Wo àwọn gbajúmọ̀ tí wọ́n pàdánú ẹ̀mí wọn lẹ́ni ọdún 27

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni ìkéde ikú gbajúgbajà olórin tàkasúfèé Oladimeji Alabama tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí MohBad gba orí ayélujára.
Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ló wà tó fi jáde láyé.
Ikú Mohbad ló ti ń fa onírúurú awuyewuye lórí ayélujára tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ sì ń ṣe ìdárò rẹ̀.
Yàtọ̀ sí Mohbad, ọ̀pọ̀ àwọn gbajúmọ̀ òṣèré àti olórin ló ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Èyí ni àkójọpọ̀ àwọn gbajúmọ̀ tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Dablixx Osha

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé, Oniyide Azeez tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Dablixx Osha jáde láyé ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kọkànlá ọdún 2022.
Dablixx Osha tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹrin ọdún 1995 jáde láyé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Nígbà tí wọ́n ń kéde ikú rẹ̀, àwọn ẹbí rẹ̀ só wí pé inú ló sọ wí pé ó ń run òun kí wọ́n tó gbe dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn.
Ní ilé ìwòsàn náà sì ni ó kú sí.
Anton Viktorovich Yelchin

Oríṣun àwòrán, Others
Ní ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kéta ọdún 1989 ni wọ́n bí gbajúmọ̀ òṣèré Anton Yelchin tó sì jáde láyé lọ́jọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹfà ọdún 2016 lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Òṣèré ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni Yelchin nígbà ayé rẹ̀.
Ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Russia ni àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ kó lọ sí Amẹ́ríkà nígbà tó wà ní ọmọ oṣù mẹ́fà.
Shot

Oríṣun àwòrán, Others
Olórin tàkasúfèé ni Evgeny Yurievich tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Shot nígbà tó wà láyé.
Ní ọjọ́ Kìíní oṣù Kejìlá ọdún 1989 ni wọ́n bí Shot tó sì dágbére fáyé ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kẹsàn-án ọdún 2017.
Àìsàn ìtọ̀ ṣúgà ló ṣekúpa Shot.
Kim Jong-hyun

Oríṣun àwòrán, Others
Olórin, akọrin, òǹkọ̀wé àti agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní orílẹ̀ èdè South Korea ni Kim Jong-hyun kó tó jáde láyé.
Ní ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹrin ọdún 1990 ni wọ́n bi, tó sì jáde láyé ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2017.
Kim Jonghyun lọ gba yàrá fún ọjọ́ méjì ní Cheongdam-dong, Gangnam ṣùgbọ́n kò ju bíi wàkátì mẹ́rin lọ tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí ní pe àwọn ènìyàn pé Jonghyun ń fi àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tó bani lẹ́rù ránṣẹ́ sí òun.
Ó ní ó jọ wí pé Jonghyun fẹ́ pa ara rẹ̀ lẹ́yìn náà ni wọ́n kéde ikú rẹ̀.
Derrick Antonio Coleman
Ní ọjọ́ Kẹrin oṣù Keje ọdún 1990 ni wọ́n bí Derrick Antonio Coleman tó sì jáde láyé ní ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kìíní ọdún 2018.
Derrick Antonio Coleman tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Fredo Santana ló jẹ́ olórin tàkasúfèé ní oríll èdè Amẹ́ríkà.
Gìrì ló pa Santana lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.












