Ọ̀dọ́bìnrin tó ní ìpèníjà ojú ń múra ìgbéyàwó létí òkun lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ táwọn dókítà fi pàrọ̀ ọkàn, ẹ̀dọ̀ àti kíndìnrín rẹ̀

Jessica Lopez jokoo sori aga nile iwosan nibi to ti wọ ṣokoto dudu ati ẹwu alaranbara lẹgbẹ mama rẹ

Oríṣun àwòrán, Northwestern Medicine

Àkọlé àwòrán, Ara Jessica Lopez tete ya ju bi awọn dokita gan an ṣe ro lọ
    • Author, Swaminathan Natarajan and Newsday Programme
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Jessica Lopez ti koju ọkan-o-jọkan ipenija lori ilera ara rẹ lati igba to wa ni kekere to fi dagba.

Lati kekere ni Lopez ẹni ọdun mejilelọgbọn lati ilu Chicago lorilẹede Amẹrika ko ti riran mọ.

Lopez tun ni arun jẹjẹrẹ, ṣugbọn o pada gbadun arun naa.

Laipẹ yii ni ọmọbinrin naa tun ṣe iṣẹ abẹ eyi tawọn dokita fi paarọ ọkan, ẹdọ ati kindinrin rẹ lẹẹkan naa.

Amọ, ni bayii, Lopez n mura lati bọ si ipele mii ninu igbesi aye rẹ - o ti n mura lati ṣe igbeyawo.

Lopez sọ fun BBC wi pe ọdun to n bọ loun n gbero bayii lati ṣe igbeyawo.

Iṣẹ abẹ to lewu

 Lopez re ni kekere to wọ aṣọ funfun ati sikaafu.

Oríṣun àwòrán, Family Handout

Àkọlé àwòrán, Lati igba to ti wa ni kekere ni Jessica ko ti riran mọ

Ile iwosan ni Lopez ti lo ọpọ igbe aye rẹ nigba to wa ni kekere, arun jẹjẹrẹ inu ẹjẹ ati jẹjẹrẹ oju lo sọ Lopez di ẹni ti ko riran mọ lati kekere.

O gba oriṣiiriṣii itọju ni kekere, ṣugbọn awọn itọju naa pada ni ipa ti ko dara lori lori agọ ara rẹ lọjọ iwaju.

Lọdun 2023 lawọn dokita sọ fun Lopez pe o nilo ọkan ati ẹdọ mii.

Nigba to n mura lati ṣe iṣẹ abẹ lati paarọ ọkan ati ẹdọ rẹ ni kindinrin rẹ naa ko ṣiṣẹ daadaa mọ.

Bo tilẹ jẹ pe o lewu, awọn dokita tẹsiwaju pẹlu iṣẹ abẹ lati paarọ ọkan, ẹdọ ati kindinrin Lopez lẹẹkan naa.

Lọjọ kẹrinlelogun oṣu Keji ọdun 2025 yii ni wọn ṣe iṣẹ abẹ naa fun Lopez.

Dokita Benjamin Bryner ile iwosan Northwestern Memorial Hospital ni Chicago ṣalaye pe gbogbo awọn dokita tawọn jọ ṣiṣẹ abẹ naa lo kọkọ jiroro lori nnkan to le ṣẹlẹ lẹyin iṣẹ abẹ ọhun.

Awọn dokita ti wọn n ṣe iṣẹ abẹ pipaarọ kindinrin, ẹdọ ati ọkan Lopez wọ aṣọ olomi aro pẹlu ibomu ni imu wọn

Oríṣun àwòrán, Northwestern Medicine

Àkọlé àwòrán, Ko din ni dokita mejila ti wọn jọ ṣiṣẹ abẹ lori Jessica Lopez

Wakati mẹwaa si mọkanla lawọn dokita naa fi paarọ ọkan ati ẹdọ Lopez, lẹyin naa ni wọn tun lo wakati mẹta si mẹrin mii lati ṣe iṣẹ abẹ lati paarọ kindinrin rẹ.

Awọn oṣiṣẹ eto ilera bii mẹẹdogun ni wọn ṣiṣẹ abẹ naa fun Lopez.

Iṣẹ abẹ lati paarọ ẹya ara mẹta ninu eeyan ko wọpọ rara, ile iwosan naa sọ pe igba mọkandinlọgọta pere ni iru iṣẹ abẹ yii ti waye lorilẹede Amẹrika.

Dokita Bryner ṣalaye pe ile iwosan oun maa n ṣiṣẹ abẹ lati paarọ ẹya ara inu eeyan kan tabi meji.

Amọ, o ni ara ọtọ ni iṣẹ abẹ ti wọn fi paarọ ọkan, ẹdọ ati kindinrin Lopez lẹẹkan naa.

Ọkan lara awọn nọọsi to ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn dokita ti wọn ṣisẹ abẹ lati paarọ ọkan Lopez n ba a sọrọ nibi to jokoo si.

Oríṣun àwòrán, Northwestern Medicine

Àkọlé àwòrán, Wọn ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun Lopez iru isẹ abẹ ti wọn fẹ ṣe fun un ki wọn to bẹrẹ

Dokita Bryner sọ pe ''loootọ ni a ti ṣe oniruuru iṣẹ abẹ fawọn eeyan, ṣugbọn eleyii lewu gan an.

