Ta a ni pásítọ̀ ọmọ Nàìjíríà tó ń pa owó gọbọi lórí ìsìn ìjọ rẹ̀ táwọn èèyàn ń wò lórí YouTube?

Pasitọ Jerry Eze wọ agbada funfun, o si fi ọwọ mejeeji rẹ si agbọn

Oríṣun àwòrán, Real Jerry Eze/Instagram

Àkọlé àwòrán, Lọdun 2019 ti ajakalẹ arun covid-19 bẹ silẹ eyi to jẹ kawọn ile ijọsin ti ilẹkun ṣọọṣi ni irinajo ijọsin ori ayelujara ijọ Pasitọ Jerry Eze bẹrẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ eeyan lo n lo itakun ayelujara YouTube lati gbe fidio ti wọn n ṣe jade lati wo, ti wọn si n pa owo nla nibẹ.

Ọkan lara iru awọn eeyan yii ni Pasitọ Jerry Eze to jẹ alufaa ati oludasilẹ ijọ Streams of Joy International and the New Season Prophetic Prayers and Declarations (NSPPD) jẹ.

Ọgunlọgọ eeyan lo maa n darapọ mọ ile ijọsin Streams of Joy International ti Pasitọ Eze ba ti n waasu lọwọ.

Akọsilẹ fi han Pasitọ naa wa lara awọn to n gba owo to pọ julọ ni Naijiria lọwọ ileeṣẹ YouTube fun fidio ti wọn maa n fi soju opo wọn lori itakun ayelujara naa.

Pasitọ Eze ko kan di ilumọọkan lasan nitori pe oun ni alufaa ijọ Streams of Joy International to n ṣe eto ''New Season Prophetic Prayers and Declarations (NSPPD),'' awọn eeyan tun mọ Ọgbẹni Eze tori owo nla to ti wa lọwọ rẹ latari fidio ṣọọṣi rẹ ti ọpọ eeyan n wo lori YouTube.

Bi irinajo ṣọọṣi ori YouTube Pasitọ Jerry Eze ṣe bẹrẹ

Lọdun 2019 ti ajakalẹ arun covid-19 bẹ silẹ eyi to jẹ kawọn ile ijọsin ti ilẹkun ni irinajo ijọsin ori ayelujara ijọ Pasitọ Eze bẹrẹ.

Ni ipari ọdun 2019 yii naa ni o ṣe ifilọlẹ eto adura ti o pe orukọ rẹ ni New Season Prophetic Prayers and Declarations (NSPPD) lori YouTube.

Eto yii ba aini ọpọ eeyan ti wọn ko lanfaani lati lọ si ṣọọṣi mọ tori ajakalẹ arun covid pade lati le maa ri ibi jọsin pada.

Adura gbigba kikan kikan, ọrọ ẹri lori oniruuru iwosan ati idande to n ṣẹlẹ nibi ijọsin ori ayelujara Pasitọ Eze lo polongo eto naa kaakiri agbaaye lori YouTube.

Ni bayii, akọsilẹ fi han pe eeyan ti ko din ni miliọnu 2.87m lo maa n darapọ mọ eto adura NSPPD, nigba ti eeyan to le ni miliọnu 643 jẹ iye awọn ti wọn ti wo eto naa lori YouTube lati igba to ti bẹrẹ.

Eyi wa lara nnkan to sọ Pasitọ Jerry Eze di ilumọọka tori kaakiri gbogbo agbaaye ni wọn ti n wo o lori YouTube.

Pasitọ Jerry Eze mu gbohun-gbohun lọwọ, o si wọ aṣọ olomi aro

Oríṣun àwòrán, Real Jerry Eze/Instagram

Àkọlé àwòrán, A bi Pasitọ Jerry Uchechukwu Eze lọjọ kejilelogun oṣu Keji ọdun 1982 niluu Umuahia ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Abia.

Ta a ni Pasitọ Jerry Eze tawọn eeyan n sọ nipa rẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

A bi Pasitọ Jerry Uchechukwu Eze lọjọ kejilelogun oṣu Keji ọdun 1982 niluu Umuahia ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Abia.

Ilẹ ẹkọ girama Ibeku High School ni Ọgbẹni Eze lọ niluu Umuahia laarin ọdun 1991 si 1997.

Lẹyin naa ni Eze lọ si ile ẹkọ fasiti ti ipinlẹ Abia nibi ti o ti kẹkọọ gboye ninu imọ itan ati ibaṣepọ pelu awọn orilẹede ilẹ okeere.

Pasitọ Eze tun tẹsiwaju ninu eto ẹkọ rẹ lati gboye keji ninu imọ okowo ni fasiti ipinlẹ Enugu.

Lẹyin to kẹkọọ gboye meji tan ni fasiti ni o ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ pẹlu banki agbaye lori akanṣe iṣẹ lati gbogun ti HIV/AIDS.

O tun ṣiṣẹ pẹlu ajọ iṣọkan agbaye UN naa lori iye awọn to wa lawọn orilẹede aye.

Lẹyin naa ni Ọgbẹni Eze di pasitọ, lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹta ọdun 2007 ni o ṣe igbeyawo pẹlu Eno Ebele.

Eleduwa si fi ọmọkunrin kan ati ọmọbunrin kan idile wọn lọrẹ.

Lọdun 2009 ni o bẹrẹ ṣọọṣi rẹ nile ijọsin All Saints Chapel, ni North Carolina lorilẹede Amẹrika.

Pasitọ Eze bẹrẹ ijọ Stream of Joy International Church nipinlẹ Abia State lọdun 2013.