Àwọn oní "pure water" daṣẹ́ sílẹ̀ nípìnlẹ̀ Oyo, mú àdínkù bá iye omi tó wà nínú báàgì

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ awọn to n ta omi inu ike ati omi inu ọra n'ipinlẹ Ọyọ, 'Association of Table Water Producers (ATWAP)' da iṣẹ silẹ fun ọjọ meje gbako lati ṣe ikede fun araalu wi pe adinku yoo ba odiwọn omi inu ọra, bẹẹ sini iye omi to n bẹ ninu baagi kan yoo di mẹrindinlogun, dipo ogun ti wọn n ta tẹlẹ.
Owọngogo awọn ohun elo ti awọn to n ta omi fi n ṣiṣẹ wọn ati ipenija to rọ mọ iyọkuro owo iranwọ ori epo ni koko nnkan ti ẹgbẹ naa sọ wi pe o ṣe okunfa igbesẹ yii.
Ẹgbẹ awọn to n ta omi inu ike ati ọra ti gbẹro lati fi kun owo omi tẹlẹri, ṣugbọn eyii mu okuta ba ọja wọn nitori awọn araalu ko fẹ ra omi ni iye owo to ga ju ara lọ.
Ninu ikede ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa ṣe lori redio jakejado ipinlẹ Ọyọ, wọn ṣe alaye wi pe dipo ki awọn fi kun owo omi, adinku yoo ba bi ọra omi kan ṣe tobi si, bẹẹ sini onka omi inu ọra to n bẹ ninu baagi kan yoo di mẹrindinlogun, dipo ogun to n bẹ ninu baagi tẹlẹri.
Yatọ si ikede ti wọn ṣe lori redio, a gbọ fọnran ikede ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa fi ranṣẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lori ikanni ikansiraẹni Whatsapp lorukọ alaga ẹgbẹ naa niluu Ibadan, Alhaji Ọladẹjọ, ninu eleyii ti wọn ti fi ọrọ ranṣẹ wi pe igba Naira ni ki wọn maa ta baagi omi inu ọra to jẹ ẹyọ mẹrindinlogun.
Wọn ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ ma mikan lorii bi wọn a ṣe ri ere jẹ nipasẹ agbekalẹ tuntun yii, nitori Diesel ti wọn fi n pese ẹgbẹta baagi 'pure water' tẹlẹri yoo maa pese to ẹẹdẹgbẹrin si ẹgbẹrin baagi nitori adinku ti o ti ba odiwọn omi inu ọra ati iye to n bẹ ninu baagi.
Awọn aṣoju ẹgbẹ naa tẹsiwaju pe laarin oṣu kọkanla ọdun yii si oṣu kinni ọdun to n bọ ni awọn yoo fi wo oye bi nnkan ṣe ri ni ọja ati bi awọn epo ti wọn n lo ṣe wọn si, eyii ni yoo sọ boya omi inu ọra yoo tun gbowolori sii.
Lonii ọjọ Aje ni wọn pada si ẹnu iṣẹ wọn, lẹyin idaṣẹsilẹ ọlọjọ meje.
Lati igba ti ijọba orilẹede Naijiria ti kede iyọkuro owo iranwọ ori epo ni awọn araalu ti n ke irora pe gbogbo nnkan to gbowolori sii.
Botilẹ jẹ wi pe ijọba ti gbe ọkanojọkan igbesẹ lati mu ki nnkan dẹrun fun awọn eeyan ilu, ko tii fi bẹẹ si iyatọ pupọ ninu awọn ipenija to n ba awọn eeyan finra.
Yatọ si ẹgbẹ awọn olomi to kede adinku ti yoo ba bi wọn ṣe n ta omi, jakejado orilẹede Naijiria ni a ti ri ẹgbẹ awọn oniṣẹ ọwọ ati ontaja to da iṣẹ silẹ nitori iṣoro eto ọrọ Ajẹ.
Laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn to n ta ẹjẹ nilu Ilorin n'ipinlẹ Kwara da iṣẹ silẹ fun ọsẹ kan gbako, nitori awọn ipenija to n koju karakata wọn.
Ariwo ti wọn mu bọ ẹnu ni pe paali ẹja Shawa to jẹ ẹgbẹrun mejidinlogun Naira tẹlẹri ti di ẹgbẹrun marundinlogoji, paali ẹja Panla ti wọn n ta ni ẹgbẹrun mẹẹdogun di ẹgbẹrun marundinlogoji, bẹẹ sini ẹja Alaran ti kuro ni ẹgbẹrun marundinlaadọta ti o wa tẹlẹri, lo si ẹgbẹrun marundinlọgọrin Naira.















