Ńṣe ló dà bíi ìgbà tí ayé fẹ́ parẹ́ – Àwọn ogúnléndé Gaza sọ ìrírí wọn

A man, sitting on debris, clutches his head as Palestinians conduct a search and rescue operation after the second bombardment of the Israeli army in the last 24 hours at Jabalia refugee camp in Gaza City, on 1 November 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, By Ethar Shalaby
    • Role, BBC Arabic

Ikilọ: Ole ri awọn nnkan ti yoo ba ọ ninu jẹ ninu iroyin yii.

Inu ile ni Suheil al-Talooli, ẹni aadọrin ọdun to jẹ ọmọ orilẹede Palistine wa pẹlu ọgbọn ninu awọn mọlẹbi rẹ nigba ti ado oloro orilẹ-ede Israel balẹ si ile awọn ogunlende ti wọn wa.

Suheil ni “Ni ṣe lo da bii igba ti iṣẹlẹ ilẹ riri n waye tabi pe opin aye ti de.”

Igba mẹwaa ni ado oloro dun leralera, ti gbogbo oju ọjọ si dudu pẹlu eefin.”

Dokita to ti fẹyintin naa ni oun gbagbọ pe ko si ẹni to tii la irufẹ nnkan bẹẹ kọja ri.

Suheil al-Talooli, talking on a phone while sitting on a sofa in a photo taken before the 31 October attack

Oríṣun àwòrán, Suheil al-Talooli

Àkọlé àwòrán, Suheil al-Talooli

Ado oloro gbẹ koto ti iwọn rẹ jẹ nita mẹwaa

Agbẹnusọ ileeṣẹ abo araẹni labo ilu ni Gaza, Mahmoud Basal sọ pe koto oni mita mẹwaa ni ado oloro naa gbẹ silẹ.

Lalẹ ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni ileeṣẹ eto ilera Gaza sọ pe ko din ni irinwo eeyan to farapa tabi ku ninu ikọlu naa.

Ile Suheil dawo le lori latari ado oloro to bale si agbegbe rẹ, o si daku rọgbọndan.

Lẹyin ti wọn fa a jade labe ile naa lo to taji, to si ri bi awọn ile to wa lagbegbe rẹ ṣe dahoro latari ado oloro.

Adugbo parẹ

O tẹsiwaju pe “Eefin gba gbogbo adugbo to bẹẹ ti ko si ẹnikẹni to lanfani lati ri ẹni to wa lẹgbẹ rẹ.”

“Lẹyin naa ni mo ri awọn oku to sun nilẹ rẹpẹtẹ, bẹẹ naa la ri awọn ẹya to pin wẹlẹwẹlẹ.”

“Gbogbo adugbo mi lo ti parẹ bayii ti ko si si ile kankan nibẹ mọ.”

Bo tilẹ jẹ pe awọn aburo rẹ ọkunrin atawọn rẹ moribọ, iyawọ rẹ, Kifah fi ẹsẹ ṣeṣe, o si ti dero ile iwosan.

Àkọlé fídíò, Watch: Explosion at Jabalia refugee camp on 31 October leaves a massive crater

Aburo Suheil obirin ṣalaye fun BBC pe ibatan ọkunrin naa bii mẹtadinlogun lo ti ku nigba ti awọn mọlẹbi rẹ mii si wa labẹ awọn ile to dawo.

Ikọlu lemọlemọ lati oju ofurufu

Ọjọ keji ti ẹgbẹ Hamas kọlu Israel ni ado oloro Israel bẹrẹ si n rọ le agọ awọn ogunlende Jabalia lori, ninu eyii ti eeyan 1,400 ti padanu ẹmi wọn.

Ado oloro akọkọ to balẹ si ọja Jabalia pa aadọta eeyan, gẹgẹ bii ohun ti Hamas sọ.

Ọjọ marun un lẹyin naa ni Israel kilọ fun awọn araalu to n gbe lagbegbe ọhun ki wọn kuro nibẹ ṣaaju ikọlu ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa.

Amọ Suheil juwe ikọlu ọjọ naa gẹgẹ bi eyii to buru julọ.

O ni “Ni ṣe ni awọn ọmọde ja si wẹlẹwẹlẹ.”

Mohamed Alaswed holding a camera lens in a street

Oríṣun àwòrán, Mohamed Alaswed

Ilẹ n mi titi

Asiko ti Mohamed Alaswed, ẹni nọdun mẹtadinlogun to n gbe ni agọ ogunlende Jabalia n ra elo ọbe ni ọja kan ni ado oloro naa dun.

