Àwọn ajínigbé jí kọ́pà gbé lásìkò tó ń rin ìrìnàjò lọ sí ibùdó NYSC nílùú Abuja

Aworan Omoniyi Oluwaferanmi

Oríṣun àwòrán, X/tobilobadearest

Akẹkọọ to n rin irinajo lọ ibu agunbanirọ kan lo ti bọ sọwọ awọn ajinigbe lasiko to n rin irinajo lọ si ibudo agunbanirọ NYSC niluu Abuja.

Gẹgẹ bi ọrẹ rẹ Tobilola Kanmi ṣe salaye lasiko to gbe ọrọ naa sori ayelujara, ni oju ọna Kabba nipinlẹ Kogi ni awọn ajinigbe naa ti gbe Omoniyi Oluwaferanmi, ẹni ọdun mẹdọgbọn, to jẹ akẹkọọ fasiti imọ ẹrọ to wa niluu Akure.

Kanmi ni isẹlẹ naa waye lọjọbọ ọsẹ to kọja, ti awọn ajinigbe naa ti wọn si n bere fun ogun milọnu naira, owo itusilẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“Ọrẹ mi ayaworan, @Mr_reguard bọ sọwọ awọn ajinigbe lasiko to n rin irinajo lọ ibudo NYSC niluu Abuja.

Bakan naa ni a tun ri aworan mii lori ayelujara to ni aworan Omoniyi Oluwaferanmi, to si rọ awọn eeyan lati da owo sinu apo owo kan lati fi gba itusilẹ rẹ.

Kanmi lasiko to n ba Ileeṣẹ iroyin Peoples Gazette sọrọ salaye pe awọn ajinigbe n bere lọwọ mọlẹbi ọkunrin naa pẹlu ẹrọ ibanisọrọ rẹ.

“Ọrẹ mi timọtimọ ni Feranmi: awọn ajinigbe yii n fi ẹrọ ibanisọrọ rẹ pe wa lati bere owo.”

Gẹgẹ bi Gazette ṣe gba jade, awọn ajinigbe naa ji gbogbo awọn ero to wa ninu ọkọ akero to n lọ ilu Abuja, ti wọn si bere fun Ọgọrun milọnu naira sugbọn ti wọn yi pada si ogun milọnu nigba to ya.