Trump lé àwọn adúláwọ̀ wá sí Ghana, ọmọ Nàìjíríà ló pọ̀ jùlọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ John Mahama orilẹede Ghana ti fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan lati ẹkun iwọ oorun Afirika ti Aarẹ Donald Trump le kuro lorilẹede Amẹrika ti balẹ si Ghana.
Eyi waye lẹyin ti orilẹede Ghana tọwọ bọ iwe adehun pẹlu Amẹrika lati tẹwọ gba awọn eeyan naa.
Lasiko ti Aarẹ Mahama n bawọn akọroyin sọrọ lanaa Ọjọru ọjọ kẹwaa oṣu yii ni o fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan lati ẹkun iwọ oorun Afirika naa ti Trump le kuro l'Amẹrika ti de si orilẹede Ghana.
Aarẹ Mahama loun tẹwọ gba awọn eeyan naa tori wọn o nilo fisa lati wọ orilẹede Ghana.
Mẹrinla lawọn eeyan naa ti wọn de si Ghana lati Amẹrika.
''Ṣaaju ni ijọba Amẹrika kan si wa lati tẹwọ gba awọn eeyan lati ẹkun iwọ oorun Afrika ti wọn fẹ le pada wale.
Ijọba Ghana gba pẹlu Amẹrika lati gba awọn eeyan naa tori wọn o nilo fisa lati wa si Ghana,'' Mahama ṣalaye.
Lati igba ti Trump ti wọle ibo aarẹ fun saa keji ni o ti n kede oniruuru ọna lati ṣatunṣe bawọn eeyan lati ilẹ okeere ṣe n wọ orilẹede Amẹrika papaa julọ lọna ti ko ba ofin mu.
O ti n han si gbogbo eeyan bayii ọna ti Trump fẹ gba lati ṣe awọn atunṣe naa, pẹlu bi o ṣe n le ọpọ eeyan kuro lorilẹede Amẹrika bayii.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Trump yoo le awọn eeyan lati ilẹ okeere kuro l'Amẹrika
O dabi ẹni pe ijọba Amẹrika ti sọ ilẹ Afirika di ibi ti wọn fẹ maa n ko awọn ọdaran l'Amẹrika lọ bayii.
Ṣaaju ki Amẹrika to ko awọn eeyan kan lati ilẹ okeere lọ si aarin gbungbun ati ẹkun guusu ilẹ Amẹrika ni wọn ti kọkọ ko awọn ọkunrin mejila kan lọ si orilẹede Mexico, Myanmar, Yemen, Eswatini ati South Sudan.
Amẹrika tun bẹ awọn orilẹede kan l'Afirika lati maa tẹwọ gba awọn eeyan tawọn orilẹede abinibi wọn ba kọ lati gba.
Ninu isọri awọn orilẹede bẹẹ ni Ghana wa, eleyii si ti di nnkan tawọn ọmọ orilẹede Ghana n sọ nipa rẹ.
Awọn wo lawọn eeyan ẹkun iwọ oorun Afirika ti wọn le l'Amẹrika gan an?
Awọn ọmọ Naijiria lo pọju ninu awọn eeyan ẹkun iwọ oorun Afirika ọhun ti wọn le l'Amẹrika gẹgẹ bi aarẹ Ghana ṣe ṣalaye.
Aarẹ Mahama ni awọn ọmọ orilẹede Gabon naa wa ninu wọn.
Aarẹ Mahama sọ pe ijọba Ghana ti pese ọkọ ti yoo gbe awọn ọmọ Naijiria naa lọ si orilẹede wọn.
O ni ijọba Ghana yoo ba olu ileeṣẹ Gabon ni Ghana sọrọ lati ṣeto ọkọ ofurufu ti wọn yoo gbe awọn ọmọ orilẹede naa pada si ilu wọn.
Idi ti Ghana fi n tẹwọ gba awọn ti wọn le kuro l'Amẹrika?
Mahama ni orilẹede Ghana n tẹwọ gba awọn eeyan ẹkun iwọ oorun Afirika ti wọn le lati Amẹrika tori o wa lara adehun awọn orilẹede ajọ ECOWAS lati faye gba lilọ lati ibikan si ibomiran lẹkun naa.
O ni adehun yii fun awọn eeyan ẹkun iwọ oorun Afirika lanfaani lati rinrin ajo lọ si orilẹede to ba wu wọn lẹkun iwọ oorun Afirika lai ni fisa fun oṣu mẹta gbako.
Aarẹ Mahama ni kii ṣe nnkan ti ko dara ti Ghana ba tẹwọ gba awọn ọmọ orilẹede mii lẹkun iwọ oorun Afirika.















