Bàálù Air Peace balẹ̀ síbi tí kò tọ́, ìwádìí ní awakọ̀ bàálù méjì mu ọtí, fa igbó, kí wọ́n tó wa bàálú

Oríṣun àwòrán, @NigeriaStories
Ajọ to n ri si abo ọkọ ofurufur ni Naijiria, Nigerian Safety Investigation Bureau (NSI), ti fidi rẹ mulẹ pe awọn awakọ baalu Air Peace meji kan lo oogun oloro ki wọn to fo.
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede lọjọ Ẹti, o ni ayẹwo oogun ti wọn ṣe fun awọn awakọ mejeji fi han pe oogun oloro wa ninu ẹjẹ wọn ki wọn to wa ọkọ ofurufu Boeing 737 kan to gbe eeyan mẹtalelọgọrun.
Ayẹwo ẹjẹ tun fi han pe ẹlomiran to tun jẹ oṣiṣẹ inu baalu naa fa igbo ṣaaju ki wọn to fo.
"Baalu Air Peace balẹ si 2,264 mita kuro ni oju ibi to yẹ ko balẹ sì, àwọn awakọ̀ rẹ̀ méjèèjì tí da nnkan saya"
Baalu ọhun gbera kuro niluu Eko lọ siluu Port Harcourt amọ ko balẹ bo ṣe yẹ ko balẹ, eyii to mu ifura lọwọ.
Wọn ni baalu ọhun balẹ si nnkan bii 2,264 mita kuro ni oju ibi to yẹ ko balẹ si ko to duro ni igba mita kọja ibi to yẹ ko duro si.
NSI ni "Gbogbo awọn ero inu ọkọ ọhun jade kuro nibẹ laaye lai si ipalara kankan."
Ajọ ọhun sọ siwaju si pe iwadii awọn fi han pe wọn mu ọti, igbo atawọn oogun mii to le mu ki eeyan ṣíṣe lasiko ti wọn n wa baalu ọhun.
Sisa ere kọja ibi to yẹ ki baalu balẹ si maa n waye lọpọ igba ti oju ọjọ ko ba ṣe dede ti awakọ baalu ko si ri iwaju rẹ daadaa.
Gẹgẹ bi NSI ṣe sọ, aṣiṣe awọn eeyan naa fidi rẹ mulẹ pe wọn ko wa lasan, wọn ti da nnkan si aya.
Lẹyin atẹjade yii ni ajọ ọhun gba ileeṣẹ Air Peace lamọran lati ṣe idanilekọọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ, ko wọn ṣi maa ṣayẹwo wọn daadaa ki wọn to bẹrẹ iṣẹ.
Kí ni iléeṣẹ́ bàálù Air Peace sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Wàyí o, iléeṣẹ bàálù Air Peace tí fèsì lórí iwadi ti àjọ NSIB gbe síta.
O ni oun ko tii tẹ́wọ́ gba èsì àbájáde iwadii àjọ náà nípa ayẹwo tó ṣe fún àwọn awakọ̀ bàálù òun méjì.
Iléeṣẹ́ Air Peace ni loore koore ni òun máa ń ṣe ayẹwo fún àwọn ọtí líle àti mímú oogun olóró fáwọn oṣiṣẹ òun, àmọ́ àwọn ko ti gbọ nípa àbọ̀ ìwádìí àjọ NSIB náà.
"A ní òfin tó lágbára èyí tó tako ọtí líle nígbà tó bá kú wákàtí mẹ́jọ kí bàálù tó fò gẹ́gẹ́ bí ìlànà àti òfin bàálù fifo ṣe laa kalẹ.
Idi sì rèé tí a ṣe máa ń ṣe ayẹwo oore koore fáwọn oṣiṣẹ wá."
Ileeṣẹ bàálù wo ni Air Peace?
Air Peace ni ileeṣẹ ọkọ ofurufu to tobi julọ ni Naijiria, o si maa n gbe awọn ero labẹle ni Naijiria ati loke okun.
Lara awọn ibomii ti Áìr Peace maa n ko awọn eeyan yatọ si Naijiria ni London, Saudi Arabia, Dakar, Freetown, Monrovia ati Ghana.
Ajọ to n ri si irinkerindo ọkọ ofurufu lagbaye, International Civil Aviation Organisation (ICAO) sọ pe ewu nla ni ki awakọ ofurufu maa da nnkan si aya ko to wa baalu, ko si bojumu rara.















