NLC, TUC kéde Ìyanṣẹ́lódì, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn alasẹ ẹgbẹ oṣisẹ orilẹede Naijiria NLC ati TUC ti kede pe awọn yoo bẹrẹ iyansẹlodi lati ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrinla oṣu kọkanla ọdun 2023.
Ikede yii jade lẹyin ti ẹgbẹ mejeeji ṣe ipade niluu Abuja.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ awọn ti bẹrẹ si ni ma mfi to awọn ọmọ ẹgbẹ lati lẹsẹkẹsẹ.
Igbesẹ yii lo da lori bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ikọlu Aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero nipinlẹ Imo lọsẹ to kọja, ti wọn si lu ni alubami.
Ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ osisẹ fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ marun un lati parọ Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Imo,
Bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu Gomina Hope Uzodimma, ẹni to n gbero lati wọ ile saa keji fun ikọlu to waye si Ajaero pẹlu bi Gomina ṣe ni oun ko mọ ohunkohun nipa ikọlu naa.
Ẹgbẹ Osisẹ tun ni ki wọn fẹ ki ijọba fofin gbe amugbalẹgbẹ Gomina, ko si foju ba ileẹjọ.
Wọn wa jẹ ko di mimọ pe awọn yoo bẹrẹ iyansẹlodi ti ijọba apapọ ba kuna lati ṣe ohun ti wọn fẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki lo sẹlẹ saaju?
Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ti fẹsun kan ileeṣẹ Ọlọpaa pe wọn lu Aare ẹgbẹ naa, Joe Ajaero ni alubami lẹyin ti wọn mu nipinlẹ Imo lọsan Ọjọru.
Agbẹnusọ ẹgbẹ NLC, Benson Upah lọ sọ eyi ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin, to fi di rẹ mulẹ pe Ajaero tí kuro ni ahamọ.
O ni, "A ti ba Aarẹ ẹgbẹ sọrọ ni nnkan bi ago mẹta abọ ni ile iwosan ti ileeṣẹ Ọlọpaa ni Owerri, nibi wọn ti gbe lọ Ile iwosan ìjọba apapọ níbi to ti n gba itọju bayii."
Sugbọn, Ileeṣẹ Ọlọpaa ni awọn mu Ajaero lọ agọ wọn lati le da bobo ẹmi rẹ sugbọn ẹgbẹ NLC ni wọn ṣekọlu sì Aarẹ ẹgbẹ naa lẹyin wọn mu.
"Alubami ní wọn na, oju ọtun rẹ ti pade," Upah salaye.
"Ajaero ninu ọrọ diẹ to salaye ni lẹyin ti wọn mu oun, wọn na oun, ti wọn si fi nnkan de loju gbe lọ ibi ẹnikẹni ko mọ, ti wọn si fìyajẹ."
Upah ni ẹrọ ibanisọrọ, owo ati awọn dukia mii ni wọn gba lọwọ Ajaero tí wọn kò si ti dapada fun.
Ileeṣẹ Ọlọpaa nawọ gani Ajaero ni ọfisi NLC to wa ni Owerri.















