Alfa Okutagidi wọ́gilé ẹjọ́ tó pe Iya Ọsun, Abẹbi Obalowu Jimoh n’Ilọrin

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Alfa Okutagidi, wọgile ẹjọ to pe Oniṣẹṣe kan tẹlẹri Abẹbi Ẹfunṣetan Yakubu, to ti di Iya Onikurani bayii ati Obalowu Jimoh, nile ẹjọ Majisireeti kan ti wọn wọ won lọ, wọn ni awon olujẹjọ naa ti tọrọ aforijin.

Tẹ o ba gbagbe Ọmọọba Ademọla Ajaṣa lo wọ awọn Oniṣẹṣe mejeeji yii lọ sile-ẹjọ lorukọ Alfa Okutagidi, to n gbe ni No 105, lagbegbe Pakata, niluu Ilọrin.

Wọn fẹsun kan awọn olujẹjọ mejeeji pe wọn ya fidio kan to gba ori ayelujara, nibi ti Iya Ọṣun Abẹbi ti ni oun ran Alfa Okutagidi lọwọ ti iyawo rẹ fi rọmọ bi, ati pe oun di gbẹgbẹ fun iyawo rẹ.

Eyi lo mu ki wọn fẹsun igbimọpọ, ibanilorukọjẹ, ati dida omi alaafia ilu ru kan Abẹbi ati Ọbalowu, ti adajọ si fibinu sọ wọn sẹwọn.

L’Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, oṣu Kẹjọ, ni Onidaajọ Muhammad Adam, gba beeli awọn mejeeji ni odiwon ẹgbẹrun lọna igba Naira (200,000) pẹlu oniduuro meji, ko to sun igbẹjọ siwaju.

Loni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ Keje, oṣu Kọkanla yii, ni agbẹjọro Alfa Okutagidi, iyẹn Usman Saad Imam, sọ fun ile ẹjọ Majisireeti naa pe Iya Oni Kurani ati Ọbalowu ti bẹbẹ, wọn ti tọrọ aforijin, fun idi eyi onibaara oun, Okutagidi ti dari ji wọn tawọn ko si ni ẹjọ kankan ṣe pẹlu wọn mọ, ki wọn o maa lọ layọ ati alaafia.

Ni onidaajọ Majisireeti Muhammad Adam ba wọgile ẹjọ wọn.

Lasiko ti Iya Ọsun Abẹbi, wa ni ahamo, lo ni oun ko ṣe ẹṣin iṣẹse mọ, to si darapọ mọ ẹṣin Isilaamu, to si bẹrẹ si ni kirun lo ba yi orukọ rẹ pada lati Iya Ọsun to n jẹ tẹlẹ si Iya Onikurani, ti ọpọ awọn musulumi si se ileri oriṣiriṣi ẹbun bii owo, mọto ati riran-an lọ si ilẹ Saudi Arabia lati lọọ jọsin fun un.

Boya awọn ẹbun yii ti wa tẹ ẹ lọwọ bayii ku si ọwọ rẹ ati awọn to seleri awon ẹbun naa fun un.

Alfa mìíràn tún wọ́ Tani-Olohun lọ sílé ẹjọ́ fẹ́sùn pé ó dáná sun Kùránì

Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Gbbajumọ oniṣẹṣe, Abdulazeez Adegbola ti wọn pe n ni Tani Ọlọhun yoo tun foju ba ile ẹjọ Majisireeti loni ọjọ Keje, ọjọ Isẹgun ọdun 2023 ni ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Ẹsun tuntun miiran pe Tani Olohun dana sun Kurani ni Ọjọgbọn Ali Agan to jẹ Alfa ile kewu Mọdirasa Muhammad wọ ọ lọ sile ẹjọ fun.

Eekan onisẹse yii lo ti ń jẹjọ lati ọjọ kẹrinla osu kẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.

Lọtẹ yii ẹsun jijo Kurani nina ni wọn gbe ka ile ẹjọ.

Ọjọgbon Ali Agan jẹ Olukọ ni ẹka imo ẹṣin Islam ni fasiti Ilọrin, o si tun jẹ gbajugbaja Alfa.

Pẹlu ẹjọ tuntun yii, o ti wa di olupẹjọ mẹrin ọtọọtọ bayii lori Tani-Ọlọhun nikan ni ile ẹjọ mẹrin ọtọọtọ.

Awon Olupẹjọ naani, Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin (Ogo Ilorin), Alfa Okutagidi, Shaikh Labeeb Lagbaji ati Ọjọgbon Ali Agan ti igbẹjọ tirẹ yoo waye lonii

Ile ẹjọ meji ti gba beeli olujẹjọ naa bayii.