Wo àwọn ọ̀nà tí o lè fi dá ààbò bo 'inverter' rẹ lọ́wọ́ gbígba iná

Àkọlé fídíò, Ẹ wo fídíò bí àwọn òṣìṣẹ́ ṣe n fò sílẹ̀ nílé alájà gogoro tó jóná l'Eko
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọlọpọ oṣiṣẹ lo ha sinu ile alaja gogoro Afriland Tower, to wa ni Broad Street , Lagos Island, nipinlẹ Eko, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan an.

Oriṣiriṣi fidio lo n lọ kaakiri lori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn eeyan ṣe n gba oju ferese sọkalẹ ninu ile naa, lati jajabọ lọwọ ina.

Eefin ina ọhun to gbale-gboko lo jẹ ki awọn eeyan tete mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ti fidio ọhun fi jade sita.

Igbakeji Oludari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Ogabi Olajide, sọ ninu atẹjade kan pe, ni nnkan bi aago kan aabọ ọsan ni awọn gba ipe pajawiri fun iṣẹ idoola, eyi to mu ki awọn oṣiṣẹ panapana lati Ebute Elefun ati Sari Iganmu, lọ sibẹ.

'Yaara ti wọn ko inverter si ni ina ti bẹrẹ'

Ọkunrin n gbiyanju lati bẹ silẹ loju ferese, ti awọn akẹgbẹ rẹ si duro ti i

Oríṣun àwòrán, @Mubarak_yshau/X

Gẹgẹ bi nnkan ti Ọgbẹni Ogabi sọ, inu yaara ti wọn n ko ẹrọ amunawa 'inverter' si nisalẹ ile nla naa ni ina ti kọkọ sọ, ti eefin rẹ si tan de ọpọlọpọ aja, ki wọn o to o bẹrẹ si ni jona.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara, a ri ọkunrin kan to n sọkalẹ lori aja ile, ti awọn kan si ba a di akasọ mu.

Ile gogoro Afriland ni oriṣiriṣi ileeṣẹ n lo fi sẹ ọọfiisi.

Ileeṣẹ panapana sọ pe awọn raaye pa ina ọhun, ti wọn si tun doola awọn oṣiṣẹ to n bẹ ninu ile.

Amọ titi di akoko yii, a ko ti i le sọ iye eeyan to farapa tabi ku ninu iṣẹlẹ naa.

Awọn nnkan to o gbọdọ ṣe ti o ba n lo inverter

Kii ṣe iroyin mọ pe lilo orisun ina ti kii ṣe tijọba, ti di tọrọ fọnkale ni Naijria, paapaa lati igba ti owo ti gun owo ina ẹlẹtiriiki.

Lara ọna abayọ ti awọn eeyan si n lo ni inverter ati solar wa.

Ṣugbọn ṣe ko si nnkan to dara, ti kii ni aleebu tiẹ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa loju opo ileeṣẹ kan to n sẹ inverter, Afore Energy, ẹrọ amunawa inverter kii ṣaba mu ewu dani, ayaafi ti ko ba si amojuto to peye fun wọn.

Lara awọn ewu ti wọn tọka si ni pe:

  • Ina le ṣẹyọ ti batiri inverter ba gbona ju bo sẹ yẹ, ti waya ba ja tabi ki waya kan ara wọn
  • Batiri le gbi/bu gbamu ti o ba lo o pẹlu batiri lithium-ion to ti bajẹ tabi eyi to n lo asiidi
  • Ina le maa gbe eeyan ti ko ba si nnkan ti wọn fi bo inverter naa daadaa, to si le ba awọn nnkan to n lo ina jẹ
Batiti ati ẹrọ inverter ti wọn so mọ ara ogiri ile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nnkan pataki mii to ṣe koko ni pe fun ẹnikẹni to n lo inverter lati mojuto ni pe, ẹ ma ṣe di ẹru to pọ ju le e.

Eyi tumọ si pe iwọn nnkan ti agbara inverter rẹ le gbe ni ki o maa lo o fun un, ko ma ba a di pe awọn waya gbona ju, to si le gbina tabi dẹnu kọlẹ.

Yatọ si ewu ina tabi ti ẹlẹtiriiki, gbigbe inverter rẹ si ibi ti eruku ti n ku si, tabi ti oorun ti n pa a , le mu ki ẹmi rẹ̀ kuru, to si le ṣokunfa ko ṣe iṣẹkisẹ.

Ki ni ọna abayọ lati dena ijamba inverter?

Lati le dena awọn ijamba to le jẹyọ lati ara lilo inverter, o le gbe awọn igbesẹ yii:

Ri i daju pe ibi ti atẹgun n fẹ si lo gbe awọn batiri inverter rẹ si

Tẹle gbogbo ilana ti ileeṣẹ to ṣe inverter naa kọ si ara rẹ fun gbigba ina si i lara tabi ṣe amojuto rẹ

Lo irinṣẹ to n ṣe amojuto bi batiri rẹ sẹ n gbona si

Lo batiri to ba ilana agbaye mu bii IEC 62619 tabi UL 1973