Mọ̀ si nípa àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú tó fẹ́ tukọ̀ Kogi

Oríṣun àwòrán, DINO MELAYE/AHMED USMAN-ODODO/ADEJO OKEME
Bi eto idibo gomina ṣe n sumọ nipinlẹ Kogi, ti ọpọ n si gbaradi pe tani yoo gba ipo Gomina lọwọ Gomina Yahaya Bello.
Ẹgbẹ oṣelu APC, PDP ati SDP ti bẹrẹ ipolongo ibo kaakiri ipinlẹ naa ti wọn bawọn araalu sọrọ pe ki wọn dibo fun wọn sugbọn awọn wo gan ni awọn oludije ẹgbẹ oṣelu to n kopa ninu eto idibo ipinlẹ Kogi.
BBC se akọjọpọ awọn oludije lati ninu ẹgbẹ oṣelu APC, PDP ati SDP ati bi wọn ṣe bẹrẹ irinajo wọn ninu eto oṣelu Naijira.
Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Ọdun 1974 ni wọn Dino Melaye, ẹni to ti fi igba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin orilẹede Naijiria to n ṣoju ẹkun idibo iwọ oorun nipinlẹ Kogi
Ilu Ayetoro Gbede ni ijọba ibilẹ Ijumu nipinlẹ Kogi ni Dino Melaya ti wa, to si jẹ oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Dino Melaye bori eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP lẹyin to fidi alatako rẹ Jabiru Usman janlẹ.
Ọdun 2015 ni Dino Melaye kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ti awọ bẹ silẹ,to si pada si ẹgbẹ oṣelu PDP lati gbaradi fun ẹto idibo lọdun 2019.
Melaye jade dupo fun gomina lọdun 2019 nipinlẹ Kogi sugbọn to padanu sọwọ Gomina Yahaya Bello, to si ṣe ipo kẹta.
O tun jẹ agbẹnusọ lori eto idibo Aarẹ to wa ninu oṣu kẹta fun Igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar
Usman Ododo

Oríṣun àwòrán, Usman Ododo
Ọdun 1982 ni wọn bi Ahmed Usman Ododo nipinlẹ Ogun.
Ẹya Ebira ni Ododo ti wa lati Okene.
Oun ni oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo Gomina to n bọ.
Usman Ododo jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin awọn ọdọ lorilẹede Naijiria to si tun jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina Yahaya Bello lori ọrọ ọdọ.
Yatọ si pe o jẹ oludamọran fun Gomina, Ododo ni oluyẹweowowo tẹlẹ nipinlẹ Kogi.
Ahmed Usman lọ ile ẹkọ Fasiti Ahmadu Bello ni Zaria ni bi to kawe gboye ninu imọ nipa isiro.
Murtala Ajaka

Oríṣun àwòrán, Murtala Ajaka
Murtala Yakubu Ajaka jẹ ọkan lara oludjje to ri ijakulẹ lasiko eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu APC, to si morile ẹgbẹ oṣelu SDP.
Ajaka, ẹni ọdun mẹrinlelogoji lo wa lati ijọba ibilẹ Odulu nipinlẹ Kogi..
Agba ọjẹ ẹgbẹ oṣelu APC iu Ajaka ko to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lọ sinu ẹgbẹ oṣelu SDP, to si jẹ pe oun lo n soju ẹgbẹ SDP gẹgẹ bi oludije Gomina ninu eto idibo to n bọ.
Ajaka kawe gbaoye ninu imọ Sociology ni Fasiti ilu Abuja.
Ẹgbẹ PDP ati LP parapọ fun eto idibo Gomina

Oríṣun àwòrán, Dino Malaye
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Kogi kede ifọwọsowọpọ wọn pẹlu ẹgbẹ oṣelu Labour Party saaju eto idibo Gomina to n bọ nipinlẹ.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu mejeeji tọwọbọ fun awọn akọroyin salaye pe ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti tẹwọgba Dino Melaye gẹgẹ bi oludije Gomina wọn.
"Inu wa dunh lati kede fun iyin pe a ti fi itan balẹ lonii.
"Ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour Party ti gba lati parapọ lati mu Dino Melaya gẹgẹ bi Gomina ti yoo soju ẹgbẹ oṣelu mejeeji lọjọ kọkanla oṣu yii."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