A jiroro lori nnkan to le ṣẹlẹ lasiko iṣẹ abẹ naa ati lẹyin rẹ.''

Lara eeyan ni wọn ti gba ẹya ara mẹtẹẹta ti wọn lo fun Lopez ki o ba le ba ara rẹ mu.

Igboya ati ifojusọna fun esi rere

Jessica Lopez n lu aago lati ṣami wi pe o n fi ile iwosan silẹ.

Oríṣun àwòrán, Northwestern Medicine

Àkọlé àwòrán, Iṣẹ abẹ lati paarọ ẹya ara mẹta ninu eeyan ko wọpọ rara, ile iwosan naa sọ pe igba mọkandinlọgọta pere ni iru iṣẹ abẹ yii ti waye lorilẹede Amẹrika.

Lopez ni pẹlu igboya loun ṣe fi ara oun silẹ fun isẹ abẹ naa.

O ni oun ko tiẹ ro nnkan ti ko dara rara lori iṣẹ abẹ naa.

Lopez ni iṣẹ abẹ ipaarọ ẹya ara inu oun mẹta jẹ ko dabi ẹni pe wọn ṣẹṣẹ bi oun ni.

Jessica Lopez jokoo lori aga nile iwosan pẹlu awọn oṣiṣẹ ile iwosan lapa ọtun ati lapa osi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Northwestern Medicine

Àkọlé àwòrán, Iwuri ni bi ara Lopez to ti n ya jẹ fawọn to n tọju rẹ

Lopez ranti bi o ṣe beere lowọ Dokita Bryner wi pe wakati meloo ni wọn yoo fi ṣe iṣẹ abẹ naa.

O ni oun tun beere nipa iru oogun toun yoo maa lo lẹyin iṣẹ abẹ ọhun.

''Ọrọ ti mo kọkọ sọ lẹyin iṣẹ abẹ naa ni pe ọjọ wo ni a wa ati pe aago meloo lo lu.

Mo tun ṣakiyesi pe ọwọ ati ẹsẹ mi lọwọọrọ, ṣaaju iṣẹ abẹ naa ni ọwọ ati ẹsẹ mi tutu,'' Lopez lo sọ bẹẹ.

Lopez tun ṣe akiyesi wi pe oun le mi daadaa ju ti tẹlẹ lọ lẹyin iṣẹ abẹ to ṣe.

Igbe aye ilera

Jessica Lopez di ẹja dolphin mu ninu omi nigba ti obinrin kan duro lẹyin rẹ lati ran an lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Northwestern Medicine

Àkọlé àwòrán, Lẹyin to lo ọpọlọpọ oṣu nile iwosan, Lopez bẹrẹ si ni gbadun ara rẹ pada.

Iṣẹ abẹ ti wọn fi paarọ ọkan, ẹdọ ati kindinrin Lopez jẹ ki o lagbara si.

Lopez ni ''mi o maa sun mọ bi mo ṣe maa n sun tẹlẹ, ko rẹ mi mọ lati aarọ di alẹ bii ti tẹlẹ.''

Bo tilẹ jẹ pe lati kekere ni Lopez ti ni ipenija oju, ko sọ ireti nu rara.

O kọ nipa bi o ṣe le lo oriṣiiriṣii aapu lori itakun ayelujara.

''Ọwọ ni mo maa n lo lati wa awọn nnkan ti mo nilo lati fi dana.

Mo maa n se irẹsi, atawọn nnkan inu omi bii ẹja, bakan naa ni mo tun maa n se spaghetti,'' Lopez ṣalaye.

Lopez ko ṣai dupẹ lọwọ ẹbi to fi ẹdọ, ọkan ati kindinrin wọn silẹ fun un lati lo.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ ẹbi rẹ ati afẹsọna rẹ pẹlu fun ifẹ ati atilẹyin wọn.

Wiwo ọjo iwaju

Lonii, inu Dokita Bryner dun pe ara Lopez ti n ya daadaa.

O ni Lopez n ṣe daadaa ju bawọn dokita ṣe lero lọ.

Lopez ni ''mo ti ni okun bayii lati le gbe igbe aye alaafia pẹlu ẹbi mi.

Mo le rinrin ajo lọ sibi to ba wu mi bayii.''

Lopez ti n rin kaakiri lati gba atẹkun sara, koda, o tun ti n ṣe ere idaraya diẹdiẹ.

Ni bayii, Lopez ti n gbero lati pada sẹnu iṣẹ ati lati kẹkọọ nipa iṣẹ iwadii sayẹnsi.

Lopez ati afẹsọna rẹ Christopher duro niwaju akara oyinbo ti abẹla wa lori rẹ

Oríṣun àwòrán, Lopez family handout

Àkọlé àwòrán, Jessica Lopez ati afẹsọna rẹ Christopher n mura lati ṣe igbeyawo leti okun

''Mo fẹ maa ṣiṣẹ ni laabu, mo si tun fẹ maa gba ẹri lori iṣẹlẹ laabi to ba ṣẹlẹ.

O wu mi lati rinrin ajo lọ ṣiṣẹ nibo miran, mo fẹ kuro nibi ti mo wa bayii,'' Lopez lo sọ bẹẹ.

Jessica Lopez ati afẹsọna rẹ Christopher n mura lati ṣe igbeyawo leti okun lọdun to n bọ.