Àṣírí tú, ọkùnrin tó pé ara rẹ̀ ní 'Obi of Lagos’ kà bòròbòrò lọ́dọ̀ ọlọ́pàá nípa jìbìtì tó fẹ́ lù

Aworan

Oríṣun àwòrán, Lagos state Police Command

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ni ọkunrin ti ọwọ tẹ pe o n pe ara rẹ ni Obi of Lagos, Chibuike Azubike, ti jẹwọ pe ayẹyẹ ifinijoye to gbe kalẹ, jẹ nnkan to fẹ fi lu awọn eeyan ni jibiti.

Ileesẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko lo si asọ loju ọrọ yii ninu atẹjade ti igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa naa, Babaseyi Oluseyi fi sita lọjọ Kọkanla, oṣu kẹsan an, ọdun 2025.

Bẹẹ ba gbegbe, Azubike, ẹni ọdun marundinlaadọrun, ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ pe o n pe ara rẹ ni "Obi of Lagos", eyi to tumọ si Ọba ilu Eko.

Ọwọ tẹ Azubike ni Ọjọru, ọjọ kẹwaa oṣu kẹsan an ọdun 2025 pẹlu awọn mẹta mii lasiko ti wọn n gbaradi fun ayẹyẹ ifinijoye naa, ti wọn ni wọn fẹ fi lu awọn eeyan ni jibiti.

Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu atẹjade naa, Azubike ati awọn ẹmẹwaa rẹ n gbaradi lati ko owo toto N1,5bn jọ lati fi kọ aafin fun Obi of Lagos, lọjọ Ṣatide, Ọjọ kẹtala oṣu kẹsan an ọdun 2025 ni gbọngan Apple Hall ni Amuwo Odofin, nilu Eko.

Oluseyi ni, "Azibuke jẹwọ lasiko ifọrọwanilẹnuwo pe ayẹyẹ ifinijoye naa loun gbe kalẹ lati lu awọn eeyan ni jibiti.

"O tun jẹwọ pe, oun kii ṣe onimọ ẹrọ to yanranti gẹgẹ bi o ṣe ti n pe ara rẹ.

Iwadii tun fihan pe, ayẹyẹ ifinijoye to gbe kalẹ, pe oun fẹ kọ aafin Obi of Lagos, jẹ ohun to fẹ fi lu awọn eeyan ni jibiti," Oluseyi ṣalaye.

O fikun pe Azubike gbe igbesẹ naa lai fi igbesẹ rẹ ọhun to ileeṣẹ ijọba to n risi eto ifinijiye nipinlẹ Eko leti.

"Afurasi ati awọn ẹmẹwaa rẹ yoo foju ba ileẹjọ lẹyin iwadii wa."

Aworan Olawale Oshun

Oríṣun àwòrán, X/Lagos Police Command/

Ẹgbẹ́ Afenifere korò ojú sí òyè ‘Obi of Lagos’, ìgbẹ́sẹ̀ tó fẹ́ gbé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà rèé

Ẹgbẹ Isọkan ilẹ Yoruba, Afenifere ti koro oju si bi ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ, Chibuke Azibike, ẹni to kede pe oun fẹ jẹ Obi ti ilu Eko.

Ẹgbẹ Afenifere wa koro oju si igbesẹ naa, to si ṣapejuwe rẹ bii eyi ti ko ni mu ọpọlọ dani rara.

Olawale Oshun, ọkan lara agbagba ilẹ Yoruba ba BBC News Yoruba sọrọ nipa isẹlẹ naa.

Oshun ni ilu kọọkan ni eto nipa bi wọn ṣe n ṣe idari Ilu ati aṣa ṣugbọn igbesẹ jijẹ Obi nilu Eko, da bi pe kii eeyan dide lati ilẹ Yoruba pe oun fẹ lọ jẹ Olootu ijọba ilẹ UK.

"Ti ẹ ba gba mi laaye, eyi ko mu ọpọlọ dani rara, ki lo fa ti ẹya Igbo maa ni oun fẹ jẹ Obi of Lagos to tumọ si Ọba ilu Eko"

"Lọtẹ yii, a ma jẹ ki wọn mọ pe eyi ko ṣeeṣe rara, tẹlẹ a ma n ro pe a ko fẹ ijangbọn ṣugbọn eyi ki ṣe ijangbọn"

Oshun ni idi ti eyi fi n waye ni pe ọpọ arosọ lo da lori pe Ilu Eko ki ṣe ilu ẹnikẹni.

"Ṣe mo le lọ si Ilu Aba ni bayii, ki n sọ pe Aba ki ṣe ilu Igbo tabi ki i ṣe ilu ẹnikẹni.

"Wọn n fi ọbọ yii lọ Yoruba nitori a gba gbogbo eeyan laye pe ki wọn wa si ilu wa lati wa ṣe orire.

"Awọn naa ni ilu wọn, ti awọn eeyan ti n ṣe orire, wọn ni Aba, wọn ni Onitisha, ti wọn ti n taja, ti ẹnikẹni ko si ba wọn du nnkan yii ṣugbọn eyi da bi pe wọn fi ọwọ rẹ eeyan ni imu."

