Ìlú Joromo Osin rèé, ìlú tó gbajúmọ̀ fún Òrí ṣíṣe, táwọn obìnrin ibẹ̀ sì ń fi okoòwò Òrí ṣe oríire
Ilu Joromo Osin jẹ abule kan to wa ni ijọba ibilẹ guusu Ilorin, ohun ti wọn si m ọ se julọ nibẹ ni ori.
Abule Joromo Osin yii si lo gbajumọ julọ fun ori sise jakejado Naijiria eyi ti awọn obinrin ibẹ n se julọ.
BBC News Yoruba de ilu yii ati ọkan lara awọn ibudo ti wọn ti n se ori sit ani abule naa.
A ba awọn obinrin to n se Ori nibẹ sọrọ, ti wọn si salaye bi Ori sise se bẹrẹ, bi wọn ti n se, oore ti wọn ri nidi Ori sise ati ipenija to n ba wọn finra.
Koda, wọn tun sọrọ lori bi ijọba apapọ se gbẹsẹ le iwa kiko eso ori lọ ta loke okun.

Awọn obinrin to n ori ti se oriire nidi isẹ Ori sise bii kikọ ile, ran ọmọ nile ẹkọ, se ayẹyẹ ominira fun awọn ọmọ to kọ isẹ ọwọ
Nigba ti ọpọ awọn obinrin to n se Ori naa n ba BBC News Yoruba sọrọ ni isẹ alarubarika ni, to si jẹ isẹ abinibi ati atọwọdọwọ.
Wọn ni ọjọ ti pẹ, ti awọn ti n se Ori ni kekere, ọwọ si ni wọn fi n pa eso ori, ki wọn to fi odo lọ ọ.
Wọn ni ori sise ti mu ki ilu Joromo Osin gbajumọ kaakiri agbaye.
Koda, wọn ni awọn ti se oriire nidi isẹ Ori sise bii kikọ ile, ran ọmọ nile ẹkọ, se ayẹyẹ ominira fun awọn ọmọ to kọ isẹ ọwọ.
Nigba ti wọn n sọ nipa ipenija to n koju wọn, awọn obinrin to n se Ori naa salaye pe owo ti wọ̀n n ra eso ori ti wọn pupọ ju.
Wọn ni bi wọn se n ko eso naa lọ soke okun lati fi se eroja ti wn fi n se ọda lo fa alekun owo eso ori naa.
Wọn kan saara si ijọba Tinubu pe o gbẹsẹ le kiko eroja naa lọ soke okun tori igbesẹ tita eso ori silẹ okeere le gba isẹ lọwọ awọn.







