Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Òṣùpá Ẹlẹ́jẹ̀ tó yọ lójú ọ̀run ní Naijiria lálẹ́ àná àtàwọn orílẹ́èdè míì

Osupa ẹlẹjẹ laarin okunkun loju ọrun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Osupa Ẹlẹjẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Airin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, ti eeyan ba rin jina yoo ri ẹja to yarọ ninu ibu.

Ni ana ọjọ keje oṣu Kẹsan an ni oṣupa ẹlẹjẹ yọ loju sanmọ lorilẹede Naijiria ati lawọn orilẹede kan lagbaaye.

Bo tilẹ jẹ wi pe, awọn onimọ nipa oju ọrun ti sọ ṣaaju wi pe oṣupa ẹlẹjẹ yoo yọ loju sanmọ lalẹ ana, iyalẹnu lo si jẹ fun ọpọ eeyan ti wọn foju gan-an ni rẹ loju ọrun.

Awọn onimọ nipa oju ọrun sọ ṣaaju wi pe Naijiria ati Ghana wa lara awọn orilẹede ti oṣupa ẹlẹjẹ naa yoo ti yọ lalẹ ọjọ Aiku lati ilẹ Afirika.

Eyi lo si jẹ ki ọpọ eeyan wa ni imurasilẹ ti wọn si n wo oju ọrun lati ri aramanda to fẹ ṣẹlẹ.

Ki lo mu ki Oṣupa pọn bii ẹjẹ, ki si lo de ti Osupa ẹlẹjẹ fi jade loju ọrun gan an?

Wọn maa n pe e ni oṣupa ẹlẹjẹ nitori bi inu oṣupa ṣe maa n pọn lasiko ti iṣẹlẹ yii ba waye.

Onimọ nipa oju ọrun kan, Ọmọwe Bloomer sọ pe ọpọ eeyan lo maa n ro pe nnkan ti ko dara ni ki oṣupa pọn bi ẹjẹ.

Gẹgẹ bi alaye tawọn onimọ nipa oju ọrun sọ, eyi maa n ṣẹlẹ nigba ti aye ba wa laarin oorun ati oṣupa, ti o si n di imọlẹ lati ara oorun si oṣupa.

Lasiko ti eyi ba ṣẹlẹ ni ojiji aye maa n bo oṣupa patapata ti oṣupa yoo si di pupa.

Nigba miran ẹwẹ, oṣupa maa n yipo aye, eyi si ni ko ni jẹ ki o mọlẹ daadaa lasiko naa.

Amọ, nigba ti ara oṣupa ba wọ inu ojiji aye ni awọn eeyan maa n ri pe apa kan da dudu ninu oṣupa.

Oṣupa ẹlẹjẹ to jade lalẹ ana ọjọ Aiku foju han lati bii ago mẹrin kọja iṣẹju mejidinlọgbọn.

Ni nnkan bi aago mẹwaa alẹ ku isẹju marun un ni o wọ okunkunu pada.

Oṣupa ẹlẹjẹ ninu okunkun loju ọrun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oṣupa ẹlẹjẹ to jade lalẹ ana ọjọ Aiku foju han lati bii ago mẹrin kọja iṣẹju mejidinlọgbọn.

Iru ipa wo ni oṣupa ẹlẹjẹ le ni lori awọn eeyan laye?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Onimọ kan ni ọpọ eeyan lai moye ọdun sẹyin lo ti kọminu lori oṣupa ẹlẹjẹ bo ya o lewu fawọn eeyan.

Ọmọwe Bloomer ni oṣupa ẹlẹjẹ maa n yọ loju ọrun latari itanṣan oorun lati inu ojiji aye to bo oṣupa mọlẹ ni.

O ni iru nnkan yii naa lo maa n ṣẹlẹ ti oorun maa n fi n pọn loju ọrun nigba mii.

Ọmọwe Bloomer ni nnkan to maa n ṣẹlẹ nigba ti oṣupa ba di pupa lawọn onimọ nipa oju ọrun maa n pe "Rayleigh scattering" eyi to maa n jẹ ki oṣupa gbe awọ pupa jade fun igba pipẹ.

Onimọ nipa oju ọrun mii, Rachel Dutton, naa ṣalaye idi ti oṣupa ẹlẹjẹ fi maa n yọ loju ọrun.

Dutton ni eyi maa n ṣẹlẹ nigba ti ayika aye ba bo oorun mọlẹ ti ko si jẹ ki ina oorun de ara oṣupa.

O ni eleyii lo maa n fa a ti ina pupa to rẹwa fi maa n jade ninu oṣupa, ohun si ni awọn eeyan maa n pe ni oṣupa ẹlẹjẹ.

Dutton ni ''ti a ba ni aye ti ko ni ayika, oṣupa yoo kan maa yọ loju ọrun, yoo si maa di dudu pada.

Amọ, dipo ki iyẹn maa ṣẹlẹ, oṣupa maa n wọ inu ojiji pupa lọ, iyẹn lo maa n fun wa ni oṣupa ẹlẹjẹ.''