Àwọn nnkan tí o le ṣe láti dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ àrùn tó le kó nílé ẹ̀kọ́

Awọn akẹkọọ to wọ aṣọ alawọ aro, wa ninu yaara ikẹkọọ wọn pẹlu olukọ to n kọ wọn

Oríṣun àwòrán, Unicef/facebook

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Asiko ti awọn akẹkọọ n pada sile ẹkọ wọn re e , lẹyin isinmi ọlọjọ gbọọrọ. Bi awọn kan ṣe n bọ si kilaasi tuntun, ni awọn mii ṣẹṣẹ n bẹrẹ irinajo ẹkọ wọn.

Ipada sile ẹkọ le fi kun awọn wahala ati aajo obi lori ọmọ, paapaa nitori bi aarun ati aisan oriṣiriṣi ṣe ma n wọpọ laarin awọn ọmọde. Awọn aisan bi ikọ, ọfinkin, iba, igbẹ gbuuru ati bẹẹbẹẹ lọ ṣaba ma n ṣe awọn ọmọde nitori ifarakanra ti wọn ma n ṣe nile ẹkọ.

Ajọ to n risi itankalẹ aarun nilẹ Amẹrika sọ pe ida mẹfa ọmọde ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun marun un si mẹtadinlogun, lo ma n pa ile-ẹkọ jẹ nitori ailera.

Lootọ ni ọmọ tiẹ le ma ma a pa ile-ẹkọ jẹ debii pe o fa ipalara fun eto ẹkọ wọn, ṣugbọn wiwa ni ilera to peye, ṣe koko pupọ. Oriṣiriṣi igbesẹ si ni obi le gbe lati mu ki agọ ara awọn ọmọ wọn w ani pipe, ati lati ro wọn ni agbara tako awọn aisan bii otutu, ikọ, ọfinkin ati igbẹ gbuuru to ma n rapala wọ yaara ikẹkọọ.

Ounjẹ aṣaraloore

Awọn ounjẹ to ni oriṣiriṣi awọ - to ni eso ati ewebẹ ninu – le fun awọn ọmọde ni pupọ ninu eroja bii vitamins, minerals, ati awọn mii, to le ro awọn ṣọja ara wọn l'agbara. Awọn onimọ ilera sọ pe apapọ eso o dara ki eso ati ewebẹ jẹ ilaji ounjẹ ti ọmọde n jẹ lojumọ.

Yiyọ ijẹkujẹ kuro ninu ounjẹ wọn naa le ṣe iranlọwọ. Awọn ipanu ati ounjẹ igbalode mii ma n mu ki iyọ, ṣuga ati ọra, pọ ju ni agọ ara ọmọ. Dipo awọn ounjẹ kiakia yii, o san ki o se ounjẹ ti ọmọ rẹ n jẹ .

Oriṣiriṣi ewebẹ bii carrot, alabusọsa, alubọsa elewe, anamọ, ata ati ataalẹ ti wọn ko jọ si oju kan

Oríṣun àwòrán, VW Pics

Awọn ounjẹ to le ro 'sọja ara' Immune System' l'agbara

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ apoogun Vitabiotics sọ pe jijẹ awọn ounjẹ ati eso bii ọsan ati ata, jẹ orisun eroja Vitamin C. Bakan naa ni awọn ewebẹ alawọ eweko naa jẹ ọna to dara lati ri folic acid, ẹdọ ẹran fun Vitamin A, folci acid ati Vitamin B12. "Awọn ẹja ọlọraa, ẹfọ oku ati inu ẹyin naa ma n fun ara ni Vitamin D.

Yatọ si awọn eroja aṣaraloore ti wọn le ri lara ounjẹ, oriṣirṣi oogun ti wọn n pe ni supplements lo le lo fun awọn ọmọde lati fun ara wọn ni agbara to le dena aarun. Amọ, rii daju pe o ba awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera sọrọ ki o to bẹrẹ si lo oogun kankan fun ọmọ rẹ.

Imọtoto Ara

Imọtoto ara jẹ ọna kan to gboogi to rọrun lati dena aarun laarin awọn ọmọde, paapaa lati dena ajakalẹ aarun. Nitori naa lo ṣe ṣe koko gẹgẹ bi obi, lati kọ ọmọ rẹ nipa pataki fifọ ọwọ loore-koore, pẹlu omi to mọ ati ọṣẹ. Bakan naa lo ṣe pataki lati ran wọn leti pe o lewu lati maa ki ọwọ wọn bọ ẹnu, oju, imu, ki wọn o le dena Kokoro aifojuri to le fa aarun.

Vitamin D lati ara oorun

Oriṣiriṣi anfaani lo wa ninu gbigba oorun sara, eyi to si le ran agọ ara ọmọ rẹ lọwọ lati gbogun ti aarun. Yatọ si pe oorun ma n fi kun ilera Egungun ati eyin, o tun ma n ro awọn eroja to n dena aarun l'agbara ninu ara.

Yatọ si awọn nnkan ti a mẹnuba yii, o tun ṣe koko fun obi kọọkan lati mu aabo awọn ọmọ to wa ni ile ẹkọ ati yaara ikẹkọọ pẹlu ọmọ wọn, ni ọkunkundun.

Ti ọmọ rẹ ba n ṣe aisan bii ikọ, ọfinkin, igbẹ gbuuru ati awọn aisan miran to le ran ẹlomii, o dara ki o jẹ ki ọmọ naa joko sile titi ara rẹ yoo fi ya.