Ìyàwó Mohbad ní òun ṣetán láti ṣàyẹ̀wò DNA fún Liam, bàbá Mohbad ní ìlú òyìnbó lòun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe é

Oloogbe Mohbad ati Wunmi, iyawo rẹ pẹlu Liam ọmọ wọn lọwọ Mohbad
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iyawo gbajugbaja akọrin takasufee to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad, Wunmi Aloba, ti sọ pe oun ṣetan lati gbe Liam ọmọ Mọhbad lọ fun ayẹwo DNA, lẹyin ti ileẹjọ majisireeti to wa ni Ikorodu nipinlẹ Eko paṣẹ wi pe ki wọn lọ ṣe DNA fun ọmọ naa.

Amofin Kabir Akingbolu to jẹ agbẹjọro Wunmi lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Amofin Akingbolu sọ pe ti Ọgbẹni Joseph Aloba, ti i ṣe baba Mohbad ba lo ya lonii, o ni Wunmi ṣetan lati gbe Liam lọ fun ayẹwo DNA.

Ọgbẹni Akingbolu sọ pe Wunmi o figba kankan sa fun ayẹwo DNA fun Liam, o ni baba Mohbad naa ni ko fi ara rẹ silẹ lati ṣe ayẹwo naa fun ọmọ Mohbad.

''Ile ẹjọ mẹjisireeti kan naa yii ni Ikorodu lo kọkọ paṣẹ lọdun 2024 pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo DNA fun Liam.

Ọgbẹni Aloba naa lo beere lọwọ ile ẹjọ nigba naa pe ko paṣẹ pe ki wọn ṣe ayẹwo DNA fun Liam, ile ẹjọ si gba bẹẹ.

Lẹyin naa ni a bẹrẹ sii sọ fun Ọgbẹni Aloba pe Wunmi ṣetan lati gbe ọmọ rẹ lọ fun ayẹwo ọhun.

Ṣugbọn baba Mohbad ko yọju nigba naa, nigba to ya lo sọ pe oun ko ni igboya ninu agbẹjọro oun mọ,'' amofin Akingbolu ṣalaye.

Amofin Akingbolu fikun ọrọ rẹ pe nigba to ya ni Wunmi gan an loun ṣetan lati lọ ṣe ayẹwo DNA fun ọmọ naa.

O ni lẹyin naa ni baba Mohbad pada lọ sile ẹjọ lati beere pe ki ile ẹjọ paṣẹ ayẹwo naa pada.

Baba Mohbad ni ilu oyinbo loun ti fẹ ki wọn lọ ṣe DNA fun Liam

Agbẹjọro Wunmi ni baba Mohbad sọ fun ile ẹjọ pe ilu oyinbo loun ti fẹ ki wọn ṣe ayẹwo naa.

Amofin Akingbolu sọ pe ilẹ okeere naa ni wọn maa ti n ṣe ayẹwo DNA tẹlẹ, kii ṣe ni Naijiria.

Ọgbẹni Akingbolu ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe baba Mohbah ni yoo sanwo fun ayẹwo DNA naa tori oun lo sọ fun ile ẹjọ pe oun fẹ ki wọn ṣe DNA fun Liam.

Amofin Akingbolu sọ pe Wunmi gan an fẹ ki wọn ṣe ayẹwo naa fun Liam ki awuyewuye lori ọrọ naa le dopin.

Igba meji ọtọọtọ ni BBC Yoruba pe Ọgbẹni Aloba lori ọrọ naa, amọ, pabo ni akitiyan wa jasi tori ko le ba wa sọrọ.

Iléejọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n lọ ṣe àyẹ̀wò DNA fún Liam ọmọ Mohbad

Ileẹjọ majisireeti to wa ni Ikorodu nipinlẹ Eko ti paṣẹ wi pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo DNA fun Liam Aloba, ọmọkunrin gbajugbaja akọrin takasufee to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad.

Ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ keji oṣu Kẹsan an yii ni adajọ majisireeti Adefisoye Sonuga paṣẹ naa.

Adajọ fikun ọrọ rẹ pe ile iwosan to ba fẹsẹ mulẹ daadaa ni wọn ti gbọdọ ṣe ayẹwo DNA fun ọmọ naa.

Adajọ paṣẹ yii lẹyin ti baba Mohbad, Joseph Aloba, beere lọwọ ile ẹjọ wi pe ki o paṣẹ ayẹwo DNA fun Liam tori oun fẹ mọ bo ya Mohbad lo bi ọmọ naa ni toootọ.

Orukọ Omowunmi Cynthia Aloba to jẹ iyawo Mohbad lo wa ninu iwe aṣẹ adajọ wi pe o gbọdọ gbe igbesẹ lori aṣẹ ile ẹjọ.

Nnkan ti baba Mohbad beere lọwọ ile ẹjọ

Oloogbe Mohbad ati Wunmi, iyawo rẹ pẹlu Liam ọmọ wọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, @_C33WHY_/INSTAGRAM

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgbẹni Aloba, baba Mohbad, beere lọwọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ fun ọga agba tabi akọṣẹmọṣẹ nile iwosan Military Hospital Yaba niluu Eko nibi ti oku Mohbad wa wi pe ko lo irun ori tabi ẹya ẹra oloogbe naa kan lati ṣe ayẹwo DNA fun Liam ni ile iwosan to ba forukọ silẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko tabi ile iwosan mii naa to ba fẹsẹ mulẹ.

Ọgbẹni Aloba tun beere lọwọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ wi pe ki ayẹwo DNA waye lori Liam ni ile iwosan to ba duro daadaa nilẹ okeere, ati pe oun ṣetan lati san owo ayẹwo naa.

Baba Mohbad sọ fun ile ẹjọ wi pe ko da oun loju daadaa wi pe Mohbad lo bi Liam, idi niyii toun ṣe fẹ ki wọn ṣe ayẹwo DNA fun ọmọkunrin naa.

Ọgbẹni Aloba tun sọ fun ile ẹjọ wi pe o ṣe pataki foun lati mọ daju bo ya Mohbad lo lọmọ naa ni toootọ ki oun le mọ bo ya oun yoo maa tọju rẹ gẹgẹ bii ọmọ-ọmọ oun.

Augustine Adegbemi lati ileeṣẹ amofin agba, Wahab Shittu (SAN) & Co., lo ṣoju Ọgbẹni Joseph Aloba nile ẹjọ, nigba ti amofin Kabir Akingbolu ṣoju Wunmi, iyawo oloogbe.

Lẹyin naa ni ile ẹjọ paṣẹ pe ayẹwo DNA meji gbọdọ waye lori Liam ni ile iwosan to ba forukọ silẹ pẹlu ijọba ni Naijiria ati ile iwosan to ba fẹsẹ mulẹ nilẹ okeere.

Adajọ majisireeti naa tun paṣẹ wi pe baba Mohbad ati iyawo rẹ tabi aṣoju awọn mejeeji gbọdọ wa nibi ti wọn ba ti fẹ mu nnkan ti wọn yoo fi ṣe ayẹwo naa lara oku Mohbad.

Adajọ wa sun igbẹjọ si ọjọ kọkanla oṣu Kọkanla ọdun yii.