Ìbẹ̀rùbojo tún dé bá abúlé Borno, Boko Haram gé orí àwọn àgbẹ̀ mẹ́tàlá l'óko

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn araalu kan tun ti bọ si ipo ibẹrubojo ni ipinlẹ Borno lẹyin ti awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi ṣekupa awọn agbẹ mẹtala nibẹ.
Igba keji ree laarin ọdun mẹta ti iru iṣẹlẹ yi yoo maa waye.
Awọn to ribi moribọ ninu ikọlu awọn alaburu yi sọ pe awọn ikọ Boko Haram bẹ ori awọn agbẹ mẹtala sinu oko wọn ni ijọba ibilẹ Mafa ni aarin gbungbun ipinlẹ Borno nirọlẹ ọjọ Aiku.
Lọjọ Aje ni wọn sinku awọn to kagbako iku lọwọ ikọ yi ni Zabarmari, agbegbe tawọn eeyan ti n dako to jina ni iwọn kilomita mẹẹdọgbọn si Maiduguri.
Awọn olugbe sọ pe awọn agbẹ naa ti wọn wa lati abule Koshebe ati Karkut n lu nkan woro ninu oko lọwọ lawọn ọmọ ikọ Boko Haram ṣadede yọ si wọn.
Wọn ko ara wọn wa ni isọri isọri ni ti wọn si jade wa lati ọna orisi lati dena awọn to wa ninu oko.Awọn agbẹ kan ribi sa ṣugbọn wọn bẹrẹ si ni ge ori awọn ti wọn ka mọ inu ojo.
Bẹẹ ni agbẹ kan to moribọ ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Naijiria nii Daily Sun ninu ifọrọwero to waye lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
Ọdun mẹta sẹyin ni iru ikọlu bayi waye kẹyin

O sọ pe nkan bi ago marun un irọlẹ ọjọ Aiku ni ikọlu naa waye ati pe awọn ṣi n wa awọn eeyan kan to di awati lẹyin ikọlu ọhun.
Ahmad Khali, olugbe Zabarmani kan sọ pe''A o le sọ boya awọn Boko Haram lo ji awọn to di awati lọ tabi pe wọn si sọnu ninu igbo.A ti sin eeyan mẹtala lonii(ọjọ Aje)''
Ọkan lara awọn fijilante araalu to ni ki wọn forukọ bo ohun laṣiri gẹgẹ bi Daily Sun ṣe jabọ sọ pe o ṣeeṣe ki awọn agbesunmọmi yi gbe alupupu wọn pamọ si inu igbo ki awọn agbe naa ma ba mọ nigba ti wọn yọ wọle tọ wọn.
Ninu ikọlu miran to waye ni ijọba ibilẹ Bama lọjọ Aiku yi kanna Boko Haram ṣekupa baba oloko kan ti wọn si ji awọn oṣiṣẹ rẹ mẹrin ton ṣiṣẹ lọwọ ninu oko rẹ.
Awọn agbe lagbegbe Zabarmari ti ikọlu yi tiwaye tun ti bẹrẹ si ni jaya tori pe irufẹ ikọlu yi waye lọdun mẹta sẹyin.
Ninu ikọlu to waye nigba naa lọhun, o gba awọn agbẹ lasiko diẹ koda o to ọdun kan ki awọn mii to le pada si oko irẹsi wọn.
Idi si ni pe awọn ti wọn ṣeku pa nigba naa lọhun to ọgọrun kan agbẹ.
Zabarmari jẹ ibi kan ti awọn agbẹ ti n gbin irẹsi pupọ ni ipinlẹ Borno ti ọpọ a si maa fọkan ijẹ imu sidi dida oko tabi tita irẹsi to ba wa lati ibẹ.
Iroyin taa gbọ laipẹ yi ni pe ikọ ọmọ ogun Naijiria ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ribi dina ikọlu kan ti awọn ikọ Boko Haram fẹ ṣe si Kano ni nkan bi ọjọ meji sẹyin.
Ni ijọba ibillẹ Gezawa ni Kano ni wọn ti kọdi awọn alaburu yi lowurọ kutu ọjọ Abamẹta.
Ọwọ tẹ awọn meji ninu ikọ Boko Haram ti wọn lero pe wọn gbimọran lati ṣe ikọlu si Kano.
Awọn meji yi wa ni ahamọ awọn agbofinro bayii.
A ko ti gbọ nkankan nipa boya ọwọ tẹ awọn to ṣe ikọlu to waye si Zabarmari titi di asiko taa n ṣe akojọ iroyin yi.












