Kí ló dé ti àwọn ológun France fi wà ní Africa?

Aworan awọn ọmọ ogun France

Oríṣun àwòrán, Getty

Ọwọja iditẹgbajoba jakejado awọn orileede kan ti ilẹ Faranse ko lẹru nigba kan rí ni Africa ti wa jẹ kó ṣe pataki ki France maa fi ọrọ ipa to n ko lagbo ologun ṣere.

Iwọde lorisirisi ti n waye ni itako si ipa France l'awọn orileede to ti ṣaaju jẹ gaba le lori.

Ni Mali ati Niger laipẹ yi ni wọn le awọn ọmọ ogun kuro nilẹ wọn.

Koda awọn orileede mii naa ti n gbero lati yọwọ ninu awọn adehun ti wọn ṣe pẹlu France ṣaaju ki won6 to gbà ominira.

Awọn adehun lo fa ti France ko fi yọ ẹyìn lọrun awọn orileede yi to sì jẹ pe o ṣokunfa o kere tan iditẹgbajọba ọgbọn laarin odun 1964 sí 1995.

Ki ló de ti awọn ologun France fi wa ni Africa?

Dr Bakary Sambe to jẹ adari ileeṣẹ itẹsiwaju imọ Timbuktu Institute sọ pe lati igba ti awọn orileede Afrika kan gba ominira ni ilẹ Faranse ti ni ọkan lati fẹsẹ wọn rinlẹ lori wọn.

Loju ilẹ Faranse ibi ti eeyan ti n lo agbara lo ri awọn orileede Afrika kan si.

Ero rẹ papọ pẹlu ti Ọjọgbọn Bruno Charbonneau, ti o jẹ onimọ nipa alaafia ati ikọlu nilẹ Afrika ni Royal Military College ti Saint Jean.

''Nini awọn ọmọ ogun bi France ti ṣe ni wọn lawọn orileede Africa kan jẹ ọna kan gbogi ti wọn fi wa laarin gbungbun eyikeyi ikọlu to ba n waye lawọn orileede yi ni paapa ti wọn ba de igbimọ alaṣẹ ajọ isọkan agbaye.''

O fikun pe Ipese iranwọ ologun fawọn orileede Afrika to wa ni ikapa rẹ yi tunmọ si pe France yoo le mojuto awọn nkan ti yoo ṣe anfaani fun ti yoo si jẹ ko le tete ko ọmọ ogun silẹ ti asiko ba to.

Awọn orileede wo lo yi ni ibudo ologun ni Afrika?

Bo ti lẹ jẹ wi pe iye awọn orileede yi ti diku lẹnu ọdun meloo kan sẹyin, ọkẹ aimọye awọn ọmọ ogun ilẹ Faranse lo ṣi wa lawọn orileede wọnyii:

  • Chad: Iye awọn ọmọ ogun France to wa lorileede yi sunmọ ẹgbẹrun kan ti wọn si n pe orukọ wọn ni French forces in Chad (EFT).Wọn wa ni olu ilu illẹ naa N'Djamena,
  • Abeche ni ila oorun ati ni Faya to wa ni ariwa ilẹ naa.Iṣẹ wọn ni lati daabo bo awọn ohun ini ilẹ France ti wọn a si tun maa ṣe iranwọ aabo lajọṣepọ pẹlu awọn ọmọ ogun ilẹ Afrika lagbegbe naa.
  • Gabon: Lati igba ti orileede yi gba ominira ni ọdun 1960 ni ikọ ọmọ ogun France ti tẹdo silẹ yi.Awọn ọmọ ogun 350 lawọn ọmọ ogun yi.
  • Wọn tẹdo si ibudo ọmọ ogun Charles De Gaulle to wa ni Libreville ti ikọ ọmọ ogun ofurufu kan naa si wa ni ibudo ofurufu Guy Pidoux.

Kí ló dé tí ilẹ́ Faransé fí nífẹ sí ìdásílẹ̀ ibùdó ológun ní Africa?

Awọn ibomiran tawọn ọmọ ogun yi tun tẹdo si ni awọn ilẹ Africa ni Ivory Coast ati ni Senegal.

Iye ọmọ ogun to wa ni Ivory Coast lati nkan bi ọdun mẹtala sẹyin jẹ 950.Iye awọn ti Senegal si jẹ 400.

Losu to kọja awọn ọmọ ogun 1300-1500 ti wọn fi ṣọwọ si Niger pẹlu ọkọ ija ofurufu,diroonu ti wọn fi n koju awọn agbesunmọmi ni wọn ti bẹrẹ si ni ko ẹru wọn kuro nibẹ lẹyin tawọn ologun to gbajọba loṣu Keje paṣẹ ki wọn kuro .