Kókó pàtàkì nípa Tyler Robinson, afurasí tí wọ́n mú pé ó yìnbọn pa Charlie Kirk l'Amẹrika

Aworan yii ṣafihan Tyler Robinson, akọkọ fi oju rẹ han,nigba ti ikeji fi egbẹ oju rẹ han. Eeyan pupa ni Tyler, irun ori rẹ lẹ mọlẹ, o wo aṣọ dudu.

Oríṣun àwòrán, HANDOUT

Àkọlé àwòrán, Tyler Robinson ti ọlọpaa fi aworan rẹ lede bii afurasi to yinbọn pa Charlie Kirk.
    • Author, Tiffanie Turnbull
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Lẹyin iku ojiji to pa Charlie Kirk, alajọṣepọ timọtimọ si aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, ọwọ ti ba ọdọkunrin kan, Tyler Robinson, gẹgẹ bii afurasi to yinbọn pa a.

Tyler Robinson, ẹni ọdun mejilelogun (22) to jẹ ọmọ bibi ilu Utah ni ọwọ ba lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 yii lori iku Charlie Kirk.

Eyi waye lẹyin to jẹwọ fun baba rẹ pe oun ni oun yinbọn mọ Charlie Kirk nibi ti Oloogbe naa ti n ba ọpọ eeyan sọrọ ni Yunifasiti Utah.

Baba Tyler, Matthew Carl Robinson, lo gba a niyanju lati lọ fa ara rẹ kalẹ fáwọn ọlọ́pàá

Baba Tyler, Matthew Carl Robinson, lo gba a niyanju lati lọọ fa ara rẹ kalẹ, gẹgẹ bi CBS News ni US, alajọṣe BBC ṣe fidi ẹ mulẹ.

Bakan naa ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI to ti kọkọ fi aworan kan ti ko fi gbogbo han sita nipa afurasi naa, sọ pe o da oun loju pe Tyler Robinson ni afurasi to wa ni ahamọ bayii.

Nibi ipade awọn oniroyin ti wọn ṣe lọjọ Ẹti, FBI ṣalaye pe awọn ṣi wa nidii ọrọ naa lati mọ idi ti afurasi yii fi gbe igbesẹ iku to pa Kirk.

Aworan Tyler Robinson ti ko fi bẹẹ han ti FBI fi sita. O wọ aṣọ dudu, de fila dudu, o si lo igo dudu si oju rẹ

Oríṣun àwòrán, FBI

Àkọlé àwòrán, Aworan Tyler Robinson ti FBI fi sita.

Ta a ni Tyler Robinson?

Bo tilẹ jẹ pe FBI ko fi alaye kikun sita nipa ẹgbẹ oṣelu ti Tyler Robinson n ṣe , tabi ipilẹ rẹ, Gomina ilu Utah, Spencer Cox, sọ pe ẹbi rẹ kan ṣalaye pe Tyler ti n da si ọrọ oṣelu lati bii ọdun meloo sẹyin.

O ni mọlẹbi Tyler naa sọ pe ṣaaju igba to yinbọn mọ Kirk ni afurasi naa ti n sọ nipa ohun ti Oloogbe fẹ lọ ṣe ni Utah Valley University.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Wọn sọrọ nipa idi ti wọn ko fi fẹran rẹ ati eronga rẹ." Gomina Cox lo sọ bẹẹ.

Akọsilẹ nipa Robinson, eyi ti BBC ri, fi han pe ọdọmọkunrin naa ko ni ẹgbẹ oṣelu kan pato tẹlẹ.

Awọn obi rẹ, Matthew Carl Robinson ati Amber Denise Robinson ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican, gẹgẹ bi akọsilẹ wọn lorilẹede naa ṣe sọ.

Koda, ko si orukọ Robinson gẹgẹ bii akẹkọọ nileewe giga Utah ti iṣẹlẹ ibọn yinyin ti waye.

Atẹjade kan ti awọn alaṣẹ Utah Board of Higher Education fi sita,

ṣalaye pe Tyler James Robinson jẹ akẹkọọ onipele kẹta ni Dixie Technical College tẹlẹ.

Ẹkọ nipa ina mọnamọna ni wọn lo n kọ nibẹ.

Akọsilẹ ori ayelujara fi han pe Baba Tyler Robinson ni ile ounjẹ igbalode, nigba ti iya rẹ jẹ oṣiṣẹ ode.

Oju opo ayelujara kan ti gbesẹ le abala ti afurasi yii n lo, wọn lo tako ilana awọn.

Ni bayii, Robinson ṣi wa ni ahamọ, bi wọn ṣe n to iwe ẹsun rẹ pọ lati foju rẹ ba ile ẹjọ.

Bakan naa ni iwadii n lọ lorii ipilẹ ọdọmọkunrin naa, ohun to gbagbọ ati awọn ẹgbẹ to n ba ṣe

Ṣugbọn awọn awoye iṣẹlẹ l'America n sọ pe o han kedere pe ipaniyan yii lọwọ oṣelu ninu.

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Charlie Kirk ṣe waye

Aago mejila kọja iṣẹju mẹtalelogun ọsan Ọjọru, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 ni wọn yinbọn mọ Charlie Kirk.

Laaarin iṣẹju mẹrindinlogun, awọn agbofinro gba ibẹ kan.

FBI fi awọn fọto afurasi sita ni aago mẹwaa owurọ keji.

Wọn kede lati fun ẹni to ba le pese ọna ti wọn yoo fi mu afurasi naa ni $100,000 laaarọ Ọjọbọ .