Ọshun fidi rẹ mulẹ pe, Yoruba yoo kọ eyi fun ẹni to pe ara rẹ ni Obi of Lagos.

"Lọtẹ yii, a ma jẹ ki wọn mọ pe eyi ko ṣeeṣe rara. Tẹlẹ a ma n ro pe a ko fẹ ijangbọn ṣugbọn eyi ki ṣe ijangbọn.

"Ti eeyan ba fi ọbọ kan lọ, nigba to ba dakẹ, ẹlomiiran a tun fi ọbọ lọ rẹ."

Ọba alayé kan nílẹ̀ Yorùbá fọnmú, ó pe 'Obi of Lagos' lẹ́jọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, X/Lagos Police Command

Ori ade kan nipinlẹ Osun, Olukosi ti Ilukosi-Ijesa, Oba Ọmọtoyosi Bayo Akinleye ti fariga lori igbesẹ bi ọkunrin ẹya igbo kan, Chibuike Azubike, ṣe fẹ fi ara rẹ jẹ oye 'Obi of Lagos'.

Oba Akinleye pin fọnran to ti n fi ibinu rẹ han lori ikede ti Obi of Lagos gbe sita lati fi kede ifinijoye rẹ ni agbegbe Amuwo Odofin nipinlẹ Eko.

O ni oun yoo pe Obi ọhun lẹjọ, ti oun yoo si tun da ọrọ naa silẹ ninu ipade lọbalọba.

"Mo ti ke si awọn ikọ mi pe ki wọn pe ọkunrin kan, ti orukọ rẹ n jẹ Chibuke Azibike to n pe ara rẹ ni Obi of Lagos lẹjọ, ti ma si tun da ọrọ naa silẹ lasiko ipade awọn lọbalọba to n bọ lọjọ Ẹti.

"Iwa yii tako asa awọn eeyan wa, ti ko si ni lọ bẹẹ," Ọba Akinleye kọ ọrọ naa soju opo X rẹ.

Ọrọ ti Ọba Olukosi Ikosi Ijesa kọ soju opo X rẹ

Oríṣun àwòrán, @letsbuildnew9ja

Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ fún ‘Obi of Lagos’ tó fẹ́ jọba l‘Eko, fi N1.5bn kọ́ ààfin rẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ, Chibuike Azubike, fun bi o ṣe fi ara rẹ jẹ oye, to si n pe ara rẹ ni "Obi ti ilu Eko".

Azubike, ẹni ọdun marundinladọrin ni ọwọ tẹ pẹlu eeyan mẹta lasiko ti wọn fi ara wọn jẹ oye ni ilana ti ko ba ofin mu.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni igbesẹ yii waye lẹyin ti o da bi pe ifinijoye fẹ da wahala silẹ laarin awọn ọdọ lori ayelujara.

Aworan iwe ipeni fun ifinijoye

Oríṣun àwòrán, X/Lagos Police Command

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Azubike, ẹni to wa lati ilu Obodoukwu ni ijọba ibilẹ Ariwa Ideato nipinlẹ Imo, ni ọwọ tẹ pẹlu Oloye Chibuzor Ani (57), Oloye Martins Nwaodika (65), ati Ikechukwu Franklin Nnadi (41).

Bẹẹ ba gbagbe, ọwọ tẹ ọkurin ti orukọ rẹ n je Frederick Nwajagu, to pe ara rẹ ni Eze Ndigbo ti agbegbe Ajao Estate nipinlẹ Eko.

Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olohundare Jimoh ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede ni kete ti ọlọpaa gbọ si iṣẹlẹ naa ni ileeṣẹ ọlọpaa gbera si agbegbe naa.

O fikun pe iwadii ti bẹrẹ, ti awọn afurasi yoo si foju ba ile ẹjọ laipẹ.

Jimoh tun wa ṣekilọ pe ki awọn araalu lati tako igbesẹ awọn eeyan ti wọn fi ọna eburu gba aṣa, to si tun fikun pe iwa yii tako ofin orilẹede Naijiria, to si le da alaafia ilu laamu.

Ki se igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ yii yoo waye nipinlẹ Eko.

Bẹẹ ba gbagbe, ọwọ tẹ ọkurin ti orukọ rẹ n je Frederick Nwajagu, to pe ara rẹ ni Eze Ndigbo ti agbegbe Ajao Estate nipinlẹ Eko.

Ijọba ipinlẹ eko gbe Eze Ndigbo ti agbegbe Ajao Estate, Frederick Nwajago, lọ sile ẹjọ lori ẹsun igbesumọmi.

Ẹsun mẹsan-an ọtọtọ ni wọn fi kan afurasi naa nile ẹjọ giga to wa ni gbagede Tafawa Balewa Square, l'Eko.

Lara ẹsun naa ni pe o n "hu iwa igbesumọmi, o kopa ninu igbesumọmi, o n ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ ti ijọba ti fofin de, o gbiyanju lati ṣe iranlọwọ owo fun igbesumọmi ati pe o n mura lati wu iwa igbesumọmi" niluu Eko.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post