Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé láti ara tomato ni ànàmọ́ 'potato' ti jáde

Aworan tomato to rẹ̀ daadaa to si rẹwa, tomato naa pọ, pẹlu potato to pọ bẹẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn onimọ Sayẹnsi sọ pe iwadii awọn fi han pe irandiran irufẹ tomato kan lo bi potato
    • Author, Dalia Ventura
    • Role, BBC News Mundo
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ohun to ba jọhun la fi n we ohun, eepo ẹpa lo jọ posi ẹliri, adingbọnaku jọ imi ahun.

Eroja ọbẹ aṣaraloore ti a mọ si tomaati lede Yoruba, tomato lede oyinbo, ko deede di ohun ti a n jẹ fun ilera lonii. O ni alajọwaye ti i ṣe potato, iyẹn anamọ́ tati ọdunkun, ohun jijẹ to ni eepo lara.

Ni nnkan bii miliọnu mẹsan-an ọdun sẹyin, nibi kan to pada waa di ibi ti a mọ si South America lonii, nigba ti awọn oke igbaa ni (Andes) ṣi n kora jọ, aginju ni gbogbo agbegbe wa, ko si eeyan lorilẹ nigba yẹn - Nigba naa, awọn irugbin meji kan ti wọn duro lẹgbẹẹ ara wọn wa laginju yii.

"Tabi ka kuku sọ pe iran irugbin meji, awọn ni baba nla ohun ti a mọ si tomato lonii." Solanum lycopersicum ni orukọ ti wọn n pe tomaati lede awọn onisayẹnsi.

Dokita Sandra Knapp, onimọ nipa eweko lati Natural History Museum, ni London lo ṣalaye bẹẹ.

"Ati eyi ti a mọ si Solanum etuberosum, ti oriṣi mẹta rẹ to wa laye bayii n wa lati Chile ati Juan Fernández Islands."

Bi ẹyin naa ba wo o lati ara orukọ wọn to jọra, mọlẹbi ni wọn, awọn eso mejeeji naa ba ara wọn tan. Wọn si le hu papọ nibi kan naa.

"Iṣipopada awọn eroja kan lara wọn lo sọ wọn di ohun to n hu lawọn apa ibi to tutu lagbaaye. "

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dokita Knapp tun tẹsiwaju pe idi ẹ naa niyẹn ti tomato fi le hu, ko si yè laaarin awọn oke igba naa.

Awọn onimọ sọ pe eyi maa n ṣẹlẹ daadaa, nigba mi-in si ree, ko ni i so eso ire.

Fun apẹẹrẹ, ẹranko kan wa to fi ara jọ kẹtẹkẹtẹ pupọ, bẹẹ ki i ṣe kẹtẹkẹtẹ, 'Mule' ni oloyinbo n pe e.

Ibalopọ laaarin abo ẹṣin ati akọ kẹtẹkẹtẹ lo maa n fa ki wọn bi Mule. Loootọ lo jẹ pe ajọṣepọ awọn ẹranko naa mu nnkan gidi jade, to si niye lori lati igba iwaṣẹ, ṣugbon Mule ko le ṣe abiyamọ.

Lawujọ awon nnkan ọgbin, awọn irugbin ti iṣesi wọn dọgba maa n hu papọ lọpọ igba. Dokita Knapp tun fidi eyi mulẹ.

Wọn le lalẹ hu funra wọn tabi ki awọn eeyan gbin wọn papọ, wọn yoo si jẹ ẹya ọtọọtọ.

"Nigba mi-in, awọn irugbin yii ko ni i le so eso ju ẹẹkan lọ, wọn ko ni i pọ niye tori eyi".

Bi Dokita Knapp ṣe ṣalaye niyẹn.

Ṣugbọn bi apapọ awọn irugbin naa ba ṣe deede, wọn yoo so eso to bẹẹ ti yoo kọja afojusun oloko.

Ohun to ṣẹlẹ ṣi tomato ati Potato ree. Lati ara ilalẹhu wọn ni miliọnu rẹpẹtẹ ọdun sẹyin, ni potato ti jade.