Aago mẹjọ ni gomina ṣepade pẹlu awọn oniroyin, nibi ti wọn ti fi aworan ati fidio afurasi lede.

Aago mẹwaa alẹ ni wọn mu afurasi pamọ si ahamọ.

Àkọlé fídíò,

Charlie Kirk, alajọṣepọ timọtimọ si aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, ni agbebọn kan yin ibọn lu, to si ṣekupa lẹsẹkẹsẹ lasiko to n sọrọ lọwọ ni bi ayẹyẹ kan ni Fasiti Utah.

Ọpọ nnkan lo si ṣokunkun lori iṣẹlẹ naa ṣugbọn awọn nnkan ti a mọ ree.

Kirk, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, ni wọn ransẹ pe ko wa sọrọ nibi ayẹyẹ Fasiti Utah, to si jokoo si abẹ orule funfun, to n ba awọn eeyan bi ẹgbẹrun mẹta sọrọ ni ita gbangba.

Ki lo ṣẹlẹ?

Gẹgẹ bii oṣojumikoro ṣe ṣalaye ati awọn fidio ti a ri, oloogbe naa n dahun si ibeere nipa wahala ibọn nigba ibọn kan dun ni deede ago mejila kọla ogun isẹju.

Lẹsẹkẹsẹ ni ẹjẹ n da nibi ọrun Kirk ṣaaju ki awọn eeyan to ya danu kuro nibi ti iṣẹlẹ ti waye.

"Mo gboro ibọn, o dun gbaaa, ti mo si oku Kirk," Oṣojumikoro sọ fun awọn akọroyin.

"Gbogbo wa da dubulẹ, mo fẹ le sọ pe a wa ni ibẹ fun bi isẹju kan ṣaaju ki gbogbo to bẹrẹ si ni ma sare ," Emma Pitts, akọroyin lati ileeṣẹ iroyin Deseret.

Aworan Charlie Kirk nigba to sọrọ nibi ipolongo ibo fun Trump ni ọdun 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Charlie Kirk

Wọn sare gbe Kirk lọ si ile iwosan pẹlu ọkọ aladani kan, Lẹyin ọpọ wakati, Trump kede iku Kirk lori opo ayelujara Truth Social.

Ọgba fasiti naa ti da paro, ti awọn alaṣẹ si ti n wa eeyan to yin ibọn naa.

Iyawo Kirk ati awọn ọmọ rẹ meji wa nibi iṣẹlẹ naa ṣugbọn alaafia ni wọn wa. Ko si ẹnikẹni to wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye to farapa yatọ si Kirk to padanu ẹmi.

Ta ni afurasi?

Àkọlé fídíò,

Awọn alaṣẹ ni iṣẹlẹ iṣekupani ni eyi- ṣugbọn a ko ti mọ eeyan to yin ibọn lu Kirk ati idi to fi ṣe bẹ.

Ọwọ tẹ eeyan meji lẹyin ọpọ wakati ti iṣẹlẹ naa waye, ti wọn si f wọn lẹ pada. Wọn ko ni ajọsepọ kankan pelu iṣẹlẹ na, awọn alaṣẹ Utah kede.

"Iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii," awọn alaṣẹ ṣalaye.

Ọpọ eeyan ni wọn ti da sita lati ṣawari eeyan to yin ibọn naa. Wọn ti ilẹ ẹkọ fasiti naa pa, ti awọn ọlọpaa si n lọ soju kokan lati wa eeyan to yin ibọn naa, Akọrọyin BBC, Regan Morris royin lati ọgba ile ẹkọ naa.

Awọn alaṣẹ ni awọn gbagbọ pe afurasi naa yin ibọn lati ori ile kan to sunmọ ibi ti Kirk ti n sọrọ.

Awọn ti n wo opo CCTV, ti wọn si gbagbọ pe afurasi naa wọ aṣọ dudu.

BBC Verifyti n wo awọn fọnran lori ayelujara eyi ti awọn eeyan ni ṣafihan agbebọn naa lori ile to ti yin ibọn ọhun.

Wọn gbe fọnran naa sori ayelujara, ṣugbọn a ko le fidi rẹ mulẹ.

Ta ni Charlie Kirk?

Kirk ati Aarẹ Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kirk ati Aarẹ Trump

Kirk jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ oṣelu conservative, to tun sunmọ Aarẹ Trump. O jẹ alejọ nibi eto iburawole Trump, to si ma n lọ ile ijọba lorekore.

Ni ọdun 2012, to wa ni ẹni ọdun mejidinlogun, o darapọ mọ eeyan da ileeṣẹ Turning Point USA (TPUSA), ileeṣẹ awọn akẹkọọ ti erongba rẹ jẹ pinpin awọn ero ẹgbẹ oṣelu conservative ni awọn ile ẹkọ giga.

O di ilumọka fun bi o ṣe gbe eto ijiroro silẹ kaakiri awọn ile ẹkọ kaakiri orilẹede, to si n sọrọ kaakiri awọn ile ẹkọ, gẹgẹ bii o ṣe n ṣe lasiko ti ibọn ba.

Kirk ni ọpọ eeyan ti ko gba tiẹ ṣugbọn o ni awọn ololufẹ ti wọn fẹran rẹ.

Wọn ma n gbe oriyin fun ipa to ko lati ri daju pe awọn ọdọ dibo fun Aarẹ Trump lasiko eto idibo to kọja.

O jẹ ọkan gbogi ninu iṣejọba Aarẹ Trump.

Àkọlé fídíò, Awọn oṣojumikoro