Wo kókó ẹ̀kọ́ 26 tí ìjọba buwọ́lù fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 'Technical College'

Awọn akẹkọọ ninu kilaasi lkan niluu Eko ti wọn lo iboju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lara awọn koko ẹkọ mii ti wọn tun fi kun ni ẹkọ nipa ifẹ si orilẹede, to fi mọ ẹkọ imọ sayẹnsi ati ẹkọ ede abinibi Naijiria
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti kede apapọ iṣẹ ọwọ mẹrindinlọgbọn ti awọn eeyan le maa kọ lawọn ile ẹkọ ẹkọṣẹ ni Naiijiria.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ, Bon Folasade, fi lede, o ni atunṣe ti wọn ṣẹṣẹ ṣe si ẹka eto ẹkọ naa kan an nipa fun awọn akẹkọọ lati kọ nipa o kere tan, imọ ẹkọ mẹfa, ati imọ ẹkọ mẹwaa o pọ ju.

Awọn akẹkọọ gbọdọ kọ nipa imọ mẹsan an si mẹwaa – ti ọkan ninu rẹ gbọdọ ẹkọ to ṣe koko, marun un si mẹfa yoo jẹ eyii ti gbogbo wọn yoo ṣe lapapọ, meji si mẹta yoo sunmọ ẹkọ nipa iṣẹ ọwọ ti wọn n kọ nigba ti ẹyọkan yoo jẹ ayalo ẹkọ.

Ileeṣe ọhun sọ siwaju si pe atunto yii lo waye latari ipele ti eto ẹkọ de lawujọ agbaye.

Wọn fi kun pe o wa ni ibamu pẹlu bi awọn eeyan ṣe nilo awọn iṣẹ ọwọ naa si lagbaye; bii iṣẹ ile kikọ, imọ ẹrọ, iṣẹ agbẹ, mọto titunṣe, imọ ẹrọ ayelujara, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Atẹjade naa sọ pe "O wa lati pese awọn ọmọ Naijiria silẹ fun ọja ọla wọn lati le figagbaga pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lagbaye lọjọ iwaju."

Lara awọn koko ẹkọ mii ti wọn tun fi kun ni ẹkọ nipa ifẹ si orilẹede, to fi mọ ẹkọ imọ sayẹnsi ati ẹkọ ede abinibi Naijiria.

Ìwọ̀nyí ni awọn koko ẹkọ mẹrindinlọgbọn ti ijọba apapọ buwọlu

  • Brick laying, block laying and concreting
  • Woodwork, carpentry and joinery
  • Plumbing and pipe fitting
  • Computer hardware & GSM repair and maintenance
  • Refrigeration & air-conditioning works
  • Mechanised agriculture (mechanisation / smart agriculture)
  • Autobody works
  • Catering craft practice
  • Solar PV installation and maintenance
  • Fashion design and garment making
  • Livestock farming/animal husbandry
  • Fish farming (aquaculture)
  • Motorcycle & tricycle repairs
  • Painting, decoration and finishes (interior design)
  • Welding & fabrication
  • Auto-electrical wiring
  • Automobile mechanics
  • Beauty therapy & cosmetology
  • Creative media (digital media production/operations)
  • Electronic systems maintenance craft
  • Furniture making & upholstery
  • Networking & system security (including satellite TV antenna installation and maintenance)
  • Social media content creation and management
  • Tiling & cladding (tiling and decorative stonework / floor-cover installation)
  • Automobile CNG conversion and maintenance
  • Leather works