Olórí Ìjọba Guinea tí àwọn agbébọn tú silẹ̀ tí padà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n

Aworan Camara

Oríṣun àwòrán, AFP

Olori ijọba ologun tẹlẹri lorilẹede Guinea, Moussa DadiS Camara, ti pada si ọgba ẹwọn lẹyin ti awọn agbebọn kan yabo ọgba ẹwọn to wa, ti wọn si tu silẹ, gẹgẹ agbẹjọro ṣe salaye.

Awọn agbebọn yii yabo ọgba ẹwọn ni olu ilu, Conakry lowurọ ọjọ Satide , ti wọn si tu Camara ati eeyan mẹta mii silẹ.

Awọn to wa ni ahamọ bayii lo n jẹjọ lori ti wọn fi kan wọn pe wọn lọwọ ninu iku eeyan toto aadọjọ lọdun 2009 lasiko ifẹhonuhan.

Yatọ si Camara, awọn ẹlẹwọn meji yooku naa ti pada si ọgba ẹwọn.

A ko le fidi rẹ mule boya wọn ji wọn gbe ni tabi awọn ololufẹ wọn lo wa tu wọn silẹ.

Agbẹjọro Camara sọ fun BBC pe olori ijọba tẹlẹri ni ko fẹ tẹle awọn agbebọn naa nitori o ni igbagbọ ninu eto idajọ, ti ko si ni sa kuro lọgba ẹwọn.

Àwọn agbébọn yabo ọgbà ẹ̀wọ̀n, tú olórí Ìjọba Guinea tẹ̀lẹ̀rí sílẹ̀

Awọn agbebọn kan yabo ọgba ẹwọn, ti wọn si tu olori ijọba ologun tẹlẹri lorilẹede Guinea, Moussa Dadis Camara silẹ kuro ni ahamọ to wa.

Adajọ agba lorilẹede naa lo fi di ọrọ naa mulẹ lọjọ Satide.

Owurọ ọjọ Satide ti ikọlu waye ni ọgba ẹwọn ti Camara wa, ti wọn si tu Ọgagun agba naa ati eeyan mẹta mii silẹ.

Camara ati mẹta yooku lo wa lọgba ẹwọn lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku eeyan toto aadọjọ ni iye ninu ifẹhonuhan kan to waye lọdun 2009.

Gbogbo ẹnu ibode orilẹede Guinea lo ti wa ni titi pa bayii nitori awọn afurasi naa.

Adajọ agba lorilẹede naa, Charles Alphonso Wright lo kede isẹlẹ naa lori Redio lọjọ Satide.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“A yo wa wọn ri, ti wọn a yoo si fi iya jẹ wọn labẹ ofin.”

Iro ibọn dun lakọlakọ ni Conakry lati aṣalẹ ana. Ilu naa da paro, ọkọ ileeṣẹ ologun wa kakiri gbogbo agbegbe.

Lara awọn ti wọn tu silẹ pẹlu Camara ni Ọga ologun Claude Pivi, minisita tẹlẹri ti wọn fẹsun kan pe oun naa lọwọ ninu iku awọn eeyan to jade laye ni paapa iṣere Conakry ninu oṣu kẹsan an ọdun 2009.

O to eeyan mẹtadinlọgọjọ to jade laye lasiko ti awọn ọmọ ologun ṣekọlu si awọn eeyan to fẹhonuhan tako iṣejọba ologun.

Bakan naa ni ọpọ obinrin lugbadi ifipabanilopọ lasiko isẹlẹ.

Camara ati awọn mẹwaa ni wọn fẹsun kan sugbọn ti wọn awọn ko mọ nkankan nipa isẹlẹ naa ati ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Camara gba agbara lọdun 2008 lẹyin ti Aarẹ Lansana Conte jade laye sugbọn o sa kuro ni ilu lẹyin ikọlu ti ọpọ eeyanti padanu wọn ni Conakry.

Camara, ẹni ọdun mọkandinlọgọta lo ti n gbe lorilẹede Burkina Faso ko to wa pada si Guinea ninu oṣu kẹsan an ọdun 2022 lati foju wina ofin.

Orilẹede Guinea wa labẹ iṣejọba ologun bayii, to si jẹ ọkan lara oriẹede to gba ijọba lọwọ ile France ti iditẹgbajọba ti waye laarin ọdun mẹwaa.