Àwọn ọmọ ilẹ̀ China tó ń fi aráàlú ṣe ẹrú rí ẹ̀wọ̀n ogún ọdún he

Awọn afurasi ọhun ni Kevin Tsao, Chen Hui, Qin Li, Jiaqing Zhou, Ma Biao, Dai Junying, ati Zhang Zhilian

Oríṣun àwòrán, Buthanani Thobela/Department of labour

Àkọlé àwòrán, Awọnn afurasi naa jẹbi ẹsun 158 ninu apapọ ẹsun 160 ti wọn fi kan wọn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ọmọ orilẹede China meje ti wọn fi ọna ẹburu gbe awọn ọmọ orilẹede Malawi wọ South Africa lati fi wọn ṣiṣẹ ẹru ti ri ẹwọn ogun ọdun he.

Adajọ sọ pe ọmọ orilẹede China meje naa ni yoo ṣẹwọn ogun ọdun lẹni kọọkan wọn.

Awọn eeyan ọhun; ọkunrin mẹrin ati obinrin mẹta naa ni ile ẹjọ ni wọn jẹbi fifi eeyan ṣowo ẹru ni South Africa ni ibẹrẹ ọdun yii.

Awọn eeyan ọhun; ọkunrin mẹrin ati obinrin mẹta naa ni ile ẹjọ ni wọn jẹbi fifi eeyan ṣowo ẹru ni South Africa ni ibẹrẹ ọdun yii.

Idajọ wọn naa lo n waye lẹyin nnkan bi ọdun mẹfa ti ọwọ ofin kọkọ tẹ wọn lẹyin ti awọn agbofinro yabo ile iṣẹ kan niluu Johannesburg nibi ti wọn ti ṣawari ọmọ orilẹede Mali 91 ti 37 ninu wọn si jẹ ọmọde.

Ijọba South Africa sọ pe fifi eeyan ṣowo ẹru jẹ ohun to buru jai bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n ṣowo ọhun lorilẹede naa.

Awọn afurasi ọhun - Kevin Tsao, Chen Hui, Qin Li, Jiaqing Zhou, Ma Biao, Dai Junying, ati Zhang Zhilian – jẹbi ẹsun 158 ninu apapọ ẹsun 160 ti wọn fi kan wọn.

Lara ohun ti wọn ṣe ni fifun awọn to wọ South Africa laaye lati wa lorilẹede naa lọna ti ko ba ofin mu.

Ọlọpaa ya bo ileeṣẹ wọn lẹyin ti ẹnikan to moribọ nibẹ fi ọrọ naa to agbofinro leti.

Lẹyin naa ni iwadii fi han pe odidi wakati mọkanla gbako lawọn oṣiṣẹ ileesẹ naa fi n ṣiṣẹ loojọ.

Yatọ si eyii, gbogbo ọjọ to wa ninu ọsẹ ni wọn fi n ṣiṣe lai gba isinnmi kankan, bẹẹ ni wọn n ṣiṣẹ ọhun lai fun wọn ni ohun elo idaabobo ara ẹni kankan.

Ohun to tun buru julọ nibẹ ni pe $1.64 (£1.22) ni wọn n fun oṣiṣe wọn fun iṣẹ wakati kan, eyii to jẹ owo to kere ju iye owo ti ofin ni ki oṣiṣẹ maa gba lorilẹede naa laarin wakati.

Ẹnikan to jẹri tako awọn ọdaran naa ni wọn ko gba awọn oṣiṣẹ ọhun laaye lati sinmi tabi jade kuro nileeṣẹ naa lasiko iṣẹ, koda wọn kii gba awọn laaye lati lọ ra ounjẹ paapaa.

Awọn alaṣẹ sọ pe ile ẹru ti wọn fi n ko ẹru lori omi ni wọn fi ko awọn oṣiṣẹ naa wọ orilẹede ọhun lati orilẹede wọn.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ oṣiṣẹ ti kan saara si idajọ naa pe inu awọn dun si ati pe yoo kọ awọn mii lọgbọn.