Alásè ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland gba adé Guinness World Records mọ́ Hilda Baci lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, GWR/Hilda Baci
Ọkunrin alase ọmọ orilẹ-ede Ireland kan, Alan Fisher, ti gba ade ẹni to se ounjẹ fun pipẹ julọ lagbaye.
Ajọ to maa n fun eeyan ni ami ẹyẹ ṣiṣe nnkan ti ẹnikan ko ṣe ri lagbaye, Guinness World Records, GWR lo kede bẹẹ lẹyin ti ọkunrin ọhun ṣe aṣeyọri naa.
Eyii to tumọ si pe Fisher ti gba ade naa lọwọ gbajugbaja alasẹ ọmọ Naijiria, Hilda Baci.
GWR kede pe ade meji ọtọtọ ni alase ọmọ ilẹ Ireland naa gba lọjọ kan ṣoṣo ninu ile ounjẹ rẹ.
Akọkọ ni pe o se ounjẹ fun wakati mọkandinlọgọfa ati iṣẹju mẹtadinlọgọta (119 hours 57 minutes), ninu eyii to ti fi odidi wakati mẹrinlelogun ju ti Hilda Baci lọ.
Ade keji ti Fisher gba ni yiyan nnkan “longest baking marathon” fun igba pipẹ julọ fun wakati mẹtadinlaadọta ati iṣẹju mọkanlelogun.
Gẹgẹ bii ohun ti GWR sọ, ni fẹgbẹkẹgbẹ ni Fisher ṣe aṣeyori mejeji.
Inu oṣu Kẹta ọdun yii ni Fisher gbọ nipa eto ounjẹ sise fun igba pipẹ naa to si pinnu lati dan an wo.
Ṣo lootọ ni pe eeyan gbọdọ duro ọdun kan gbako ko to gbiyanju lati gba ade GWR lọwọ ẹlomiran?
Lẹyin ikede GWR yii ni inu awọn ololufe Hilda Baci kan bajẹ latari pe ẹlomiran ti gba ade GWR lọwọ rẹ.
Eyii lo mu ki ẹnikan bere lọwọ ajọ naa loju opo X eredi ti wọn ṣe fun ẹlomiran ni ade naa lai duro ọdun kan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Amọ GWR fesi pe ko si ohun to jọ bẹẹ, ati pe ofin naa kii ṣe eyii ti awọn gbe kalẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, alase ọmọ ipinlẹ Ekiti kan, Chef Dammy ti gbiyanju lati gba ade naa lọwọ Bacci, amọ ọpọ ọmọ Naijiria sọrọ kobakungbe si alase naa.
Ọjọ karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2023 yii ni Hilda Baci gba ade naa ki Alan Fisher to gba a lọwọ rẹ bayii lẹyin oṣu mẹfa.












