Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìjàmbá iná tó pa eèyàn méjì tí ọ̀pọ̀ farapa ní 'Canada Embassy'ni Abuja

Aworan

Oríṣun àwòrán, aworan

Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni ina nla kan sọ ni Olu ileeṣẹ ilẹ Canada to wa niluu Abuja, nibi ti eeyan meji ti padanu ẹmi wọn ti awọn mi-in si tun farapa.

Gẹgẹ bi atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l’Abuja, Nkechi Isa fọwọ si ṣe ṣalaye, o ni àgbá epo dísù kan lo bu gbamu ni yara ẹrọ amunawa ta a mọ si jẹnẹrẹtọ, eyi to wa lolu ileeṣẹ ilẹ Canada l’Abuja.

O fi kun un pe eeyan meji lo ku ninu ijamba naa, awọn meji mi-in si wa nileewosan ijọba apapọ, iyẹn National Hospital Trauma Centre.

Ina naa jo wọn pupọ gẹgẹ bo ṣe sọ, ọmọ orilẹ-ede Naijiria si lawọn to fara kaaṣa iṣẹlẹ naa.

Atẹjade naa tẹsiwaju, pe ikọ ẹlẹni marun-un kan lo n ṣatunṣe si ẹrọ jẹnẹretọ kan to bajẹ nibẹ lọwọ. Ina sọ nigba ti tanki epo disu ẹlẹgbẹrun lita gbina lojiji, ni nnkan bii aago mọkanla ku iṣẹju mẹẹẹdogun, o si to aago mejila aabọ ọsan ki ajọ panapana ilẹ wa too ri ina naa pa.

Aarẹ Bọla Tinubu ti wa ba ijọba orilẹ-ede Canada kẹdun, pẹlu awọn ọmọ orilẹde naa to n ṣisẹ nilẹ yii ati gbogbo eeyan ti iṣẹlẹ naa kan. Aarẹ sọ pe Naijiria ṣetan lati fun wọn latulẹyin to tọ lori ijamba ina naa.