"Ìyá mi ti kú, òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ni bàbá mi, mò ń fi ìwé ẹ̀rí NCE ta Puff-puff, kí gómìnà Adeleke tó gbà mí síṣẹ́"
Yoruba ni ori ẹni ni gbe alawore ko ni, lọjọ ti eeyan yoo ba si pade oloore, gaga ni ara yoo ya.
Bẹẹ ni ọrọ ri fun obinrin kan Oluwatosin Adejumo, ẹni to n din ohun ipanu pọfunpọfun ta, to si yara mọ isẹ.
Amọ lọjọ kan ni ori rẹ gbe pade oloore rẹ, tii se gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, lasiko ti wọn se iwọde oju popo kan nilu Osogbo.
Gomina Adeleke ra gbogbo Pọfunpọfun ti obinrin naa gbe sori ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira lasiko iwọde oju popo naa.
Amọ eyi ko tan sibẹ, se ni gomina tun fun obinrin onipọfunpọfun naa nisẹ ijọba tori Oluwatomisin naa ni iwe ẹri olukọ onipokinni NCE lọwọ.
Isẹ Alase si ni gomina fun obinrin yii nile ijọba ipinlẹ Osun to wa nilu Osogbo.
BBC News Yoruba wa kan si obinrin yii, Oluwatomisin Adejumọ lati gbọ tẹnu rẹ ati bo se rin irinajo aye rẹ, to fi pade alaanu rẹ tii se gomina.

"Sọọsi ni mo ti pade iya kan to gba mi si isẹ alase, owo isẹ alase ni mo tu jọ, fi wa bẹrẹ si din Pọfunpọfun ta"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Oluwatosin Adejumọ ni kii kuku se gomina Ademola Adeleke ni oun wa lọ lọjọ ti isẹlẹ naa waye.
Amọ oun lọ si iwaju ile ijọba ni Abere nilu Osogbo, lati lọ ta ọja ti oun lọjọ naa ni.
"Ọdun mẹrin sẹyin ni mo padanu iya mi, lati igba yẹn, o nira fun mi lati tẹsiwaju tori oun ko ni isẹ lọwọ.
Mo sa n foriti, lootọ ni baba mi jẹ osisẹ ijọba amọ emi naa ni mo n tiraka lati tọju wọn.
Sọọsi ti mo n lọ ni mo ti pade iya kan to gba mi tọwọ tẹsẹ gẹgẹ bii ọmọ.
Alase ni mama yii, ti wọn ba si ti gba isẹ alase, wọn maa n mu mi dani, mo si maa n tẹle wọn.
Owo isẹ alase yii ni mo tu jọ, titi ti mo fi wa bẹrẹ si ni maa din Pọfunpọfun ta.
Mo maa n gba awọn eroja Pọfunpọfun yii ni awin ni, ti mo ba ti ta ọja tan, maa lọ da owo naa pada."
"Puffpuff ni mo lọ ta niwaju ile ijọba, ni mo pade gomina to fi N50,000 ra ọja mi, o tun fun mi nisẹ ijọba"
Oluwatomisin Adejumọ sọ siwaju fun BBC News Yoruba pe oun ni iwe ẹri olukọ NCE lootọ, ti oun si ti se isẹ Tisa ri nibi ti oun ti n kọ awọn akẹkọọ ni A for Apple.
"Nigba ti mo jokoo, ti mo se isiro pe ti mo ba gbe igba pọfunpọfun yii, owo ti maa ri nibẹ yoo ju owo ti mo n ri nidi isẹ olukọ lọ.
Ni ọjọ ti mo pade gomina, kii ku se awọn ni mo wa lọ, mo lọ ta Pọfunpọfun niwaju ile ijọba ni Abere nilu Osogbo ni.
Ko pẹ ti mo de ibẹ, ni awọn eeyan n yọ mọ wọn, bẹẹ ni emi naa bẹrẹ si ni yọ mọ wọn, ti mo n pariwo imọlẹ Adeleke.
Bi gomina Adeleke se pe mi niyẹn, wọn beere ọja ti mo gbe sori tii se Pọfunpọfun, wọn fun mi ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, ti wọn si pe mi wọle.
Wọn n beere ibeere lọwọ mi, pe se mo lọ sile iwe, wọn si ri pe akẹkọjade ni fasiti ni mi, ti wọn si fa mi le Kọmisana Ajeigbe Olusoji lọwọ.
Wọn ti gba awọn iwe ẹri mi, wọn ti n se akọsilẹ nipa mi amọ oun to ku ni ki n gba iwe igbanisisẹ."

"Ohun to ku mi ku bayii ni lati ran baba mi, to jẹ osisẹ fẹyinti lọwọ, ati aburo mi"
Amọ lọwọlọwọ bayii, Oluwatosin ti gba iwe igbanisisẹ lọdọ ijọba ibilẹ Osun.
Bakan naa lo gba awọn ọdọ ni imọran pe ki wọn mase tiju isẹ oojọ wọn tori idi isẹ ẹni la ti n mọ ni ni ọlẹ.
"Mo n gba awọn ọdọ ẹlẹgbẹ mi nimọran lati mase tiju isẹ ti wọn n se niwọn igba ti ko ba ti lodi si ijọba tabi ilana Ọlọrun.
Mo dẹ tun n gba awọn akẹẹgbẹ mi nimọran lati lọ kọ isẹ ọwọ tori atẹlẹwọ ẹni, kii tan ni jẹ.
Bakan naa, ohun to ku mi ku bayii ni lati ran baba mi to jẹ osisẹ fẹyinti lọwọ ati aburo mi."






