'Ọmọ mẹ́ta nínú méje ti mo bí ni kò jọ àwọn yóòkù rára, wọ́n gbó ju ọjọ́ orí wọn lọ'

Àkọlé fídíò,
'Ọmọ mẹ́ta nínú méje ti mo bí ni kò jọ àwọn yóòkù rára, wọ́n gbó ju ọjọ́ orí wọn lọ'
    • Author, Uche Akolisa
    • Role, Senior Journalist

Ninu ẹbi Akwuo, ọmọ mẹta ninu meje ti tọkọtaya naa bi lo yatọ si awọn mẹrin to ku.

Awọn mẹta ọhun ni oju wọn gbo, ti wọn si jọ arugbo bo tilẹ jẹ pe ọmọde ṣi ni wọn.

Iwadii BBC fihan pe aarun kan ti wọn n pe ni Cutix laxa, ni wọn ni. Bakan naa ni awọn onimọ sayẹsni sọ pe eeyan kan ninu miliọnu kan eeyan lo ma n ni aarun ọhun.

Ọkan ninu awọn ọmọ naa, Chizaram, jẹ ọmọ dun mẹjọ, ikeji, Chiadi, si jẹ ọmọ ọdun mẹfa.

Ile ẹkọ ti awọn ọmọ naa ni wọn n raaye fi ara pa mọ si kuro ni arọwọto awọn to ma n fi wọn ṣe yẹkẹ́ nitori bi oju ati ara wọn ṣe gbo.

Chizaram sọ pe awọn eeyan ma n sọ pe oun n ṣe aisan, amọ oun mọ pe ko si ohunkohun to n ṣe ohun.

Lati igba ti wọn ti bi wọn ni ara ati oju wọn ti ri bẹẹ, ṣugbọn oriṣiriṣi alaye ni awọn eeyan ṣe fun iya wọn, Ngozi Akwuo, ẹni ogoji ọdun.

"Nigba ti mo bi Chizaram, awọn oniṣegun ibilẹ sọ fun mi pe, iya ọkọ mi to tik u, ni ọmọ naa jọ.

"Nigba t imo bi Chiadi, awọn eeyan kan tun sọ pe baba ọkọ mi to tik u ni oun naa jọ."

Arakunrin Akwuo ati awọn ọmọ rẹ meji, Chiadi ati Chizaram, joko
Àkọlé àwòrán, Baba wọn, Arakunrin Akwuo ni aarun naa kọkọ mu nigba to wa ni ọmọde

Chiadi ati Chizaram n ṣe daadaa ninu ẹkọ wọn nile ẹkọ.

Ogbonna Oluchi, to jẹ olukọ wọn jẹri si eyi – "Nigba t imo bẹrẹ si I kọ wọn, ipo kẹjọ ni Chiadi ma n gbe, amọ ni bayii, o ti n gbe ipo kẹta. Ipo kinni tabi ikeji ni ẹgbọn rẹ ma n gbe.

Awọn onimọ nipa ẹran ara sọ fun BBC pe aarun kan ti wọn n pe ni Cutis Laxa, ni ẹbi naa ni.

Ọjọgbọn Khalid Adekoya, to jẹ olukọ ni ẹka imọ Cell Biology ati Genetics ni Fasiti ilu Eko, sọ fun BBC pe ara ami arun naa ni pe ara awọn to ba ni i ma n gbo ju ọjọ ori wọn lọ, ti wọn o si da bi agbalagba.

Iya awọn ọmọ naa ree to gbe abikẹyin rẹ, ti oun naa ni aarun naa lara, dani

Ajọ American National Library of Medicine ṣe apejuwe aarun naa gẹgẹ bi aiṣe deedee to ma n de ba iṣan ara, awọ, awọn ẹya to wa ninu, ati ẹya ara mii.

Ọpọ rẹ lo ma n jẹ ajogunba bi ti ẹbi yii, amọ awọn mii ma n ṣẹlẹ funra wọn.

Awọn onimọ sayẹnsi sọ pe aarun naa ko ṣe idiwọ fun eto ẹkọ wọn.

Dokita Utom-Obong Akpan ti ẹka eto ẹkọ ẹya ara ni Fasiti Bowen, sọ pe awọn miran to ba ni aarun yii ma n ni ipenija pẹlu ọpọlọ wọn, amọ "nigba ti a ṣe ayẹwo ẹbi yii, a ri i pe ko si ohunkohun to ṣe ọpọlọ won".

Awọn ọmọ naa n ko pa ninu oriṣiriṣi idije ere idaraya, eyi to ti sọ wọn ti gbajumọ laarin ilu wọn.

Igboya ti wọn ni yii, si lo n ran wọ lọwọ lati koju awọn to n fi wọn ṣe yẹẹyẹ.

Tọkọtaya Akwuo pẹlu awọn ọmọ wọn mejeeje duro niwaju ile wọn
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ mẹta lo yatọ ninu meje ti tọkọtaya Akwuo bi