GWR kéde Hilda Baci bí ẹni tó se ìkòkò ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù tó tóbi jùlọ

Àjọ Guinness World Records, GWR ti kéde Hilda Baci bí ẹni tó se ìkòkò Ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù tí ilẹ̀ Nàìjíríà tó pọ̀ jùlọ ní àgbáyé.
GWR nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi soju òpó X wọn ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹsàn-án sọ pé Hilda tún ti gba àmì ẹ̀yẹ míì pelu bó ṣe se Ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù tí Nàìjíríà tí ìwọ̀n rẹ̀ tó kílógíráàmù 8,780.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà péjú pésè sí ìpínlẹ̀ Eko láti wo bí gbajúmọ̀ alásè náà ṣe ń se ìkòkò ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù tó tóbi jùlọ ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án.
Ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù jẹ́ oúnjẹ tó gbajúmọ̀ ní Nàìjíríà, Ghana, Senegal, Sierra Leone, Liberia àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìdí rèé tí mo fi se ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù nínú ìkòkò tó tóbi jùlọ ní àgbáyé - Hilda Baci

Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló péjú pèsè sí ilé ìtura Eko Hotel and Suites tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 láti wo bí gbajúmọ̀ alásè nnì Hilda Baci ṣe ń se ìkòkò ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù tó tóbi jùlọ ní àgbáyé.
Ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù jẹ́ oúnjẹ tó gbajúmọ̀ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Afrika.
Ní ọdún 2023 ni Hilda Baci di ìlúmọ̀ọ́ká nígbà tó ṣe ìpèníjà gẹ́gẹ́ bí alásè tó dáná fún ìgbà tó pẹ́ jùlọ, tí àjọ Guinness World Record sì fun ní àmì ẹ̀yẹ pé ó se oúnjẹ fún wákàtí mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún àti ìṣẹ́jú mọ́kànlá.
Hilda Baci sọ fún BBC News Pidgin pé ìdí tí òun fi ṣe ìpèníjà náà nip é Nàìjíríà kìí gbẹ́yìn níbi ohunkóhun.
"Àwa làgbà nílẹ̀ Africa tí ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù sì jẹ́ ohun tí wọ́n mọ Africa mọ́. Mo wá rò ó pé ó máa dára láti se ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù tó tóbi jùlọ àti pé ó máa jẹ́ ohun ìwúrí fún orílẹ̀ èdè wa."

Àwọn ohun èlò tí wọ́n fi se ìrẹsì jọ̀lọ́ọ̀fù náà

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí èèyàn yóò dìde láti se ìkòkò ìrẹsì tó tóbi jùlọ ní àgbáyé.
Bí wọ́n ṣe ń fọn rere #HildaBaci àti #GuinessWorldRecord lórí ayélujára bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn èyí tí púpọ̀ wọn jẹ́ ọ̀dọ́ àtàwọn tó fẹ́ràn oúnjẹ ṣe péjú pésè síbi tí àsè náà ti wáyé láti ṣe àtìlẹyìn fún Hilda Baci.
Hilda Baci sọ fún BBC pé ó tó ọdún kan tí òun fi ṣe ìpalẹ̀mọ́ láti mú kí àsè náà wá sí ìmúṣẹ.
Ó ní oṣù méjì gbáko ló gba òun láti ṣe ìkòkò tí wọ́n fi se oúnjẹ náà àti pé nílẹ̀ yìí ni àwọn ti ṣe kòkò náà.
Ó ṣàlàyé pé ìkòkò tí wọ́n fi se ìrẹsì ọ̀hún jẹ́ lítà 22,619 àti pé èèyàn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún ni àwọn jọ pawọ́pọ̀ láti ṣe àsè náà.
Ó ní àwọn ohun èlò tí wọ́n lò láti fi se oúnjẹ náà jẹ́:
- Báàgì ìrẹsì igba (200)
- Páálí tòmátò alágolo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500)
- Ọ̀pọ̀lọpọ̀ adùn ọbẹ̀
- Àlùbọ́sà ẹgbẹ̀tà kílógíráàmù (600kg)
- Omi ẹgbẹ̀rún mẹ́fà kílógíráàmù (6000kg)
- Ẹran ewúrẹ́
- Òróró ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin kílógíráàmù (700kg)
Àmọ́ níṣe ni ọ̀rọ̀ náà bẹ́yìn yọ nígbà tí ìkòkò ìrẹsì náà tẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ fi ọkọ̀ ńlá gbé e láti fi wọ̀n ọ́n.
Àwọn alásè náà sáré ṣẹ́ ọwọ́ sí awakọ̀ ọ̀hún láti má gbe mọ́ tí wọ́n sì pín oúnjẹ náà sínú abọ́ fún àwọn èrò tó wà níbẹ̀.
Ní ọdún 2023 ni àjọ Guinness World Record ti kọ́kọ́ dádé ẹni tó se oúnjẹ fún ìgbà tó pẹ́ jùlọ fún Hilda Baci.
Ó di ìlúmọ̀ọ́ká nígbà náà fún bí ó ṣe dáná fún ọjọ́ mẹ́rin láì sinmi, tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fi mọ́ àwọn olóṣèlú àtàwọn èèkàn ìlú tí wọ́n ń kan sáárá sí i.
Àjọ Guinness World Record nígbà náà sọ pé òkìkí Hilda Baci kàn débi pé ọjọ́ méjì ni ojú òpó àwọn kò fi ṣiṣẹ́ bí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣe ń kàn sí ojú òpó náà.
Ó gba ipò ẹni tó se oúnjẹ fún ìgbà pípẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ilẹ̀ India kan, Lata Tondon tó ti wà nípò náà láti ọdún 2019 pẹ̀lú nǹkan tó lé ní wákàtí márùn-ún.
Ta ni Hilda Baci?

Ní ogúnjọ́, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 1995 ni wọ́n bí Hilda Effiong Bassey tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Hilda Baci.
Ọmọ bíbí ìjọba ìbílẹ̀ Nsit Ubium ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ni.
Lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ Madonna University, Anambra nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Sociology ló bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ sísè tà.
Ó ní òun ní ìmísí oúnjẹ sísè láti ọ̀dọ̀ ìyá òun, Lynda Ndukwe tí òun náà jẹ́ alásè.
Yàtọ̀sí oúnjẹ sísè, Hilda Baci tún jẹ́ òṣèré tíátà tó sì ti kópa nínú àwọn sinimá bíi Dreamchaser, A Walk on Water àti Mr &Mrs Robert.















