Kí ni ìtúmọ̀ Falana gbọ́ tìẹ, ọ̀nà wo ló fi le ṣe ìrànwọ́ fún ìlera ọpọlọ rẹ?

- Author, Majdi Goussous
- Role, BBC News Arabic
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Lọjọ ti mo wa lori itakun ayelujara Instagram ni mo ṣadeedee ri fidio kan ti o sọ pe ''ni bii ọdun mẹwaa si asiko ti a wa yii, waa maa bẹbẹ lati maa gbadun nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ,'' ọrọ yii lo wa loju iworan.
Eyi lo ran mi leti nnkan ti ọpọ eeyan maa n tiraka lati ṣe- gbigbe igbe aye lori nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ.
Eleyii maa n jẹ kawọn eeyan le maa pe akiyesi ara wọn si nnkan ti wọn n ro, bi ara wọn ṣe n ṣe ati nnkan to n ṣẹlẹ ni ayika wọn.
Bo tilẹ jẹ wi pe gbogbo eeyan lo n ṣiṣẹ ojọ wọn kaakiri, awọn onimọ nipa ero ọkan ẹda sọ pe ki eeyan maa ro nipa nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ dara fun ilera ọpọlọ.
''Mi o mọ pe igba to dara fun mi ni mo ti wa ṣaaju''
''Mo fi ọpọ ọdun ṣofo lati ri pe mo n ṣe daadaa sii, lai mọ pe mo tiẹ n ṣe daadaa gan an tẹlẹ lai mọ,'' Zeina lati Amman lorilẹede Jordan lo sọ bẹẹ.
O ni oun ṣaba maa n ṣakiyesi bi oju oun ṣe ri ati bi oun ṣe gbewọn to nigba toun wa ni ọmọ ogun ọdun le diẹ.
Amọ, ni bayii, Zein sọ pe oun ṣe aṣeju nigba naa lẹyin to wo awọn fọto to ya lasiko naa.
Raed toun jẹ amoju ẹrọ kọmputa ni oun maa n ṣaroye nipa iṣẹ to pọ tẹlẹ, koda oun tun maa n sọ pe ko ba wu oun ki oun paarọ iṣẹ.
Ṣugbọn Raed ni oju mii loun fi n wo o bayii lẹyin toun padanu iṣẹ naa.
Owo oṣu ti Raed n gba nibi iṣẹ to n ṣe tẹlẹ lo fi n tọju ara rẹ, ohun naa si lo fi n tọju ẹbi rẹ pẹlu.
O ni oun o mọ pe igbadun loun wa nigba naa ki iṣẹ to bọ lọwọ oun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ meji ni Ahmed bi, o si ti le logoji ọdun, o maa n fẹ kawọn ọmọ rẹ tete dagba ki o le ni isinmi funra rẹ.
Amọ, oju to fi n wo nnkan yatọ nigba tawọn ọmọ naa dagba tan.
''Bi wọn ṣe maa n sunkun, pariwo ati bi wọn ṣe maa n beere ibeere kan naa ni gbogbo maa n su mi nigba ti wọn wa ni kekere.
Ṣugbọn ni bayii, o wu mi lati maa gbọ ohun wọn ati awọn ibeere ti wọn maa n bi mi ni gbogbo igba,'' Ahmed lo sọ bẹẹ.
Ki lo de ti ọpọ ṣe maa n foju fo nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iriri Zeina, Raed ati Ahmed fi idi rẹ mulẹ pe gbogbo eeyan lo maa n pada mọ riri igba ti wọn ti gbe sẹyin.
Dokita Nawaf Al-Rifai to jẹ onimọ nipa ọrọ inu ọkan eniyan nile iwosan Irbid Medical Consulting Centre ni Jordan ṣalaye pe awọn eeyan maa n rinrin ajo ninu ọkan wọn lọ sibi awọn nnkan to ti ṣẹlẹ ṣẹyin ati nnkan to le ṣẹlẹ lọjọ iwaju.
Dokita Al-Rifai ni kii ṣe pe awọn eeyan ti wọn maa n foju fo nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ ko ni akiyesi.
O ni wọn maa n ṣaba ronu nipa oriṣiiriṣii nnkan lo maa n fa a.
