France ṣetán láti kó 1,500 ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní Niger – Macron

Niger coup

Oríṣun àwòrán, reuters

Aarẹ orilẹ-ede France, Emmanuel Macron ti kede pe orilẹ-ede naa yoo ko awọn ọmọ ogun ati aṣoju ijọba rẹ kuro ni orilẹ-ede Niger lẹyin iditẹgbajọba to waye nibẹ.

Macron ni “France ti ṣetan lati ko awọn aṣoju ijọba rẹ, laarin wakati diẹ si asiko yii, awọn aṣoju rẹ yoo pada si France.”

O fi kun pe ibaṣepọ ileeṣẹ ọmọ ogun Niger ati France ti dopin ati pe laarin oṣu diẹ si asiko yii ni awọn ọmọ ogun France to wa ni Niger yoo pada sile.

“Inu wa dun bi France ṣe n kuro nilẹ wa”

Ẹwẹ, awọn ọmọ ogun to ditẹgbajọba ni Niger ti sọ pe inu awọn dun si igbesẹ France lati ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro nilẹ awọn.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin AFP, awọn ologun naa ni “Ọjọ Aiku ọsẹ yii ni a o ṣe ajọyọ igbesẹ tuntun fun ominira Niger.”

Lọwọ yii, ko din ni ẹgbẹrun kan abọ ọmọ ogun France to wa ni Niger.

Igbesẹ France lati ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Niger lo n waye lẹyin ọpọ ifẹhonuhan awọn eeyan orilẹ-ede Niger lodi si awọn ọmọ ogun France.

Lara awọn ilu ti ifẹhonuhan ọhun ti milẹ julọ ni ilu Naimey, to jẹ olu ilu orilẹ-ede naa.

Amọ ṣa, awọn onwoye kan gbagbọ pe igbesẹ naa yoo ṣe akoba fun agbara ti France ni lorilẹ-de naa atibo ṣe n gbogun ti awọn agbesumọ nibẹ.

Ṣugbọn Aarẹ Macron ni oun ko le tori agbara jẹ ki awọn kọlọrọsi kan mu orilẹ-ede oun ni igbekun.

Macron fi kun pe Aarẹ ti wọn gba ipo lọwọ rẹ, Mohamed Bazoum, nikan ni oun mọ gẹgẹ bii ojulowo Aarẹ ni Niger.

Niger jẹ ọkan lara awọn orilẹ-ede ti France ko lẹru pẹlu awọn orilẹ-ede mii bii Burkina Faso, Guinea, Mali ati Chad ṣaaju ominira.