Ẹgbẹ́ Mọdirasatu Mohammed Ilọrin tún pe Tani-Ọlọhun lẹ́jọ́ fún dídáná sun Kurani nígbá kan

Oríṣun àwòrán, Others
Báyìí ẹgbẹ awọn Alfa kan ti wọn n pe ni Mọdirasatu Mohammed, ṣe tun ti wọ AbdulAzeez Adegbọla, ti ọpọ mo si Tani Ọlọhun, lọ si ile ẹjọ ni ilu Ilorin ni ipinle Kwara ni Aarin gbungbun Naijiria.
Iwaju Magistrate Muhammed Adam ni ile ẹjọ Majisireeti ti o kalẹ si iluu Ilọrin ni wọn gbe ẹjọ naa ká,
Ẹsun didana sun iwe mimọ awọn musulumi iyẹn Kurani si ni wọn fi kan-an
Ko to di oni, Tani Ọlọhun, lo ti n jẹjọ lọna mẹta ọtọọtọ niluu Ilọrin, Upper Area eyi ti Alfa Okutagidi wọ ọ lọ, Majisireeti ti awọn ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ogo Ilọrin wọ ọ lọ ati eyi ti Sheikh Labeeb Lagbaji pe.
Alfa Ọjọgbọn Abubakar Ali Agan, jẹ olori fun ẹgbẹ Modirasatu Mohammed ni Ilorin.
Ẹsun ibanilorukọjẹ ni awọn mẹtẹẹta yi fi kan an, Ile ẹjọ si ti gba beeli meji ninu mẹtẹẹta ọhun.
Ẹsun wo ni ẹgbẹ́ Modirasatu Mohammed fi kan Tani Olohun?
Ẹsun ti ẹgbẹ awon Alfa Mọdirasatu Mohammed yii fi kan an nikan lo yatọ, tii se ẹsun didana sun Kurani,
Ẹjọ ti wa di mẹrin ọtọọtọ lọrun Tani-Ọlọhun bayii.
Kini o ṣẹlẹ nibi igbẹjọ ni Ana?
Nibi igbẹjọ toni, agbẹjọro ẹgbẹ Mọdirasatu Mohammed, iyẹn Usman Saad Imam, sọ fun ile ẹjọ pe awọn onibara oun fẹsun kan olujẹjọ pe, o dana sun iwe mimọ awọn musulumi iyẹn Qurani leyi ti ko ba ofin mu.
O tẹsiwaju pe ki Adajọ beere lọwọ lọọya Ta-ni-Ọlọrun idi ti ko fi gba iwe ipẹjọ lọwọ ọlọpaa to mu iwe ọhun lọ fun un lọgba ẹwọn to wa.
Tani Ọlọhun ko yọju si ile-ẹjọ rara ṣugbọn agbẹjọro rẹ Ademọla Banks, duro fun un.
Kini agbejọro Tani Olohun sọ?
Ademọla Banks, sọ fun ile ẹjọ pe onibaara oun ko tẹwọ gba iwe ipẹjọ, idi niyi ti ko fi yọju si ile-ẹjọ ki adajọ fun oun ni asiko diẹ lati ṣe ohun totọ ti iwe ipẹjọ naa yoo fi tẹẹ lọwọ.
O fi kun un pe ẹjọ ti pọju lọrun onibaara oun bọya eyi ni idi ti ko fi le ribi ronu daadaa lati gba iwe naa lọwọ wọn.
Lẹyin to ti gbọ ọrọ lẹnu awọn mejeji, Majisireeti Muhammed Adam, sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla oṣu kọkanla ọdun yii, to jẹ ọjọ ti yoo jẹjọ lori ẹjọ ti Sheikh Labeeb Lagbaaji pe e.












