Ìdí tàwọn obìnrin kìí fi jáde lọ́jọ́ kan ní Ondo rèé

Aworan abawọle Ilu Ondo

Bayii ni a n ṣe ni ile wa, eewọ ibo miiran ni. Ọdun Moko jẹ ọdun kan to ma n waye lẹẹkan lọdun, to si ni awọn eewọ kan tabi meji paapa fun awọn obinrin niluu Ondo.

Lasiko ọdun Moko ni ilu Ondo, obìnrin kankan ko gbọdọ jade sita lowurọ kutu titi di irọlẹ

Oni ọjọ keje oṣu kọkanla, ọdun yii ti bẹrẹ niluu Udoko, ọkan lara awon ilu kereje to wa labẹ ilu Ondo.

Ọpọ awon ọja to wa ni Ilu Ondo ati agbegbe rẹ lo ma'n wa ni titipa, ti ko ni si kara kata, paapa eyi to jẹ ti awọn obinrin.

Ni awọn ọja to ba wa ni ṣiṣi, awọn ọkunrin nìkan lo ni anfani lati bo sí tà wa ṣe tita ati rira ọja.

Ọdun ko yọ awọn alakọwe obinrin ti wọn sise ni ile ẹkọ, banki tabi ileeṣẹ ijọba silẹ rara

Ki gan ni ọdun Moko wa fun?

Aworan Ọga niluu Ondo

Ohun gboogi ti ọdun yii wa fun ni lati mu irẹpọ wa laarin gbogbo ilu kereje to wa ati lati fọ awọn ilu naa mọ niluu Ondo.

Igbagbọ awọn araalu ni pe sise ọdun yii yoo jẹ ki wọn ṣe aṣeyọri ninu gbogbo ohun ti wọn ba dawọle, yaala ninu oko tabi nibi ọja tita

Baba olorisa ti Udoko to tun jẹ oloye agba fun ọdunwo, Olaifa ifatuyi Adeniran, so pe orukọ mẹta ni awọn n pe ọdun yii; "Ọdun Ọrọ, Ọdún Moko tabi Ọdún Jonfa.

"Bo ṣe je wipe ọrọ ni won fi de ile Aye, ni ọjọ Ọdun Moko, gbogbo nnkan ti eyan ba so lo ma wa sì imuse"

Baba olorisa na so pe Ọdun Moko lo ma n le iku lo, aarun ati aisan kuro niluu Ondo.

"Nigba iwasẹ, awon to tẹ ilu duro lo bẹrẹ ọdun yii lati mu ilu tuba, tu sẹ

"Lasiko naa ẹyẹ ko ke bi ẹyẹ, won wa n wa ọna ti ilu ma fi tu ba tu ṣẹ. Ifa wa gbawọn ni imọran pe kì won gbe awon igbesẹ kan to si jẹ lẹyìn naa ire yoo bẹrẹ si ni wọ ilu."

Oloye giga Olaifa Adeniran sọ pe nitori pe Yoruba gbagbọ pe ẹnu awọn obinrin ko ki n bọ nipa ti asiri ni awọn baba nla wọn fi kede konigbe fun awọn obinrin ilu naa lasiko ọdun.

"Nígba ti awon baba wa n gbe awọn igbesẹ ti ifa sọ yii, won ko jẹ ki awọn obinrin gbọ tàbí mo ni pa' rẹ. Ifa lo fun won ni imọran lati le mu ilu tu ba tu sẹ."

Nnkan buruku to ma sẹlẹ si obinrin to ba kọ eti ikun

Aworan awọn onisẹẹse

Ọdun yii ni wọn jẹ ko di mimọ pe ko wa lati fi ta abuku si obinrin tabi lati ma ka wọn sugbọn wọn ni lati tẹle asa ati ise ilu naa.

BBC Yoruba rin kaakiri ilu to si jẹ pe ọja ni ilu na da paro. Awon olutaja ọkùnrin perete lowa ni ọja.

Pupọ awọn ọmọde lọkunrin lo wa loju popo, ti wọn gba bọọlu, ti ko si apẹẹrẹ pe obinrin wa lakiya.

Baba olorisa tun jẹ ko di mimọ pe Obinrin to ba wo oro na, nnkan buruku lo ma ṣe lẹ sì.

Gbogbo Obinrin niluu yii yala ọmọde tabi agbalagba ni wọn ko ni anfani lati foju wo oro yii.

"Ati omo ile ati awọn olutaja obinrin ni wọn ko ni anfani lati jade rara.

"Awọn ọkunrin nìkan lo ni anfani lọ si ibi to ba wu wọn niluu ondo loni.

"To si jẹ pe w ni yoo lọ ba awọn ìya won tabi iyawo wọn duro si ile itaja."