Ajínigbé jí ọkọ àti ìyàwó rẹ̀ mẹ́ta gbé ní Kwara, dáná sun ọ̀kadà àwọn fijilanté, làwọn ọ̀dọ́ bá fẹ́hónúhàn

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Fọfọ ni ojuupopo kun fun awọn ọdọ ilu Isanlu Isin, ipinlẹ Kwara, ni aarọ ọjọ Satide, ọjọ kẹtala oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 yii, lasiko ti wọn n fi ẹhonu han latari eto aabo Isanlu Isin ti wọn lo ti mẹhẹ.
Nnkan bii aago meje owurọ ni awọn ọdọ naa ti tujade sojuu popo, ti wọn si di opopona Omu-aran si Oke Onigbin pa fun ọpọ wakati ti iwọde naa fi waye.
Awọn ọdọ naa ni awọn n fẹhonuhan latari iṣoro eto aabo to n koju ilu Isanlu Isin.
Kí ló fa ìfẹ̀hónúhàn gan-an?

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Ọkan lara awọn ọdọ naa to ba BBC News Yoruba sọrọ, to pe orukọ rẹ ni Ọgbẹni Adewale, ṣalaye pe l'Ọjọru to kọja, awọn fura pe awọn agbebọn ti wọ igbo Isanlu Isin lati ọna Ọ̀là.
Adewale sọ pe nigba to di Ọjọbọ ni awọn ọdẹ ilu ati awọn fijilante wọ inu igbo naa lọ lati le wọn kuro, wọn si gbe ọkada wọn si abẹ igi kan ninu igbo naa.
O ni ṣugbọn si iyalẹnu awọn, nigba ti awọn ọlọdẹ naa yoo fi pada debi ti wọn gbe ọkada wọn si, awọn agbebọn tawọn furasi pe Fulani ni wọn, ti dana sun gbogbo ọkada awọn ọlọdẹ to n lọ bii mẹẹẹdọgbọn.
Adewale tẹsiwaju pe awọn ọlọdẹ ọhun ko pe mọ nigba ti wọn yoo fi pada sinu ilu, meji ninu wọn lo ni wọn ti bọ sọwọ awọn agbebọn ti awọn ko ri wọn mọ.
Awọn iṣẹlẹ yii lo ni o mu ki awọn ọdọ ilu Isanlu Isin tu jade lati fẹhonuhan.
Bakan naa ni araalu Isanlu Isin miran ti orukọ tiẹ n jẹ Kehinde, tun ṣalaye fun BBC pe inu fuu -aya fuu- lawọn eeyan ilu wa latari awọn iṣẹlẹ yii.
Kehinde sọ pe ko si ẹnikẹni to ṣi ṣọọbu itaja lọjọ ifẹhonuhan naa ni Isanlu Isin.
O ni awọn meji ti wọn kọkọ jigbe ti san ogun miliọnu fun itusilẹ, wọn ko si ti i yọnda wọn titi di asiko yii.
O parọwa si ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba apapọ lati ran wọn lọwọ nipa ọrọ eto aabo.
"Ọpọ ìgbà ni àwọn ajínigbé ti ji aráàlú gbé, wọ́n ji ọkọ àti ìyàwó rẹ̀ mẹ́ta pẹlu àwọn ọmọ wọn lọ''

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Nigba to n sọrọ lori iṣoro ijinigbe yii, Oloye Michael Ayanda Oode, to ṣoju fun Kabiyesi ilu naa, sọ pe ọpọ igba ni awọn ajinigbe ti ji awọn araalu gbe, wọn si tun n ji wọn gbe ni ilu Ẹlẹyin pẹlu.
Oloye Ayanda ṣalaye pe laipẹ yii ni wọn ji ọkunrin kan gbe ni Ẹlẹyin, pẹlu iyawo rẹ mẹtẹẹta àti awọn ọmọ wọn gbe .
Aṣoju ọba naa rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati ijọba apapọ lati ran wọn lọwọ lori eto aabo to mẹhẹ yii.
Ninu ọrọ Gomina ipinlẹ Kwara, Mallam Abdurahman Abdurazak, o ba awọn fijilante to padanu ẹmi wọn kẹdun, ati awọn eeyan ilu Isanlu Isin lapapọ.
Atẹjade ti Akọwe iroyin fun Gomina Abdulrahman, Rafiu Ajakaye, fọwọsi, sọ pe Gomina gbe ẹbun owo miliọnu mẹwaa Naira kalẹ fun mọlẹbi awọn fijilante to padanu ẹmi wọn.
Bakan naa lo ṣeleri pe ijọba yoo fi awọn ọmọ ogun sọwọ si agbegbe naa laipẹ. O rọ araalu lati gba alaafia laaye.
Àlàyé ọlọ́pàá
Ninu ọrọ Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara; Ejirẹ Adeyemi Toun, o ni kete tawọn gbọ si iṣẹlẹ naa ni ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ologun ati awọn ọtẹlẹmuyẹ, ti ko ikọ ẹṣọ alaabo sọwọ si agbegbe naa.
Bakan naa lo ni ifọwọsowọpọ Alaga ijọba ibilẹ Irẹpọdun; Azeez Yakubu Tinuọla ati Alaga ijọba ibilẹ Isin; Ọmọọba Benjamin Lanre Jọlayemi naa ko gbẹyin.
Alukoro sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara; Adekimi Ojo, ti rọ awọn ọdọ agbegbe naa lati gba alaafia laaye, ki awọn janduku ma baa ja iwọde gba mọ wọn lọwọ.
Bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn ọdọ ilu naa fun ifọwọsowọpọ wọn.


