Aworan awọn eso mejeeji ti i ṣe tomato ati potato lo han ninu aworan yii. Tomato lewe, o leso pupa, potato to wa lẹgbẹ rẹ lewe, ṣugbọn ko ti i so

Oríṣun àwòrán, LOC/Biodiversity Heritage Library

Àkọlé àwòrán, Irugbin ti a mọ si tomato ree lapa osi, eyi to pada di potato to jẹ iyekan rẹ niyẹn lapa ọtun ninu aworan yii.

" Iyanu lo jẹ pe potato ta a n fojoojumọ ri to si ṣe pataki si wa ti wa fun ọdun pipẹ. Dokita Knapp lo sọ bẹẹ.

" Tomato ni iya rẹ, eyi ti a mọ si Etuberosum ni baba rẹ."

Sanwen Huang, Ọjọgbọn lati Chinese Academy of Agricultural Sciences to lewaju iwadii kan ti wọn gbe jade ni Journal Cell loṣu Keje, lo sọ eyi di mimọ.

Kí ni tomato fi jọ potato?

Leyin ti a ti mọ ipilẹ awọn eso mejeeji, o daa ka yanna-na afijọ wọn.

Loootọ, bi a ba ri tomato lọja, ko jọ potato. Potato le loju, o si ni eroja ti a mọ si Starch.

Tomato ni tiẹ pupa loju, o wu oju lati wo, o kun fun omi, o rẹwa. Ṣugbọn awọn irugbin mejeeji jọra wọn bi Dokita Knapp toun naa kopa ninu iṣẹ iwadii yii ṣe wi.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ewe awon irugbin mejeeji ati ododo wọn jọra gan-an, eso potato to ba so maa n fi ara jọ tomato nigba ti ko ba ti i pọ́n.

"Yatọ si ohun ti a le foju ri, a ti mọ tipẹ pe potato, tomato ati etuberosum sunmọ ara wọn gidi.

"Ohun ti a ko mọ ni eyi to sunmọra ju si potato ninu wọn, nitori ọlọkan -o-jọkan eroja inu wọn fi nnkan ọtọọtọ mulẹ fun wa nipa wọn."

Dokita Knapp lo ṣalaye bẹẹ.

Aworan naa ṣafihan irugbin to gun ti wọn pe ni TomTato, eyi ti wọn fi igi gbe duro, pẹlu eso tomato loke, potato nisalẹ.

Oríṣun àwòrán, Thompson & Morgan

Àkọlé àwòrán, Potatoes ati tomato jọra to bẹẹ to jẹ bi a ba gbin wọn pọ, eso mejeeji yoo tibẹ jade. Gẹgẹ bi eyi to wa ninu aworan yii ti a mọ si TomTato, awọn ileeṣẹ oniṣẹọgbin meji lo ṣe e, awọn naa ni Thompson ati Morgan

O ti le logun ọdun ti awọn onimọ ijinlẹ ti n wadii aṣiri eso potato to n ta nilẹ bii iṣu, ṣugbọn ko bọ si i fun wọn , idi si ni pe ẹya ti potato jẹ yatọ.

Bi ọpọ nnkan abẹmi ṣe ni awọn ohun ti a mọ si chromosome lara ti ko ju meji lọ, mẹrin ni potato ni, ni tiẹ.

Lati tu ohun to wa nidii eyi palẹ, ikọ oluwadii yii ko ohun ti a mọ si genomes jọ, o ju ọgọfa (120) lọ ti wọn ko kalẹ, awọn nnkan yii wa ninu eyi ti a mọ si cell ninu ara, wọn si ko potato, tomato ati etuberosum to pọ jọ pẹlu.

Abajade rẹ ni pe eroja genomes to wa ninu tomato fẹrẹ ri bakan naa bi eyi ti wọnri lara potato.

Iṣẹda awọn irugbin yii ki i ṣe ti ẹnikan tabi ẹnikeji, awọn mejeeji ni won jọ ni wọn." Dokita Knapp lo tẹnu mọ ọn bẹẹ.

Bi awọn oluwadii yii ṣe ṣawari ajọṣepọ to gunmọ, laginju South America lọdun pipẹ sẹyin niyẹn.

Potato to ba ta sita maa n fi ara jọ awọn to ṣẹ ẹ kalẹ, iyatọ ibẹ ni pe potato funra rẹ ni nnkan lara nisalẹ yẹpẹ, iyẹn naa si ni ohun ti a n jẹ.

