọn ileeṣẹ iroyin lo n kọ nnkan ti oju wọn ko to lori iṣẹlẹ naa.
Onitọhun sọ eyi lasiko ti akọroyin BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ile Arabinrin Ogunmola to wa niluu Ibadan.
Lara nnkan ti ẹni naa sọ to tako si iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri ni pe oloogbe naa ko si niluu Oyinbo. O ni ilu Eko lo wa laarin awọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n ṣe iṣẹ orin ko to di pe o ni aisan iba.
"Iba lasan ni wọn pe e tẹlẹ, ṣugbọn o ni lati wa si ọdọ iya rẹ niluu Ibadan ki o le gba itọju nigba ti iba naa ko tete lọ."
Alaye ti wọn ṣe fun akọroyin wa ni pe funra oloogbe lo wọ baluwẹ lati bu omi s'ori nigba to de Ibadan ki wọn to gbee lọ si ile iwosan aladani kan nibi ti o dakẹ si.
Ọjọbọ, ọjọ kẹrin oṣu kẹsan ọdun yii sini wọn o sinku Oloogbe naa ni idakọkọ, nitori pe ọmọde ni.
Diẹ lara awọn aworan lati ile iya oloogbe naa ree.

