Nibo ni ọrọ ki eeyan maa fọkan si nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ ti wa?
Ki eeyan maa fọkan si nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ wa lati inu aṣa awọn ẹlẹsin Buddhism.
Lati bii ọdun 1960 lọ soke lawọn onimọ sayẹnsi ti bẹrẹ si ni ṣe iwadii lori anfaani to wa ninu ki eeyan maa fọkan si nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ lati le fi wo ailera ọpọlọ.
Ọjọgbọn Jon Kabat-Zinn l'Amẹrika wa lara awọn akọṣẹmọṣẹ to ṣe agbekalẹ eto MBSR ni Fasiti Massachusetts Medical Center lọdun 1979.
Ọjọgbọn Kabat-Zinn sọ fawọn alaisan ti ara n dun lati maa ro nipa nnkan to n ṣẹlẹ si wọn lọwọ lasiko ti wọn fi ṣe eto ti wọn ṣe fun ọsẹ mẹjọ.
Iwadii Ọjọgbọn naa fidi rẹ mulẹ pe ki eeyan maa fọkan si nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ maa n ṣe iranwọ fawọn eeyan lati gbe igbe aye to dara lojoojumọ.
Ọjọgbọn Kabat-Zinn pada gbe abọ iwadii rẹ jade ninu iwe iroyin eto ilera.
Ni bayii, ajọ eleto ilera NHS ni UK ti n lo eyi lati maa ṣe itọju awọn alailera.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣiṣe afiwe ara ẹni pẹlu ẹlomiran
Safaa Al-Ramahi, to jẹ akọroyin aṣewadii, sọ pe o ṣee ki eeyan maa ri nnkan ti kii ṣe ootọ ti ẹni naa ba n wa lori ayelujara ni gbogbo igba.
O ni diẹdiẹ ni gbogbo awọn nnkan ti eeyan n ri lori ayelujara yoo maa wọ inu ero ọkan eeyan, eyi yoo si jẹ ki ẹni naa maa ro pe otitọ ni gbogbo nnkan to wa lori ayelujara.
Al-Rifai to jẹ onimọ nipa ero ọkan eeyan sọ pe wiwa lori ayelujara fun igba pipẹ lo maa n jẹ ki ọpọ eeyan fi ara wọn we ẹlomiran.
''A maa n sọ fawọn to ba n gba itọju wi pe ki wọn ma yẹ foonu wọn wo mọ tori ti wọn ba ti n ṣe bẹẹ ni wọn yoo maa fi ara wọn we ẹlomiran.
Eeyan ni lati maa ṣe agbeyẹwo awọn to jẹ ọrẹ eeyan lori ayelujara ki eeyan si mọ bo ya ibaṣepọ to ni anfaani ninu lo wa laarin wọn,'' A;-Rifai lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni ọna abayọ?
Al-Rifai ṣalaye pe awọn nnkankan wa ti a le ṣe to le ṣe iranwọ.
O rọ awọn eeyan lati maa ro nipa nnkan ẹyọkan ṣoṣo fun iṣẹju marun un.
Fun apẹẹrẹ, o ni eeyan le maa ro nipa coffee mimu, eeyan le maa wo bi o ṣe gbona si lọwọ.
Bakan naa, ẹni to gbe coffee lọwọ naa tun le maa ṣe akiyesi bi o ṣe n rin.
Al-Rifai ni ọna miran ni ṣe pẹlu lilo ẹya ara marun un:
- Ṣapejuwe nnkan marun un ti oju rẹ ri bayii
- Ronu lori iro ti o gbọ
- Ṣakiyesi nnkan mẹta ti o fọwọ kan
- Gboorun nnkan meji
- Jẹ nnkan to wa lẹnu rẹ wo
Al-Rifai ni nnkan ti gbogbo eyi da le lori ni lati ma ni ipaya ọkan lori awọn nnkan mii.
O ni o ṣe pataki fawọn eeyan lati maa ranti wi pe ọpọlọ ko wa fun ko maa ṣiṣẹ ni gbogbo igba.
Al-Rifai ni ọpọlọ eeyan gbọdọ ṣiṣẹ diẹ, ki o si tun sinmi diẹ ni.















