Ṣé lóòótọ́ ni ẹni tí kò bá ní nọ́mbá owó orí TIN kò ní lè lo báǹkì ní Naijiria láti ọdún 2026?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n pa owo wọle fun ijọba apapọ, Federal Inland Revenue Service (FIRS), ti sọ pe irọ ni iroyin to n mi igboro titi pe awọn ọmọ Naijiria ti ko ba ni nọmba idanimọ owo ori, TIN, ko ni le ṣi apo iṣuna ni banki bẹrọ lati ọdun to n bọ.
Arabinrin Aderonke Atoyebi, to gbẹnusọ fun ajọ alaga FIRS, Zacch Adedeji sọ pe ko si ootọ kankan ninu iroyin naa.
Gẹgẹ bo ṣe, ijọba ti ṣe atunṣe si eto owo ori Naijiria to fi jẹ pe wọn ti ni alaye nipa araalu lọwọ tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, X/ FIRS
O sọ siwaju si pe gbogbo araalu ati ileeṣẹ to tọ si lati maa san owo ori ni ijọba ti mọ lai nilo ki wọn maa ṣe wahala lọtun.
Atoyebi ṣalaye pe "TIN jẹ nọmba mẹtala ti ijọba maa n fun ẹnikẹni ati ileeṣẹ to ba lẹtọọ lati maa san owo ori ni Naijiria.
"Lara awọn alaye to wa ninu nọmba naa ni ọdun ti wọn fun eeyan ni nọmba ọhun, ibi ti wọn ti fi orukọ ẹni naa silẹ (araalu lo n lo TIN nigba ti awọn ileeṣẹ n lo RC) ipinlẹ ti wọn ti ṣe iforukọsilẹ naa ati nnkan mii fun aabo.
"TIN jẹ ohun elo ti FIRS fi n fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan n san owo ori kaakiri Naijiria."
Ajọ naa fi kun pe fun ẹnikọọkan, wọn ti so nọmba idanimọ orilẹede, National Identification Number (NIN) mọ TIN wọn lasiko ti ajọ NIMC ba n pese rẹ fun wọn.
Atoyebi sọ pe ni kete ti eeyan ba ti lọ ṣi apo ifowopamọsi ni banki to si fi nọmba NIN rẹ silẹ nibẹ tabi ti ẹni naa fi alaye nipa ara rẹ sinu fọọmu KYC ni ẹrọ ayarabiaṣa banki naa yoo wa TIN ẹni ọhun jade ti yoo si so o mọ apo rẹ ni banki.
O fi kun pe "fun awọn to n ṣowo, TIN wọn ti so pọ mọ nọmba RC ti ajọ to n forukọ ileeṣẹ silẹ, CAC fun wọn.
"Bẹẹ naa ni oniruru awọn ẹlẹgbẹjẹgbe naa ni TIN wọn ti so pọ mọ nọmba iforukọsilẹ wọn.
"Eto yii n tumọ si pe ẹnikọọkan tabi awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ko nilo lati ṣe iforukọsilẹ tuntun fun TIN ti wọn ba fẹ lo ile ifowopamọ kankan."
O ni anfani to wa ninu igbesẹ naa ni pe ko ni si fifi akoko awọn eeyan ṣofo mọ.
Ẹwẹ, ọrọ yii lo jẹyọ nitori iroyin to gba igboro kan pe gbogbo ọmọ Naijiria yoo nilo lati ni TIN ki wọn to le ṣi apo nile ifowopamọ bẹrẹ lati oṣu Kini, ọdun 2026.
Iroyin naa lo da ibẹrubojo si ọkan ọpọ araalu latari wahala ti ṣiṣẹ eyii yoo da si wọn lọrun amọ FIRS ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
Ọna ti o le fi gba nọmba idanimọ owo ori rẹ ree

Oríṣun àwòrán, JTB
Igbesẹ akọkọ
- Lọ soju opo ajọ Joint Tax Board, JTB ni https://tin.jtb.gov.ng
- Tẹ "Search for TIN"
- Kọ nọmba BVN rẹ sibẹ to fi mọ ọjọ ibi rẹ lati mọ boya ijọba ti fun ọ ni TIN
Igbesẹ keji lati forukọsilẹ fun TIN ti ijọba ko ba fun ọ ni TIN funra wọn
- Lọ soju opo https://tin.jtb.gov.ng/ to jẹ ti ajọ JTB
- Tẹ akọle "Register for TIN" to jẹ ti ẹnikọọkan
- Dahun awọn ibere to yẹ nibẹ bii BVN, NIN rẹ atawọn nnkan mii ti wọn ba bere lọwọ rẹ
Lẹyin naa ni ki o fi gbogbo rẹ ranṣẹ ki o si maa duro de iwe ẹri 'Tax ID certificate.'
Ranti pe o ko nilo lati san owo kankan fun eyii, ohun ti o si le ṣe funra rẹ ni, yala lori ẹrọ kọmputa tabi lori foonu rẹ.















