Àfojúsùn láti dé ibi gígá tí àwọn àgbà òṣèré ti dé ló jẹ́ ká tẹpá mọ́ṣẹ́ - Trending Kidz
Gbajumọ ni wọn lawọn oju opo ayelujara bii Tiktok, Facebook ati Instagram, iyẹn awọn ọdọmọde kan ti a mọ si Trending Kidz, ti wọn maa n fi ede Yoruba ṣe ere oniṣe lori akọle ọtọọtọ to ba n jẹ jade.
Gẹgẹ bi alaye Aina Oluwatobilola to sọrọ lorukọ awọn oṣere naa, o ni awọn ere kan ti ki i ṣe ti ibilẹ tabi abule ni awọn fi bẹrẹ, ṣugbọn ere naa ki i ṣe daadaa lawọn oju opo yii, awọn eeyan ki i wo.
Eyi lo fa a ti wọn fi yi ilana ere pada, ti wọn si bẹrẹ si i ṣere abule.
''Nigba ti a bẹrẹ ere abule, a ri i pe awọn eeyan wo o daadaa, ọpọlọpọ awọn ọba paapaa lo ba wa sọrọ pe ka maa tẹsiwaju, awa naa si tun ni i lọkan lati fi iṣẹ wa gbe aṣa Yoruba larugẹ, ati ki awọn eeyan le maa ri ohun ti yoo pa wọn lẹrin-in.
Àwọn òṣèré ńlá kì í dá wa lóhùn nìgbá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ti ń tẹ̀lé wa báyìí

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Oluwatobilola sọ pe awọn agba oṣere ti wọn ti wa lagbo tiata ti a mọ si Nollywood ki i kọkọ da awọn lohun nigba tawọn ṣẹṣẹ bẹrẹ agbekalẹ awọn yii.
O ni bawọn ba fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si wọn, wọn le ma ri i debi ti wọn yoo tilẹ dahun. Ṣugbọn pẹlu iyanju ati ai ko aarẹ ọkan, pupọ ninu wọn ti n tẹle Trending Kidz bayii.
O fi kun un pe awọn ti lọo ṣere ni awon ilu nla bii Eko ati Ogun, awon si ti lọ si awon eto nla nla tawọn ko tiẹ lero pe awon le de lọdun marun-un si asiko yii.
Nipa idojukọ ti wọn n ri, Tobiloba sọ pe nitori pe ọmọde ni wọn, awọn obi awon kan ninu wọn ko fẹẹ gba ki ọmọ wọn ṣe iṣẹ naa, ṣugbọn nigba ti wọn ri i pe okiki awọn ti n kan, inu wọn bẹrẹ si i dun si i.
Ni afikun, Omodara Toyin toun naa jẹ ọkan lara awọn Trending Kidz, sọ pe awọn eeyan nla to n ṣe iṣẹ tawọn n ṣe yii lo maa n jẹ iwuri foun to fi wu oun pẹlu lati darapọ.
Taiwo Sunday, oṣere miran lara wọn, ṣalaye pe oun ko le kopa bayii tẹlẹ, igba toun darapọ mọ awọn ẹgbẹ oun yii lo di pe oun le ṣe e, ti inu oun si maa n dun toun ba n wo ara oun.
Afojusun awọn ewe naa bi wọn ṣe wi ni lati de ibi giga, amọran wọn fun awọn to n ṣe iru iṣẹ wọn yii si ni lati ma ṣe ko aarẹ ọkan bi wọn tilẹ doju kọ ohunkohun.