Bi eeyan ba ni iṣu to ta loko, bi ẹni to ni ile ounjẹ ni gbogbo igba ni. Awọn ounje naa n jẹ ki ara mokun, wọn wulo lasiko otutu, ilẹ gbigbẹ, ayipada ọgbẹlẹ atawọn mi-in to le waye lati ara oju ọjọ.

Potato to farajọ tomato lo wa ninu aworan yii, nigba to ṣẹṣẹ n jade.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan irugbin potato to farajọ tomato

Irúgbìn tó bá ń ta bí iṣu ló rọ́wọ́ mú

Awọn onimọ ijinlẹ Sayẹnsi tun ri i pe irugbin to ba n ta bi iṣu lo rọwọ mu, wọn ni ipilẹ irugbin bẹẹ n tọka si pe o ni nnkan kan lara to fun un ni anfaani lati ta bii iṣu ninu ilẹ ni.

Wọn fi kun un pe ko si eyi to le da duro lai fara ti irugbin keji ninu awọn irugbin alajọṣe yii, ṣugbọn ti wọn ba to wọn pọ, wọn yoo mu ohun to n di potato jade labẹlẹ.

Awọn ikọ lati orilẹede China ti Dokita Knapp ba ṣiṣẹ gan-an fidi eyi mulẹ.

"Wọn ṣe ọpọlọpọ iwadii to wuyi gan-an, wọn tu gbongbo awọn nnkan to wa lara awọn irugbin yii lati fidi ero wọn mulẹ, bi ko ba si tiwọn ni, awọn to ta yẹn ko tiẹ kuro loju kan tẹlẹ".

Dokita Knapp lo ṣalaye bẹẹ.

"Lonii yii, o ju ọgọrun-un ẹya rẹ lọ to wa ni awọn ilu America, lati Guusu-Iwọ-Oorun America de Chile ati Brazil."

Dokita Knapp lo sọ bẹẹ.

Aworan eyi ti wọn n pe ni eruberosum ati tuberosum lẹgbẹ ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Shenzhen Institute of Agricultural Genomics, Chinese Academy of Agricultural Sciences

Àkọlé àwòrán, Ẹya etuberosum lapa osi, tuberosum lapa ọtun . Wọn le jọra wọn bi eeyan ba n wo wọn, ṣugbọn ti apa ọtun lo n di potato ti a n jẹ.

Kọ́kọ́rọ́ kan ba eyín ajá jẹ́

Ṣugbọn kan wa ninu bi awọn irugbin yii ṣe le ba ara wọn duro, oun naa si ni pe wọn tun le ṣe akoba fun potato.

"Lati gbin wọn, eeyan a gbin awọn potato kéé-kèè-ké, to tumọ si pe ti o ba gbin oriṣi kan rẹ, oriṣi kan yẹn naa ni gbogbo wọn yoo jẹ." Dokita Knapp lo ṣalaye bẹẹ.

Eyi si tumọ si pe bi wọn ṣe jẹ oriṣi kan naa lati orisun kan naa yii, ko si eyi ti yoo le koju arun ajeji to ba kọlu wọn ninu wọn.

O fi n ye wa idi ti awọn onimọ ijinlẹ fi ṣe iwadii yii.

Gẹgẹ bi Dokita Knapp ṣe wi, ikọ awọn Chinese to ṣe iwadii naa fẹ oriṣi potato to le di omiran ti yoo si tun ṣe ka si iran kan.

Igbagbọ wọn ni pe bi awọn ba fi oriṣi miran la wọn, yoo mu irugbin mi-in ti yoo le koju iṣoro to ba gba ibi ayika yọ.

"Ẹmi ati ẹnikeji mi toun naa jẹ onimọ ti a jọ ṣe iwadii yii fẹ mọ irugbin to sunmọ potato ju, ati idi ti wọn fi wa loriṣiriṣi ẹya.

"Fun idi eyi, a bẹrẹ iwadii naa lọna to yatọ, a si beere ibeere lọna kọọkan ti a gba, eyi to mu ki iwadii naa ya wa lara ti a si n ṣiṣẹ naa lọ."

Bẹẹ ni Dokita Knapp wi.