O ni “Lojiji ni mo gbọ ado oloro mẹfa to dun leralera… ti eefin si bo gbogbo agbegbe naa.”

Ni kete ti ado oloro naa dun lo sare lọ sibẹ latari pe awọn mọlẹbi rẹ wa nibẹ, amọ ile ti dawo le awọn eeyan naa lori, to si ṣoro fun un lati yọ wọn jade.

Mo ri awọn ọmọde ti wọn n ko oku awọn ọmọde mii

Lẹyin ibugbamu naa ni awọn eeyan agbegbe ọhun bẹrẹ si n ko awọn oku atawọn to farapa lọ sile iwosan.

Mohamed ni “Mo ri awọn ọmọde to n ko oku awọn ọmọde mii.”

“Awọn abiyamọ n wa ẹkun mu bi wọn ṣe n wa awọn ọmọ wọn. O ṣoro lati mọ ohun to ṣẹlẹ ni akoko naa.”

Gẹgẹ bii ohun ti Mohamed, to jẹ ayaworan sọ fun BBC, ọpọ eeyan ni wọn ri yọ labẹ ile dawo ṣugbọn ti ẹya ara wọn ti ja sọnu sinu ile naa.

Wounded patients being treated on the floor in a photo posted by the hospital to social media

Oríṣun àwòrán, The Indonesian Hospital / Facebook

Ẹrọ amunawa ile iwosan kọṣẹ

Ile iwosan ilẹ Indionesia kan to wa lẹba Beit Lahia lo gbalejo awọn eeyan to pọju ti wọn farapa atawọn ti wọn ku.

Dr Marwan Sultan, The Indonesian Hospital
Àkọlé àwòrán, Marwan Sultan

Adari ile iwosan naa, Marwan Sultan, sọ fun BBC pe nnkan bii aago kan ọsan ni ẹrọ amunawa rẹ kọṣẹ lẹyin ti epo bẹntiro tan ninu rẹ.

O ni “A ko ṣiṣẹ abẹ fun ẹnikẹni mọ ayafi awọn ti wọn ti wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

Rescuers carry a man on a stretcher from the aftermath of the 31 October Jabalia attack

Oríṣun àwòrán, Reuters

Dokita Sultan ni oun gbagbọ pe irufẹ awọn ohun ija oloro ti oun ko mọ ni Israel lo fun ikọu naa.

O ni pupọ ninu awọn ti wọn farapa ni ẹjẹ n da lara wọn lati inu wa, ti eegun awọn mii si run.

Amọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun Isreal, Israel Defense Forces (IDF) ni oun ko lagbara lati sọ fun BBC nipa irufẹ ohun ija ti awọn lo lati dojukọ Gaza.

Àkọlé fídíò, Watch: Video from 9 October from BBC Arabic inside the Jabalia refugee camp after an Israeli airstrike

Wọn ti pa ọkan lara awọn ọgagun Hamas

Lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ileeṣẹ ọmọ ogun Israel sọ ninu atẹjade kan pe ado oloro oun ti ṣekupa Ibrahim Biari, to jẹ ọgagun Hamas to kọlu Israel lọjọ keje, oṣu kan naa.

People stand around the edge of the giant crater at Jabalia refugee camp on 1 November 2023

Oríṣun àwòrán, EPA

Ẹwẹ, Hamas ti sọ pe ikọlu Israel si Gaza lọjọ kọkanlelọgbọn naa mu ẹmi eeyan meje to wa ni igbekun awọn lọ, ti mẹta lara wọn si jẹ ọmọ orilẹ-ede meji ọtọtọ.

Amọ agbẹnusọ orilẹ-ede Israel fun ọrọ ilẹ okeere, Lior Haiat, sọ fun BBC pe oun ko mọ ipo ti awọn eeyan to wa ni igbekun naa wa nitori Hamas ko gba ajọ adoola ẹmi, Red Cross lati rekọja sibẹ.

O ni “Ẹtan ni wọn fi n ja ogun, wọn si n fi awọn eeyan to jẹ alaiṣẹ gba ọta ibọn.”

“A ke si Hamas lati jọwọ gbogbo awọn to wa ni igbekun wọn silẹ ni kankan.”

“Ọwọ Hamas lo wa bi awọn eeyan naa yoo ku ni o tabi wọn yoo ye.”

Edited by Andrew Webb