Ilé ẹjọ́ gba ẹ̀bẹ̀ igun adarí ADC tẹ́lẹ̀, ó ní David Mark àti Aregbesola kò gbọdọ̀ pe ara wọn ní adarí ẹgbẹ́ mọ́, wọ́gilé òǹtẹ̀ INEC lórí wọn

Aworan aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ; David Mark ati Ọgbẹni Rauf Aregbesola; gomina ipinle Osun tele. David Mark de fila dudu to ni ila pupa tẹẹrẹ, o logo si oju rẹ, o si n rẹrin-in muse. Ọgbẹni Aregbesola wọ agbada, o de fila, o mu ẹrọ gbohun-gbohun dani, o si n rẹrin-in. Awọn eeyan wa nitosi rẹ ninu aworan naa

Oríṣun àwòrán, David Mark/ Rauf Aregbesola/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Seneto David Mark ati Ogbeni Rauf Aregbesola
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Lẹyin ti iroyin gbode kan pe ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti buwọ lu iyansipo David Mark, olori ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, ati Rauf Aregbesola, gomina ipinlẹ Osun nigba kan, gẹgẹ bii Alaga ati Akọwe fun ẹgbẹ oṣẹlu African Democratic Congress (ADC), ọrọ ti pada ba ẹyin yọ.

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ ti paṣẹ pe iyansipo ti INEC buwọ lu naa ko fẹsẹ mulẹ.

Kootu paṣẹ pe David Mark, Rauf Aregbesola, Oserheimen Osunbor ati awọn miran ti wọn n pe ara wọn ni oloye ẹgbẹ oṣelu ADC ko gbọdọ sọ bẹẹ mọ.

Aṣẹ kootu giga naa si ti bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ lai pẹ rara.

Iwe idajọ meji to kede pe ki David Mark ati Rauf Aregbesola mase pe ara wọn ni adari ẹgbẹ ADC mọ

Oríṣun àwòrán, ADC

Àkọlé àwòrán, Iwe idajọ

"Idajọ naa ṣafihan ẹtọ awa olori ninu ẹgbẹ ADC, a gba fun idajọ naa, ti yoo mu ogo otitọ ẹgbẹ ADC jade"

Igun adari ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress naa, ko to di pe awọn David Mark gba ẹgbẹ lọwọ wọn, fi idi isẹlẹ naa mulẹ.

Igun naa ṣalaye ninu atẹjade kan, pe idajọ naa n ṣafihan ẹtọ awọn olori ni.

Wọn ni awọn gba fun idajọ naa ti yoo mu ogo otitọ ẹgbẹ ADC jade.

Adari eto iroyin ninu igun ADC naa, Ọmọwe Christopher Okechukwu, rọ awọn olori oṣelu ni Naijiria lati darapọ mọ ADC.

O ni laipẹ yii ni iforukọsilẹ yoo di nnkan irọrun kaakiri Naijria.

O wa rọ awọn to parapọ di ADC lati gbaruku ti Ọnarebu Nafiu Bala, gẹgẹ bii Alaga apapọ ẹgbẹ.

O fi kun un pe agbajọ ọwọ nikan ni awọn le fi sọya, lati gbe orilẹede yii de ibi ọjọ iwaju rere.

Kí ni àkọsílẹ̀ David Mark àti Aregbesola tí INEC fòǹtẹ̀ lu bíi Alága àti Akọ̀wé ẹgbẹ́ ADC

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), ti buwọ lu iyansipo David Mark, olori ile igbimọ aṣofin Naijiria tẹlẹ, ati Rauf Aregbesola, gomina ipinlẹ Osun nigba kan, gẹgẹ bii Alaga ati Akọwe fun ẹgbẹ oṣẹlu African Democratic Congress (ADC).

Ninu atẹjade kan ti INEC fi si oju opo ayelujara rẹ l'Ọjọru lo ti kede ibuwọlu iyansipo naa.

INEC fi kun un pe Mani Ibrahim ni Akapo ẹgbẹ lapapọ, Akibu Dalhatu ni akọwe owo apapọ ẹgbẹ, Oserheimen Osunbor, gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Edo si ni amofin ti yoo maa gba ADC nimọran.

Akojọpọ awọn oloṣelu to di ADC yii lo n gbaradi lati koju Aarẹ Bola Tinubu ninu idibo ọdun 2027.

Ṣaaju ni ẹgbẹ naa ti kọkọ fi ẹsun kan INEC pe wọn ko tete gba orukọ All Democratic Alliance (ADA) tawọn fẹ wọle.

Lẹyin igba naa ni wọn yan David Mark bii olori Fidihẹ-ẹ, wọn si fi Aregbesola to jẹ imulẹ Tinubu tẹlẹ ṣe Akọwe Fidihẹ-ẹ.

Ta a ni David Mark, olori ADC tuntun?

David Alechenu Bonaventure Mark ni wọn ni bi lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ọdun 1948, ni Otukpo, ipinlẹ Benue.

Ologun ni David Mark ko too fẹyinti, oloṣelu si ni pẹlu. Oun lo di ipo olori ile igbimọ aṣofin Naijiria mu lati ọdun 2007 titi di 2015.

David Mark ni sẹnetọ fun ẹkun-un Guusu Benue ni 1999 titi di 2019.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Mark fun igba pipẹ ko too kuro ninu ẹgbẹ naa ni 2025 yii, to si darapọ mọ ADC.

Ko too di sẹnetọ, David Mark ni gomina ipinlẹ Niger laaarin 1984 si 1986, Alaga tuntun ADC yii si ti figba kan ṣe minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ri, oun si ni olori ile igbimọ aṣofin to pẹ ju nipo naa ni Naijiria.

Rauf Aregbesola

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Odu ni Ọgbẹni Rauf Adesoji Aregbesola ninu ọrọ oṣelu lorilẹede Naijiria, bẹrẹ lati ipinlẹ Eko, titi de ilu abinibi rẹ ti i ṣe ipinlẹ Osun.

Ilu Ilesa, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi Rauf Aregbesola, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 1957 ni wọn bi i.

Lati ileewe giga ni Aregbesola ti bẹrẹ oṣelu tirẹ, nigba to jẹ abẹnugan fun awọn akẹkọọ ni Polytechnic, Ibadan.

Oṣu Kẹfa ọdun 1990 ni wọn yan an bii aṣoju ninu ẹgbẹ oṣelu SDP.

Eekan ni Aregbesola ninu ẹgbẹ AD (Alliance for Democracy) ti Senato Bola Tinubu n lewaju rẹ ni 1999, nigba naa ni Aregbe jẹ adari ipolongo ẹgbẹ ibo fun Tinubu (BATCO),Tinunu si pada di gomina Eko lọdun naa.

Lẹyin ti Tinubu di gomina Eko lo yan Aregbe si ipo kọmiṣanna iṣẹ ode. Laaarin 2010 si 2018 ni Aregbesola fi wa nipo gomina ipinle Osun. o si pada tun ṣe minisita ọrọ abẹle lati 2019 de 2023.

Imulẹ Aarẹ Tinubu ni Aregbesola tẹlẹ ko too ma ri bẹẹ mọ, ti Aregbe kọyin si APC ati iṣẹ ọwọ rẹ, to si darapọ mọ ADC to sọ ọ di Akọwe apapọ ẹgbẹ bayii.

Oserheimen Aigberaodion Osunbor

Aworan Amofin Oserheimen Aigberaodion Osunbor. O ge irun rẹ lọ silẹ, o logo, o si wọ aṣọ oyinbo to di mọ ọrun.

Oríṣun àwòrán, Daily Trust

Àkọlé àwòrán, Amofin Oserheimen Aigberaodion Osunbor

Amofin ni ọkunrin to gba ipo oludamọran nipa ofin fun ẹgbẹ ADC yii, oloṣelu si ni pẹlu.

Ọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa ódun 1951 ni wọn bi I ni ipinlẹ Edo.

Oserheimen Aigberaodion Osunbor lo ṣe gomina ipinlẹ Edo lati ọdun 2007 di 2008.

O ṣiṣẹ bii sẹnetọ to n ṣoju Aarin gbungbun ipinlẹ Edo lati 1999 titi di 2007.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Osunbor tẹlẹ ri, ko too kuro nibẹ wọ ADC bayii.

Ọjọ keji oṣu Keje ọdun 2025 yii wọn di ẹru ẹgbẹ ADC, nigba ti wọn kede David Mark bii Alaga Fidihẹ-ẹ, ti wọn si kede Arẹgbẹ bii akọwe Fidihẹ ẹ.

Lara awọn oloṣelu to parapọ di ADC yii ni Atiku Abubakar, Peter Obi, Nasir El-Rufai, Rotimi Amaechi, awọn gomina tẹlẹ ri, Abubakar Malami ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹ má dá wa lẹ́jọ́ nítorí ìkùnà tó ṣẹlẹ̀ sí ẹgbẹ́ wa lásìkò àtúndì ìbò - Agbẹnusọ ADC

Lẹyin atundi ibo to waye loṣu Kẹjọ to kọja, eyi ti ẹgbẹ ADC ko ti ri ipo kankan mu, Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Bolaji Abdullahi, ti ni ki ẹnikẹni ma ṣe tori iyẹn bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ awọn.

Abdullahi sọ eyi l'Ọjọru lori eto kan lori tẹlifiṣan Channels.

O ni aṣẹṣẹyọ ọjọ ni ADC, ẹgbẹ to ṣẹṣẹ de ti ko ti i pẹ rara ni, ko si yẹ ki ẹnikẹni bu ẹnu atẹ lu u .

Agbẹnusọ ADC fi kun un pe ẹgbẹ to ṣẹṣẹ de ti ko si ti I fi gbogbo ara ṣetan fun ibo didi nigba naa ni ADC, o ni eyi lo fa a ti wọn ko fi rọwọ mu ninu atundi ibo.

"A ti ṣalaye nipa ẹ, a ti fi atẹjade sita. Ibo yẹn wa ye lai ti i pe oṣu kan ti a da ẹgbẹ wa silẹ. A o tiẹ mọ pupọ ninu awọn oludije, idi niyẹn ti a fi sọ pe ẹ ko le da ADC lẹjọ pẹlu esi ibo naa."

Agbẹnusọ ADC lo sọ bẹẹ.

Ṣaaju ni ADC ti sọ pe magomago pọ ninu idibo naa ni awọn ko ṣe ri ọwọ yọ.

Ẹ o ranti pe atundi ibo naa lo waye lati di alafo awọn eeyan to fipo silẹ ati awọn to di oloogbe ni awọn ile igbimọ aṣoju.

Ninu atundi ibo naa ni INEC ti kede pe APC bori ni ipinlẹ mejila, APGA, bori ni ipinlẹ meji, PDP bori nipinlẹ kan, ti i ṣe Oyo, nigba ti NNPP naa bori ni ipinlẹ kan ti i ṣe Kano.